Description
Iṣẹ́-rírán kan ṣoṣo pere!
Awon ogbifo miran 53
Dokita Naaji ọmọ Ibrọ̄hīm Al-'Arfaj
Fun gbogbo oluṣewadii nipa ododo pẹlu ootọ ati imọkanga
Fun awọn oni laakaye oloye
Ki ni a gba lero pẹlu iṣẹ-riran kan yìí?
Ki ni iwe mimọ n sọ nipa rẹ?
Ki ni Kuraani n sọ nipa rẹ?
Ki ni o ri si i lẹyin iyẹn?
Lẹyin ṣiṣẹda Adam, wọn gbé ojúlówó iṣẹ́-rírán kan wá bá awọn eniyan nipasẹ itan ẹda, ati nitori riran awọn eniyan leti pẹlu iṣẹ́-rírán yii ati dida wọn pada si oju ọna taara, Ọlọhun kan Ọba ododo ran awọn Anabi ati awọn Ojiṣẹ gẹgẹ bii: Adam ati Nuh ati Ibrọ̄hīm ati Musa ati Muhammad (Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba wọn) lati mu iṣẹ́-rírán kan ṣoṣo de etigbọọ gbogbo eniyan, oun ni pe:
Ọlọhun Òdodo ẹyọkan pere ni, ki ẹ jọsin fun Un
O ran lati mu iṣẹ́-rírán yii de etigbọọ gbogbo eniyan:
Nuh " Ọlọhun yin Ọlọhun ọkan ṣoṣo ni, ẹ jọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo "
Ibrọ̄hīm " Ọlọhun yin Ọlọhun Ọkan ṣoṣo ni, ẹ jọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo "
Musa " Ọlọhun yin Ọlọhun Ọkan ṣoṣo ni, ẹ jọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo "
Isa " Ọlọhun yin Ọlọhun Ọkan ṣoṣo ni, ẹ jọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo "
Muhammad " Ọlọhun yin Ọlọhun Ọkan ṣoṣo ni, ẹ jọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo "
Ọlọhun ti ran awọn oni ipinnu ọkan ninu awọn Ojiṣẹ ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn ti a mọ ati awọn ti a ko mọ ninu awọn Anabi Rẹ ati awọn Ojiṣẹ Rẹ lati jẹ ọpọlọpọ iṣẹ, ninu wọn ni:
Gbigba imisi ti Ọlọhun ati mimu u de etigbọọ awọn ijọ wọn ati awọn olutẹle wọn
Kikọ awọn eniyan ni imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo ati mimọ ijọsin kanga fún Ọlọhun
Ṣíṣe àfihàn àwòkọ́ṣe dáadáa ni ti ọrọ ati ni ti iṣe, lati le jẹ ki awọn eniyan kọ́ṣe wọn nibi oju ọna wọn lọ si ọdọ Ọlọhun
Dida oju awọn olutẹle wọn kọ ibẹru Ọlọhun ati itẹle Rẹ ati titẹle awọn àṣẹ Rẹ
Kikọ awọn olutẹle wọn ni awọn idajọ ati awọn eyi ti o daa julọ ninu awọn iwa
Itọsọna awọn oluyapa ati awọn ọṣẹbọ ninu awọn olujọsin fun awọn ooṣa ati awọn ti wọn yatọ si wọn
Ìmúdé etigbọọ awọn eniyan pe wọn yoo gbe wọn dide lẹyin iku wọn, wọn yoo ṣe iṣiro fun wọn ni ọjọ igbedide lori awọn iṣẹ wọn, ẹnikẹni ti o ba ni igbagbọ ninu Ọlọhun nikan ṣoṣo ti o si ṣiṣẹ rere, ẹsan rẹ ni alujanna, ẹnikẹni ti o ba ṣẹbọ pẹlu Ọlọhun ti o si yapa, ibudesi rẹ ni ina
