Description
No Description
Awon ogbifo miran 3
تعريف موجز بالإسلام
بلغة : اليوربا
Introduction to Islam in Yoroba Language
Ni Oruko Olohun Oba Ajoke aye Asake orun.
ALAYE NIPA ESIN ISLAAM NISOKI.
Gbogbo eyin je ti Olohun, Eni ti I se Oba gbogbo aye. Ki ike ati ola si ma a je ti asiwaju gbogbo awon ojise Anabi wa Muhammad ati awon ara ile re pelu awon alabarin (sohaabah) re ni apapo.
Lehin - wa igba - naa, esin ISLAM: ohun ni ki eniyan jeri pe kosi enikankan toye kasin ayafi Olohun, ati wipe Anabi Muhammad ojise Olohun ni. Pelu okan ati ahan, ati awon orikerike ara. Esin ti anwiyi ko awon origun igbagbo mefeefa sinu, ati lilo awon origun Islam maraarun, ati mima se daada. Osije ipari awon ise Oloun ti osokale fun olupinnu awon Anabi ati ojise, eleyi tii se Anabi Muhammad omo Abdullah (ki ike ati ola Olohun o maa baa).
Oun si ni esin otito ti esin miran ki yo o je atewogba ni odo Olohun yato si oun nikan. Olohun si ti se e ni esin irorun ti ko si isoro kankan tabi wahala nibe. Ko se ohun ti o koja ikapa won ni oranyan fun awon ti won gba esin naa. Beeni ko si la ohun ti o koja agbara won kowon ni orun. Ohun sini esin ti ose pe imo Oloun ni okan(al - Taoheed) ni ipilese re, ami re si ni ododo, abalo-ababo re si ni deede, opomulero re si ni otito, emi re si ni ike.
Oun si ni esin ti o tobi ti o se pe oun dari gbogbo eda si ibi gbogbo ohun ti yo o je anfaani fun won ni orun won ati aye won. Bee naa ni o si tun n ki won ni ilo nipa gbogbo ohun ti yo o se won ni suta ni isemi orun ati ni igbesi aye won. Ohun ni esin ti Olohun fi se atunse awon adi-okan ati awon iwa. Ohun naa ni O fi se atunse isemi aye ati ti orun. Ohun ni Olohun fi se irepo laarin awon okan ti o keyin si ara won, ati awon ife inu oniranran. Nipase eyi ni O fi yoo ninu okunkun biribiri iro, ti O si se ifinimona re lo si ibi otito, ti O si to si ona toto.
ISLAM ni esin ti o duro to, eyi ti a gbe kale ni ona ti o dara de opin ninu gbogbo awon iro ti o muwa ati ninu gbogbo awon idajo re pata. Ko si iroyin kankan ninu re ayafi otito ati ododo be e si ni ko se idajo kankan ayafi pelu daada ati deede. Ninu re ni: awon adisokan ti o ni alaafia, awon ise ti o duro to, awon iwa ti o dara pari, ati awon eko ti o ye kooro.
Ni soki,ise ISLAM wa lati se amulo awon ohun ti o n bo wonyii:
(1) Sise alaye Olohun ti I se oluda awon eniyan fun won pelu (ifosiwewe alaye) awon oruko Re ti o dara julo eyi ti kosi oloruko fun ati awon iroyin Re ti o ga pari, eyiti kosi alafiwe fun nibe, pelu awon ise Re ti o mu ogbon dani ti kosi ni orogun nibe,ati awon ohun ti o to si Olohun nikan soso.
(2) Pipe awon eru Olohun (awon eniyan) losi ibi jijosin fun Olohun nikan soso ti kosi orogun fun. Eyi yo o je be e nipa sise ohun ti Olohun se lofin fun won ninu tira re (Alquran) ati ilana ojise re (sunnat) pelu sise ohun ti Olohun fe, ati jijina si ohun ti o ko. Eyi ti o se pe daradara ati orire won ni aye ati ni orun won wa ni be.
