×
New!

Bayan Al Islam Encyclopedia Mobile Application

Get it now!

AKASO ODODO (Al- WASEELAH) (Èdè Yorùbá)

Pípèsè: Ishaaq bn Ahmad al Ilaalawi

Description

Idanileko yii so nipa ohun ti a npe ni akaso ododo tabi wiwa ategun si odo Olohun eyi ti esin Islam pawa lase re. Oro die waye nipa awon eri lori bi a tise nwa ategun ati die ninu asise ti apakan ninu awon Musulumi maa nse

Download Book

Awon ogbifo miran 1

    AKASO ODODO (Al- WASEELAH)

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Ishaaq bn Ahmad al Ilaalawi

    Atunyewo: Rafiu Adisa Bello

    2013 - 1434

    التوسل المشروع

    « بلغة اليوربا »

    إسحاق بن أحمد الإلالوي

    مراجعة: رفيع أديسا بلو

    2013 - 1434

    AKASO ODODO (AL WASEELAH)

    Al –waseelah ni gbolohun ede Arab ti o tumo si akaso tabi ona isunmo. Gbolohun naa waye ni ona meji pere ninu al Qur'aan Abiyi; suurah Maaidah, aayah 35 ati Suurah Israa', aayah 57.

    Ninu Suurah Maaidah, Olohun so pe:

    ﴿ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱبۡتَغُوٓاْ إِلَيۡهِ ٱلۡوَسِيلَةَ وَجَٰهِدُواْ فِي سَبِيلِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ ٣٥ ﴾ [المائدة: ٣٥]

    “ Mo pe eyin onigbagbo ododo, e beru Olohun, e wa akaso si odo Re ki e si jagun si oju ona Re nitori ki e le jere." Ese ketedinlogota ninu Suuratil Israa' lo bayi pe: “ –awon alujonu ti awon alaigbagbo nkee pe- nwa ona lati sunmo odo Oluwa won…"

    Ibeere ti o n fe idahun ni pe:

    1- Kini a le fi se akaso si odo Olohun?

    2- Akaso wo ni Olohun pase pe ki a wa?

    Akaso ti Olohun pe wa si ni ki a sunmo odo Re. Ohun ti a si le fi sunmo Olohun ni itele ase Re ati itakete si aigboran ati iwa ese gege bi itoka awon onimo Tafseer. Ninu ohun ti o je ki itumo won yii fidi munle ni itan ti Ojisenla Muhammad- Alaafia ati ike Olohun fun un- pa fun awon omo leyi re nipa awon ijo isaaju. Itan naa ni kukuru lo bayi pe:

    Ona di mo awon eniyan meta kan ti won wa ni ori irin-ajo, won sa si inu apata kan, apata naa si panude mo won ti won ko lee jade.

    Ninu isoro ti won wa yii won ronu ona ti won lee fi wa akaso si odo Olohun nitori ki ona o le la, won si ri i pe ona abayo ni ki awon be Olohun pelu ola ise rere ti awon ti se siwaju Olohun.

    Okan ninu won je omo rere si awon obi re o si fi jije omo rere naa se akaso si odo Olohun, apata naa si lanu die. Ikeji won je olowo onisowo ti kii je egun mo iyan. O be Olohun pelu bi o ti se toju owo agbasese re ati eni ori re. Olohun gbaa, apata si tunbo lanu sii. Eniketa se iranti bi ohun se segun Esu ti o fe je ki oun se agbere ati bi ohun se segun re pelu iberu Olohun ni aaye ti enikan ko ti ri i. O fi ola ipaya ikoko yii be Olohun, apata sipaya, won jade won si moribo kuro ninu isoro naa.

    Leyin ti a ti mo akaso ododo ti a n fi ola re be Olohun, oro to ku ti yoo so ara re nipe, Ola Anabi nko? Ola Musa ati Isa nko? Ola Shehu lagbaja nko? Nje o leto ki a maa fi ola won se akaso si odo Olohun?

    Ni otito ati ododo, Olohun da awon Anabi re lola ni orisirisi ona. O si fi ola ti o ga julo fun Anabi wa Muhammad- Alaafia ati ike Olohun fun un- sugbon Olohun ko se e ni ilana fun awa erusin Re ki a maa fi ola won se adua. Gbogbo eri ti o toka sii ni o gba ayewo fini fini. Fun asepe ise, a o toka si die ninu awon egbawa naa:

    1) E FI OLA MI SE AKASO SI ODO OLOHUN; TORIPE OLA MI TOBI PUPO NI ODO OLOHUN.

    2) ANABI AADAM SE ADUA O SO PE MO BE IRE OLOHUN PELU OLA ANABI MUHAMMAD.

    Gbogbo awon ojogbon-islam ti won se iwadi eri oro meji isaaju yii ni won panupo pe: AGBELERO NI EGBAWA TI O SO PE ANABI AADAM FI OLA ANABI SE ADUA. Ninu eri oro won nipe OPURO ATI ALAGBELERO ORO NI ABDUR RAHMAAN BN ZAYD ti o hun egbawa hadith yii. Bakanaa ni won royin egbawa alakoko pe o mehe, osi le pupo. Ninu awon onimo hadith yii ni Al Bayhaqi, Ibnu Katheer, Ibnu Hajar al 'Asqolaani ati awon miran.

    Bi a ba tun wo inu itan awon sahaabah, omoleyin ojisenla iyonu Olohun fun won, yoo farahan gbangba pe, won ko fi ola Anabi se adua yala ni oju aye re tabi leyin ti o ti jepe Olohun. Eri oro wa nipe nigbati oda da ni oju aye Anabi Muhammad- Alaafia ati ike Olohun fun un- won so fun un ki o se adua ki ojo ro. Ojisenla be Olohun ojo si ro fun ojo meje gbako. Oda tun da won ni asiko Umar, leyin ipapoda Ojisenla, won gbera won lo si odo Abbaas won so fun un pe ki o se adua ki ojo lee ro. Olohun gbo adua naa, ojo ro ara si de won.

    Ni ipari, koko oro ti a o di mu nipe:

    1- Eto ni fun elesin Islaam ki o se akaso si odo Olohun ninu adua re pelu;

    a- Oruko Olohun ti o rewa ati oriki Re ti o ga julo.

    b- Ise rere ti o ti se siwaju Olohun.

    c- Adua ti musulumi egbe re ba se fun un.

    2- Agbelero ni gbogbo egbawa ti o so pe ki a fi ola Anabi se adua.

    3- Ika ko dogba, Olohun se ola fun enikan ju elomiran. Sibe sibe eewo ni ki a fi ola elomiran se adua. Dipo bee, beere fun ola lodo Olohun Ti O nsola fun eniti o ba wu ﷻ‬.

    4- Ranti mi si rere ninu adua re. Olohun yoo se amona wa.

    معلومات المادة باللغة العربية