Dajudaju awọn Anabi wọnyi ati awọn Ojiṣẹ, Ọlọhun kan ṣoṣo ni O ṣẹda wọn ti O si ran wọn niṣẹ. Dajudaju aye ti oun ti nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu awọn ẹda n sọ nípa bibẹ Ọlọhun Aṣẹda, ti wọn si n jẹrii si ijẹ Ọkan ṣoṣo Rẹ; nitori naa Ọlọhun ni Aṣẹda aye ati nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu ẹda ati awọn ẹranko ati awọn kokoro. Oun ni Aṣẹda iku ati iṣẹmi ti o maa tán ati iṣẹmi gbere
Dajudaju awọn iwe mimọ ti wọn n bẹ lọdọ awọn Juu awọn awọn Kristẹni ati awọn Musulumi, gbogbo wọn n jẹrii si bibẹ Ọlọhun ati mimu U ni Ọkan ṣoṣo
Dajudaju oluwadii nipa ododo, ti o bá kọ agbọye nipa Ọlọhun pẹlu òtítọ́ ati imọkanga ninu iwe mimọ ati Kuraani Alapọn-ọnle, yoo le ṣe iyatọ awọn iroyin ti aaso ti o jẹ ti Ọlọhun nìkan, ti ẹni ti o yatọ si I ko nii ba A kẹgbẹ nibẹ ninu awọn ooṣa ti wọn gba lero. Eleyii ni diẹ ninu awọn iroyin yẹn:
Ọlọhun Ododo, Aṣẹda ni, wọn ko dá A
Ọlọhun Ododo, Ọ̀kan ṣoṣo ni, ko si orogun fun Un, kò sì pọ̀, ko bimọ, wọn ko bi I
Ọlọhun mọ kuro nibi èrò ẹda, awọn oju ko lee ri I ni aye
Ọlọhun ko ni ibẹrẹ tabi opin, ko nii ku, ko si nii bọ́ si ara nkankan, ko si nii fi ara hàn ninu ẹda Rẹ kankan.
Ọlọhun ni Àjíronúkàn ti O da duro fun ara Rẹ, ti O rọrọ kuro lọdọ ẹda Rẹ, ti ko ni bukaata si wọn, ko ni baba tabi iya, iyawo tabi ọmọ, ko ni bukaata si oúnjẹ tabi mimu tabi ikunlọwọ lati ọdọ ẹnikẹni, ṣugbọn awọn ẹda ti Ọlọhun da ni bukaata si I
Ọlọhun da ni awọn iroyin titobi ati pipe ati ẹwa ti ẹnikẹni ninu ẹda Rẹ ko ba A kẹgbẹ tabi jọ Ọ nibẹ, ko si nǹkan kan bii iru Rẹ
Lilo awọn òṣùwọ̀n ati awọn iroyin yii (ati eyi ti o yatọ si wọn ninu awọn iroyin ti Ọlọhun da ni ni Oun nikan ṣoṣo) rọrun fun wa lati pe ni irọ ati lati kọ ami awọn ọlọhun ti wọn gba lero
Ni bayii, ẹ jẹ ki n pada lati ṣe iwadii iṣẹ́-rírán ẹyọkan naa ti a darukọ si oke rẹ ati lati fa jade apakan awọn ọrọ Ọlọhun ninu iwe mimọ ati Kuraani ti o n kanpa mọ ijẹ-ọkan-ṣoṣo Ọlọhun. Ṣugbọn ṣiwaju iyẹn, mo fẹ lati pin ero yii pẹlu yin:
Awọn kan ninu awọn Kristẹni le maa ṣe eemọ ti wọn yoo maa beere pe: Ninu nnkan ti o han ni pe ẹyọkan ni Ọlọhun, awa naa ni igbagbọ ninu Ọlọhun kan ṣoṣo, ki wa ni o ṣẹlẹ?
Òtítọ́ ni pe ni ipasẹ ẹ̀kọ́ mi ati kika ti mo kà gan nipa ẹsin Kristẹni ati ifọrọwerọ mi ti o pọ pẹlu awọn Kristẹni, mo ri pe "Allahu" lọdọ wọn (ni ibamu si èrò àwọn kan ninu wọn) o ko nnkan ti o n bọ yii sinu:
Ọlọhun baba
Ọlọhun ọmọ
Olohun ẹ̀mí mímọ́
Dajudaju òtítọ́ ti o han kedere ti o rọrun ati làákàyè ti o ni alaafia, méjèèjì yóò ti oluwadii ti kii ṣe ojúsàájú lọ sí ibi bibeere lọwọ awọn Kristẹni wọnyi pé:
Ki ni itumọ ọrọ yin pe "Ọlọhun jẹ ọkan ṣoṣo" ti ẹ si n tọka si ọlọhun mẹta?
Njẹ ẹyọkan ni Ọlọhun ti O bọ́ sára nǹkan mẹta ni abi mẹta ni ti O bọ́ sára nǹkan ẹyọkan (ọkan ninu mẹta abi mẹta ninu ọkan)?