(3) Riran awon eniyan leti aye won ati ibuseri padabosi won leyin iku ati ohun ti won yo o ba pade ninu saaree won ati nigba igbende won ati isiro ise won ati nile ikeyin won, ogba idera alujonaa ni yoo je, abi ina ti o n jo geregere, gbogbo re patapata ni odiwon ise onikaluku.
Ni soki a lee se alaye awon origun pataki Islaam ninu awon koko ti o n bo wonyii:
IKINNI: Awon origun igbagbo (Imoni) osije mefa:
(1) Gbigba Olohun gbo. Eleyi si ko awon inkan ti o n bo wonyi sinu:
(a) Nini igbagbo pe okan ni Olohun nibi ise e re. Eyi tumo si pe Oun ni Oba, Oluda, Oluni,Olusakoso gbogbo awon eto eda re aseyowu lori won.
(b) Nini igbagbo pelu pe Olohun nikan ni Atoosin eyi tumo si pe Oun ni Olohun otito gbogbo in ti won bati n se ijosin fun leyin Olohun iro ati ikuna ni, ti koto.
(d) Nini igbagbo ninu awon oruko Olohun ati awon iroyin Re. Eyi tumo si pe Oun ni o ni awon oruko ti o dara julo ati awon iroyin ti o pe perepere ti o si ga julo gege bi o ti wa ninu tira Re (Al-quran)ati (sunnat) ojise Re (ki ike ati ati ola Olohun ki o ma a baa)
(2) Nini igbagbo ninu awon ironse Olohun (Molaaikat):
Awon Molaaikat je eru Olohun alaponle. Olohun ni o si dawon. Bakannaa won je oluse ijosin fun, won si tun je atele ase re ni perepere. Olohun si fi awon ise orisirisi fun okookan won. Ninu won ni Jibriilu eni ti a se afiti ise mimo ti o ba n waye lati odo Olohun, si odo eni ti O ba fe ninu awon anabi Re ati awon ojise Re ti si. Ara won si tun ni Miikailu eni ti o wa fun eto riro ojo ati awon koriko ti n hu. Bee naa ni ara won ni Isiraafiilu eni ti o wa fun fifon fere ni asiko ti Olohun ba fe ki aye o pare, ati nigba ti o ba tun fe ki won dide (lati jabo nipa igbesi aye won).Ara won si tun ni molaaika iku eni ti ojuse re je gbigba awon emi ti asiko re ba to.
(3) Nini igbagbo si awon iwe mimo Olohun (tira):
Olohun Oba ti o tobi ti osi kaya o so awon iwe kale fun awon ojise Re eyi ti ona mimo, rere ati daradara wa ninu re.Eleyi ti amo ninu awon iwe yi nii:
(a) Taoreeta eyi ti Olohun so kale fun anabi Muusa eni ti awon kan mo si “Moose" (ki ike ati ola Olohun o maa baa) Iwe yi ni o tobi julo ninu iwe awon omo isireeli.
(b) Injiila (bibeli) ti Olohun so kale fun anabi Isa (ki ike ati ola Olohun o maa baa).
(d) Sabuura ti Olohun so kale fun anabi Dauda (ki ike ati ola Olohun o maa baa).
(e) Awon iwe (ewe tira) ti Olohun so kale fun anabi Ibraimon (ki ike ati ola Olohun o maa baa).
(f) Alkuraani alaponle eyi ti Olohun ti ola Re ga julo so kale fun anabi Re ti n je Muhammad eni ti ise olupinu awon anabi. Tira alaponle yii ni Olohun fi fagile gbogbo awon iwe mimo ti o ti so kale siwaju re. Idi niyi ti Olohun funraare mojuto siso tira naa (kuro nibii afikun tabi ayokuro) nitoripe oun ni yoo seku gegebi awijare ti o fese mule gidi fun gbogbo eda titi di ojo igbende (alikiyamo).