Ni afikun si eyi, ati nibamu si apakan adisọkan awọn Kristẹni, awọn iṣẹ kan ati awọn bibẹ kan ati awọn aworan ọtọọtọ n bẹ fun awọn ọlọhun mẹtẹẹta yii gẹgẹ bi o ṣe n bọ yii:
Ọlọhun baba = Oun ni Aṣẹda
(Ọlọhun ọmọ = oun ni olùlani) olugbala)
Ọlọhun ẹmi mimọ = oun ni olubadamọran (olufunnilagbara)
Dajudaju ero pe Al-Maseeh ni ọmọ Ọlọhun tabi oun ni Ọlọhun tabi apakan ninu Ọlọhun, o tako nǹkan ti awọn ọrọ Taorāh ati Injil fi rinlẹ pátápátá, nigba ti o la a mọlẹ pe dajudaju ẹnikẹni ko lee ri Ọlọhun ni aye:
"Dájúdájú ẹyin ko gbọ ohun Rẹ rárá, ẹ ko si ri oju Rẹ"
Jòhánù 5:37
"Ẹnikẹni ko ri I rara, ẹnikẹni ko si nii ni ikapa lati riri I"
Lẹ́tà kìíní sí Tímótì 6:16
"Ẹnikẹni ko lee ri mi ki o si wa ni alaaye"
( Ẹ́kísódù 20:33)
Ni ibamu si awọn ọrọ Ọlọhun yii ati eyi ti o yatọ si wọn, mo n ṣe eemọ ni ẹni ti o n beere pẹlu gbogbo òtítọ́ ati ifọkantan pe bawo ni a ṣe maa jẹ ki ọ̀rọ̀ awọn ti wọn n sọ pe dajudaju Isa ni Ọlọhun wà ni ìbámú pẹ̀lú awọn ọrọ iwe mimọ ti wọn n fi rinlẹ pe ko si ẹnikẹni ti o ri Ọlọhun tabi ti o gbọ ohun Rẹ?!
Ṣe kii ṣe pe awọn Juu ati awọn ẹbi Isa ati awọn olutẹle rẹ ri Isa Al-Maseeh (ọlọhun ti ọmọ, gẹgẹ bi àwọn kan nínú wọn ṣe n lérò ti wọn si gbọ ohun rẹ ni àsìkò yẹn ni)?
Bawo ni Taorāh ati Injil ṣe maa fi rinlẹ pe dajudaju Ọlọhun ẹnikẹni ko lee ri I tabi gbọ Ọ, lẹyin naa ki a tun wa ri ẹni ti o maa lero pe Isa ti wọn ri bi o ṣe ri ti wọn si gbọ ohun rẹ ni Ọlọhun tabi ọmọ Ọlọhun? Njẹ àṣírí kan ti o pamọ n bẹ ti o so pọ mọ paapaa Ọlọhun ni bi?
Dajudaju Taorāh n kanpa mọ idakeji iyẹn, torí pé ó wà nínú rẹ pé Ọlọhun sọ pe: Dajudaju Emi ni Oluwa ti ko si Ọlọhun miiran. Ati pe Emi ko sọrọ pẹlu àṣírí, Mi o si ṣe afojusun mi ni nnkan ti o pamọ..dajudaju Emi ni Ọlọhun ti Mo n sọ ododo, ti Mo si n kede ohun ti o jẹ ododo." (Aísáyà 19:45)
Mo n rọ ẹ, ka ọrọ Ọlọhun ti o ṣaaju ni àkàtúnkà, ki o si ronu nipa rẹ fun igba ti o pẹ
Ni bayii, ki a jọ gbéra papọ̀ lati ṣe ìrìn-àjò fun iwadii nipa paapaa Ọlọhun ninu iwe mimọ ati Kuraani Alapọn-ọnle, ti mo si n fẹ ki ẹ fun mi ni irori yin ati awọn nnkan ti ẹ ri si i lẹyin ti ẹ ba ti ronú jinlẹ si awọn aayah ati awọn ọrọ Ọlọhun, ti ẹ si ka iwe kékeré yii ni kika ti ṣiṣe lámèyítọ́ ti ko si ojúsàájú ninu ẹ.