(4) Nini igbagbo si awon ojise Olohun:
Olohun ti ran awon ojise kan si awon eda Re. Eni akako ninu awon ojise naa ni anabi Nuhu nigbati anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa, ati gbogbo awon ojise ti o siwaju re) si je olupinu won. Gbogbo awon ojise Olohun pata - ti o fi mon anabi Isa omo Moriyam, ati Uzaeru, (ike Olohun ati ola re o maa ba won) - je eda abara ti kosi nkankan ninu iwasi I je Olohun ni ara won. Awon paapaa je eru Olohun gegebi awon eda yoku naa ti je eru Olohun, sugbon Olohun se aponle fun won pelu riran won ni ise mimo si awon eda abara yoku. Ni akotan, Olohun ti pari gbogbo ise ti o fe ran si aye pelu anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa). O si ti ran an si gbogbo eniyan laiko da enikan si, nitori naa, ko si anabi kankan mo leyin re.
(5) Nini igbagbo si ojo ikehin:
Ojo agbende ni ojo ikehin ti ko ni si ojo kankan leyin ojo naa mo. Ojo naa ni Olohun yoo gbe gbogbo eniyan dide lati inu saree laaye lati seku titi ayeraye ninu ile idera (alujanna) tabi ninu ile iya (ina) .
Ninu igbagbo si ojo ikehin ni: nini igbagbo si gbogbo ohun ti yoo sele leyin iku, gegebi, iyonu inu saree, ati ohun ti yoo tun sele leyin eleyi gegebi agbende, ati isiro ise ti eda gbe aye se. Leyinwa-igba-naa, ni didari si ibugbe ayeraye eyi ti I se alujanna tabi ina.
(6) Nini igbagbo si kadara (akoole):
Ohun ti oun je kadara ni; nini igbagbo pe Olohun ni O pebubu gbogbo ohun ti n be, ohun ni O si da gbogbo eda ni ona ti mimo Re ti siwaju re ti ariwoye Re si fe bee. Gbogbo awon eto re ni o ti je mimo ti o si ti wa ni akoole ni odo Re. O fe gbogbo ohun ti n sele ni o je ki o maa sele bee, Oun paapaa ni o si daa.
IKEJI: Awon origun ISLAM:
Esin ISLAM je ohun ti a mo lori awon origun marun kan to je pe eniyan ko lee je musulumi tooto ayafi ti o ba ni igbagbo ninu awon origun naa ti o si n loo. Awon naa niyi:
Origun kinni:
Ijeri (igba tokantokan) pe Olohun nikan ni oba (ti a a josin fun) ati pe ojise Olohun ni anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa) Ijeri yii ni kokoro ISLAM ati ipilese re ti gbogbo eka yoku duro le lori.
Itumo pe kosi oba miran leyin Olohun ni pe; ko si eni ti o leto pe ki a ma a se ijosin fun ju oun nikan lo. Oun nikan ni apesin tooto. Gbogbo elomiran ti a ba n dari ijosin si odo re yato si Oun je iwa ibaje ti ko si lese nile bi o ti wu ki o mo. Ohun ti o n je Olohun Oba ninu agboye awa musulumi ni eni ti a a josin fun.
Itumo ijeri pe anabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa) je ojise Olohun ni gbigba a ni ododo ninu gbogbo ohun ti o fun ni ni labare re, ati titele e ninu gbogbo oun ti o pa lase ati jijinna si gbogbo ohun ti o ko fun ni lati se ti o si jagbe mo, ati wipe ako gbodo sin Olohun ayafi lori ilana re.
Origun keji: Irun kiki:
eyi ni awon irun ti a ma n ki ni eemaarun lojojumo .Olohun se e ni ofin lati lee je ifun ni iwo o Re lori awon eru Re, ati idupe fu Un lori awon ideraa Re ati okun idapo laarin musulumin ati Olohun re.Eyi ti yoo maa ba ni gbolohun ninu re ti yoo si ma a gbadura sii. Ti awon irun yii yo o si je akininlo fun un nipa I se ibaje ati ise aburu.
Olohun si ti se e ni esin rere ati daradara igbagbo ati laada aye ati ti orun fun eni ti o ba n ki irun wakati maraarun daadaa. Ni ipase awon irun yii ni ibale okan ati ibale ara ti yoo je okunfa orire aye ati ti orun.
Origun keta: Itore aanu (zaka):
Eyi ni ore atinuwa kan ti eni ti o ba ni owo ti o ti wo gbedeke ti ilana ISLAM se afilele re yoo ma a san ni odoodun fun awon eni ti o leto si gbigba re ninu awon alaini ati awon miran to letosi, itore aanu yi ko je dandan fun alaini ti ko si gbedeke owo yii ni owo re.
Eni ti oje dandan fun ni awon olowo lati fipe esin won. Ti yoo si tun mu ilosiwaju ba iwasi won ati ihuwasi won pelu. Eyi si tun je ona kan pataki lati mu iyonu ati iyojuran aye kuro lara won ati lara dukia won. Ati lati se afomo fun won kuro nibi aburu, ati lati se ikunlowo fun awon talaka ati awon alaini lawujo won ati lati se igbeduro ohun ti yoo mu nkan tubatuse fun awon gan an alara paapaa. Paripari gbogbo re, oore aanu yii ko koja inkan kinkinni ninu ohun ti Olohun se fun won ninu owo ati ije-imu.
Origun kerin: Aawe:
Ohun naa ni gbigba aawe osu Ramadan alaponle, eyi ti se osu kesan ninu osu odun hijirah (odun ti a n fi osupa ka). Ninu osu yii ni gbogbo awon musulumi yoo se ara won ni osusu owo ti won yoo si kora duro nibii gbogbo ojukokoro won gege bi jije ati mimu ati biba iyawo eni lopo ni asiko osan. Iyen ni pe kikoraduro yo bere lati asiko idaji kutu (yiyo alufajari) titi di asale (asiko wiwo oorun). Olohun yoo fi gbigba awe yi boti ye pe esin won ati igbagbo won ati wipe yoo fi pa ese ati awon iwa tikodara re fun won, bakana yoo si se agbega fun won ati beebee lo ninu awon oore ninla laye ati lorun gegebi nkan daradara miran yoo ti je tiwon ninu awon oore nlanla ti o ti pa lese sile ni ile aye ati ni orun.
Origun karun: Irinajo si ile mimo (Haji):
Ohun naa ni gbigbera lati lo si ile Olohun alaponle lati lo josin fun Olohun ni asiko kan pato gegebi otise wa ninu ofin Islaam. Olohun ti see ni oranyan fun eni ti o ba ni agbara re ni eekan soso ni igbesi aye eniyan. Ninu asiko haji yii ni gbogbo musulumi jakejado aye yoo kojo si aaye ti o loore julo lori ile, ti won yoo maa se ijosin fun Olohun kan soso, ti won yoo si wo ewu orisikan naa. Ko nii si iyato laarin olori ati ara ilu, olowo ati mekunnu, funfun ati dudu ninu won. Gbogbo won yoo ma a se ise ijosin kan naa ti osi ni odiwon. Eyi ti o se koko julo ninu re ni diduro ni aaye ti a mo si “Arafat" ati rirokirika ile Oluwa (Kaaba) abiyi (ti oje adojuko gbogbo Musulumi ni asiko ijosin won) ati lilo bibo laarin oke Safa ati Moriwa. Awon anfaani aye ati orun olokan-o-jokan ti ko se e ka tan ni o wa ninu re.