Láìní ṣe ojúsàájú, maa pada ṣe àfihàn àwọn ẹri láìní ṣe àwílé kankan, ni ẹni tí n rankan ironujinlẹ si i láìsí ojúsàájú, ti awọn èrò kankan tabi idajọ ti o ṣaaju ko nii ròpọ̀ mọ́ ọn
Ọlọhun Ọkan ṣoṣo Ọba ododo ninu iwe mimọ (Majẹmu Lailai):
Gbọ, Israeli: Oluwa Ọlọrun wa Oluwa kan ni.
(Diutarónómì 4:6)
Ṣe kii ṣe pe Ọlọhun Ọkan ṣoṣo ti da ẹ̀mí iṣẹmi fun wa ni, ti O si n pèsè fun wa?
(Málákì 15:2)
Ki ẹ le mọ ki ẹ si ni igbagbọ ninu Mi, ki ẹ si mọ pe dajudaju Emi ni Ọlọhun, ti ko si ọlọhun kankan ṣiwaju Mi, ti ko si lee si lẹyin Mi lailai. Emi ni Oluwa, ti ko si olugbala kankan yatọ si Mi
(Aísáyà 43:10-11)
Emi ni Akọkọ ati Ikẹyin ti ko si ọlọhun kankan yatọ si Mi. Ta ni o da bii Emi?
(Aísáyà 44:6)
Ṣe Emi kọ́ ni Oluwa ni ti ko si ọlọ́hun kankan yatọ si Mi? Ọba daadaa ati Olugbala, ti ko si ẹlomiran
(Aísáyà 45:21)
Njẹ o le sọ awọn ọrọ Ọlọhun miran ti wọn da bii wọn
Ọlọhun Ọkan ṣoṣo Òdodo ninu iwe mimọ (Májẹ̀mú Tuntun):
Ìyè àìnípẹ̀kun ni láti mọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, àti Jésù Kristi ẹni tí ìwọ rán.
(Johanu 3:17)
Ẹ jọsin fun Ọlọhun Ọlọhun yin, ki ẹ si sìn ín nikan
(Mátíù 10:4)
Gbọ́, ìwọ Israẹli: Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni...Ọlọ́run kan ṣoṣo ni, kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn Rẹ̀
(Máàkù 12:28-33)
Ọ̀kan ni Ọlọ́run, ọ̀kan sì ni alárinà láàárín Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn, òun sì ni ọkùnrin náà Kristi Jésù
(Lẹ́tà kìíní sí Tímótì 5:2)
Ọkan ninu wọn tọ̀ ọ́ wá, o si wipe, Oluwa rere, kini ohun rere ti emi yóò ṣe lati ni ìyè ainipẹkun? O (Jesu) dahun pe: ((Ki ni ìdí ti ẹ fi n pe mi ni ẹni rere? Ko si ẹni rere kan ayafi ẹnìkan, Oun naa ni Ọlọhun). ( Ìhìn Rere Mátíù 19:16-17 gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì King James Version )
Njẹ o le sọ awọn ọrọ Ọlọhun miran ti wọn n jẹrii si pe Ọlọhun Ọkan ṣoṣo ni? (Kii sii ṣe mẹta! )
((Sọ pé: "Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo. Allāhu ni Aṣíwájú (tí ẹ̀dá ní bùkátà sí, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn. Kò bímọ. Wọn kò sì bí I. Kò sì sí ẹnì kan tí ó jọ Ọ́.))
(Surah 113: Aayah 1-4
((Dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi))
(Surah 21: Aayah 25)
((Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn t'ó wí pé: "Dájúdájú Allāhu ni Ìkẹta (àwọn) mẹ́ta." Kò sì sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Tí wọn kò bá jáwọ́ níbi ohun tí wọ́n ń wí, dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro l'ó máa jẹ àwọn t'ó di kèfèrí nínú wọn))
(Surah 5: Aayah 73)
((Dájúdájú Ọlọ́hun yín, Ọ̀kan ṣoṣo ni;))
(Surah 37: Aayah 4)
((Ṣé ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: "Ẹ mú ẹ̀rí yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo))
(Surah 27: Aayah 64)
Ni òtítọ́, dajudaju iṣẹ́-rírán yii (Imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo) jẹ akori ipilẹ ninu Kuraani Alapọn-ọnle
Dajudaju awọn ọrọ Ọlọhun yii ati eyi ti o yatọ si wọn ninu awọn ọgọrọọrun ẹri ninu iwe mimọ ati Kuraani n jẹrii si pe dajudaju Ọlọhun Ọkan ṣoṣo ni láìsí iyèméjì, ti ko si si ọlọ́hun miran ti o yatọ si I, gẹgẹ bi Bibeli ti sọ, "Gbọ, Israeli: Oluwa Ọlọrun wa Oluwa kan ni. Ọ̀kan ni Ọlọrun, kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn Rẹ̀.