IKETA : IHSAN;
eleyi tumo si pe ki ire Musulumi maa sin Olohun re pelu igbagbo ati esin ododo gegebi eniwipe oun wo O ni iwajure, biotileje pe ire kori I dajudaju Oun ri iwo. Bakanaa ki o rii daju wipe oun se ohun kohun ni ibamu pelu ilana(Sunnah) ojisee Re annabi Muhammad (ki ike ati ola Olohun o maa baa). Ki osi mase yapa si ilana naa.
Gbogbo ohun ti awiyi gan ni anpe ni ISLAM.
Bakan-naa ni ISLAM tun seto igbesi aye awon eni ti o gba a lesin yala ni igbati won ba wa ni eyo kookan ni, tabi nigbati won ba wa nijo nijo, osise ni ona ti orire aye ati torun yo o fi je tiwon. Nitori idi eyi ni o fi se fife iyawo ni eto fun won osi se won lojukokoro lo sibe. O si se sina sise ati iwa pansaga ni eewo fun won ati gbogbo awon iwa ibaje. Bee ni o si se dida ibi po ati sisaanu awon alaini ati talika ni oranyan pelu mimoju to won. Gegebi oti se ni oranyan tosi tun seni lojukokoro lo si ibi gbogbo iwa to dara ti o tun se iwa buruku lewo, gege bi o sen kini nilo kuro nibe. Siwaju sii, o se kiko oro jo lona mimo leto gegebii owo sise tabi yiyani ni nkan ati ohun ti ojoo. Ni idakeji ewe, ose owo ele (riba) ati gbogbo owo ti koleto ati ohun ti oba ti ni modaru tabi itanje ninu, o se won ni eewo.
Yato si ohun ti a ka siwaju yii, ISLAM se akiyesi aidogba awon eniyan ninu diduroto si oju ona ilana re ati kikiyesi eto awon eniyan miran. Nitori-idi-eyi ni o fi gbe awon ijiya amunisakuro-nibi-ese kale fun titayo aala ti o ba sele ninu awon eto Olohun oba Mimo; gegebii: pipada sinu keferi leyin igba ti o ti gba ISLAM ati sise sina, ati mimu oti ati bee bee lo. Gege bee ni o gbe awon ijiya adanilekun kale fun titayo ala si awon eto omo niyan gegebii: tita ejesile sise owo basubasu,sise dukia awon eniyan bi kotiseye, titayo aala nipa pipa eniyan tabi ole jija tabi piparo agbere mo elomiran tabi sise eda egbe eni ni suta, ati bee bee lo. O se pataki lati fi yewa pe awon ijiya kookan ti o fi lele yii se deede irufin kookan la isi aseju tabi aseeto nibe. ISLAM tun seto o si tun fi ala si ibasepo ti owa laarin awon ara ilu ati awon adari won. O si se titele awon adari ni dandan fun ara ilu ninu gbogbo ohun ti ko ba si sise Olohun ninu re. O si se yiyapa si ase won ati aigbo aigba fun won ni eewo nitori ohun ti o le tara eyi jade ninu awon iyonu ati ruke rudo fun terutomo ati tiletoko.
Ni ipari, a le e fowogbaya re pe ISLAM ti kakoja nibi sise eto asepo ti o dara, ati ise ti o yanju laarin eru ati olohun re. Bakana laarin omo eda eniyan ati awujo ti o n gbe nibe, ati gbogbo oran re. Kowa si rere kan ninu awon iwa ati awon ibalo ayafi ki o je pe o ti se ifinimona awon eniyan lo sibe ki o si se won lojukokoro si. Bee si ni ko si aburu kan ninu awon iwa ati awon ibalo ayafi ki o je pe o ti ki awon eniyan nilo gidigidi nipa jin jinna si.Eyi ni o fi wa han gbngba pe esin ti ko labujeku kankan ninu ni ISLAM je, esin ti o si dara ni pelu ti a ba gbe ye wo ni gbogbo ona.
Eyin fun Olohun oba oluse akoso gbogbo agbanla aye.