"( Máàkù 8:12-33)
Kuraani Alapọn-ọnle n sọ nipa alamọri yii ninu ọrọ Rẹ pe:
(Sọ pé: "Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo)
(Surah 113: Aayah 1)
Iwe mimọ ko jẹ́rìí si pe Ọlọhun jẹ Ọkan ṣoṣo nikan, bi ko ṣe pe o tun n jẹrii si pe Ọlọhun ni Aṣẹda ati Olugbala Kan ṣoṣo
Ki ẹ le mọ ki ẹ si ni igbagbọ ninu Mi, ki ẹ si mọ pe dajudaju Emi ni Ọlọhun, ti ko si ọlọhun kankan ṣiwaju Mi, ti ko si lee si lẹyin Mi lailai. Emi ni Oluwa, ti ko si olugbala kankan yatọ si Mi
(Aísáyà 43:10-11)
Pẹlu iyẹn, yoo fi oju han pe sísọ pe Ọlọhun ni Isa tabi pe Ọlọhun ni ẹmi mimọ, tabi ohun ti o yatọ si mejeeji, ọ̀rọ̀ ti ko fi ẹsẹ múlẹ̀ ni, ti ko si ni ẹri, wọn ko jẹ nnkan kan afi awọn ẹda kan ninu ẹda Ọlọhun, ti ko si si ohun ti o kan wọn ninu ọ̀rọ̀ náà, wọn kii ṣe ọlọhun tabi ìyípadà ológo fun Ọlọhun tabi igbe awọ wọ tabi aṣojú fun Un. Ko si nnkan kan bii iru Rẹ ni ibamu si nnkan ti iwe mimọ ati Kuraani Alapọn-ọnle sọ
Ọlọhun ti binu si awọn Juu pẹlu okunfa anu wọn ati ijọsin wọn fun awọn ọlọhun kan ti wọn yatọ si I
"Ibinu Ọlọhun le koko lori wọn"
(Nọmba 25:3)
Musa- ki ọla Ọlọhun maa ba a- sì rún ọmọ màlúù wúrà wọn
Àmọ́, ikọ̀ àwọn ti wọn mu Ọlọhun ni Ọkan nínú àwọn Kristẹni fi ara da iya; nitori pe wọn ni igbagbọ ninu imu Ọlọhun ni ọkan, ti wọn sì kọ jíjìrọ̀ awọn ẹkọ Isa ti o dúró déédéé (ti o jẹ ti imú Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo) ti wọn tako adadaalẹ Mẹ́talọ́kan ti o han lati ọwọ Pọ́ọ̀lù ati awọn olutẹle rẹ
Kókó ọrọ naa ni pe Ọlọhun ran Adam ati Nuh ati Ibrahim ati Musa ati Isa ati Muhammad ati gbogbo awọn Anabi ati Ojiṣẹ (ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba gbogbo wọn lapapọ) fun pipe awọn eniyan sibi nini igbagbọ ninu Ọlọhun ati mimọ ijọsin kanga fun Un ni Òun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un tabi akẹgbẹ fun Un (mimọ ni fun Un). Eleyii ni iṣẹ́ kan ṣoṣo ti a ran wọn:
Ọlọhun Ọba Ododo ẹyọkan péré ni; nitori naa, ẹ jọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo
Ati pe níwọ̀n ìgbà ti o ṣe pe iṣẹ́-rírán awọn Anabi ati awọn Ojiṣẹ jẹ ọkan; nitori idi eyi, ọ̀kan ni ẹsin wọn. Ti o ba ri bẹ́ẹ̀, ki ni ẹsin awọn Anabi ati awọn Ojiṣẹ wọnyi?
Dajudaju kókó iṣẹ́-rírán wọn dá lori ijupa-jusẹ sílẹ̀ fun Ọlọhun, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ ti o n sọ nípa itumọ "Isilaamu" ati agbọye rẹ ninu ede larubawa
Kuraani Alapọn-ọnle ti fi rinlẹ pe Isilaamu ni ẹsin ododo fun gbogbo àwọn Anabi Ọlọhun ati awọn Ojiṣẹ Rẹ, a le tọ ipasẹ ododo ti Kuraani yii ninu iwe mimọ bákannáà (a maa pada tọ ipasẹ ododo yii ninu iwe mimọ ninu iwe pelebe ti o n bọ ti Ọlọhun ba fẹ)
Ni ipari, o jẹ dandan fun wa ti a ba fẹ ri igbala lati gba iṣẹ́-rírán yii ati nini igbagbọ ninu rẹ pẹlu ododo ati imọkanga. Ṣugbọn iṣẹ yii ko to ni oun nikan! Bi ko ṣe pe o jẹ dandan fun wa bakannaa nini igbagbọ ninu gbogbo awọn Anabi ati awọn ojise Rẹ (Ìyẹn ko nini igbagbọ ninu Anabi Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sinu) ati titẹle imọna wọn ati ṣíṣe iṣẹ pẹlu rẹ. Oun ni oju ọna si iṣẹmi gbere ti oriire
Irẹ ti o n ṣe iwadii nipa ododo pẹlu imọkanga ti o si nífẹ̀ẹ́ si igbala, bóyá waa le ronu si alamọri yii ki o si woye si i nsinyii ati ṣiwaju ki asiko tó bọ́, ṣiwaju iku ti o maa n de lojiji! Ta ni o mọ igba ti yoo de?
Lẹyin ironu jinlẹ ati atunro nibi alamọri ti o ṣe koko ti o jẹ ti onipinnu yii, ati pẹlu laakaye ti o ni agbọye ati pẹlu ọkan ti ododo, o ni ikapa lati fi rinlẹ pe Ọlọhun Ọkan ṣoṣo ni ti ko si orogun fun Un tabi ọmọ, o tun ni ikapa lati ni igbagbọ ninu rẹ, ti waa si jọsin fun Un ni Òun nikan ṣoṣo, ti waa si ni igbagbọ pe Muhammad Anabi ni, Ojiṣẹ si ni, gẹgẹ bii Nuh ati Ibrọ̄hīm ati Musa ati Isa
Ni bayii o rọrun fun ẹ lati pe- ti o ba fẹ- gbolohun yii:
Ash-hadu an laa ilaaha illallohu wa ash-hadu anna Muhammadan rọsuulullah
Ijẹrii yii ni igbesẹ ti afisiṣẹse akọkọ lori oju ọna si iṣẹmi gbere ti oriire, oun ni ojúlówó kọ́kọ́rọ́ fun awọn ilẹkun alujanna
Ti o ba ti pinnu lati gba oju ọna yii, o rọrun fun ẹ lati wa ikunlọwọ ọrẹ rẹ tabi aládùúgbò rẹ ti o jẹ Musulumi, mọsalasi ti o sunmọ julọ tabi ààyè ìpolongo Isilaamu, tabi ki o pe mi lórí ago, tabi ki o kọ lẹ́tà si mi (inu mi maa dun pupọ si iyẹn).
(Sọ pé: "Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu l'Ó ń ṣàforíjìn gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. Ẹ ṣẹ́rí padà (ní ti ìronúpìwàdà) sí ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Un ṣíwájú kí ìyà náà t'ó wá ba yín. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́. Kí ẹ sì tẹ̀lé ohun tí ó dára jùlọ tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fun yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ṣíwájú kí ìyà náà tó wá ba yín ní òjijì, nígbà tí ẹ̀yin kò níí fura)
Kuraani Alapọn-ọnle - Surah 39: Aayah 53-55
Lẹyin kika iṣẹ́-rírán kan ṣoṣo yii ni àkàgbọ́yé ti àronúsí, àwọn olóòótọ́ àti àwọn ti wọn mọ nǹkan ti wọn n ṣe lè béèrè pé: Kí ni òtítọ́, kí ni kò tọ́, kí ni kí a ṣe?
Mo maa sọrọ nípa àwọn ìbéèrè yii ati awọn mìíràn ninu awọn ìwé mi ti n bọ̀, ti Allāhu ba fẹ́.
Fun alekun ìsọfúnni, tabi ibeere tabi àbá, dakun má ṣe iyèméjì láti kàn si onkọwe lori adirẹsi ti o n bọ yii:
P.O. Box 814 - Al-Hufuuf - Al-Ahsaau 31982 Saudi Arabia.. [email protected] / "[email protected]
Tabi ọfiisi...........
Aaye wa fun eyikeyii àyípadà tabi àtúnṣe
Ti o ba ri bẹẹ, ki ni ododo gan?