×

وجوب الاعتصام بالكتاب والسنة (يوربا)

إعداد: Rafiu Adisa Bello

الوصف

إن الاعتصام بكتاب الله وسنة رسوله - صلى الله عليه وسلم - أقوى أسباب النجاة للعبد في الدنيا والآخرة. وهذه مقالة بلغة اليوربا تبين أنه بالاعتصام بهذين الأصلين فاز سلف هذه الأمة برضا الله في الدارين، كما كانوا بعيدين كل البعد عن الشقاوة وجميع أسبابها، ولن يصلح آخر هذه الأمة إلا بما صلح به أولها.

تنزيل الكتاب

    DANDAN NI FUN MUSULUMI LATI MAA SERI SI IBI

    AL-KURANI ATI SUNNA

    LORI ORO ESIN

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Rafiu Adisa Bello

    2013 - 1434

    وجوب الاعتصام بالكتاب والسنة

    « بلغة اليوربا »

    رفيع أديسا بلو

    2013 - 1434

    DANDAN NI FUN MUSULUMI LATI MAA SERI SI IBI AL-KURANI ATI SUNNA

    LORI ORO ESIN

    Siseri sibi Al-kurani ati sunna ati diduro sinsin pelu won ni okunfa ola ati oriire fun gbogbo ijo Musulumi patapata, ohun naa ni o si je iso fun won kuro nibi orisirisi adanwo, nitoripe gbogbo aburu patapata ohun ti o n se okunfa re naa ni gbigbunri kuro nibi esin Olohun ati awon ofin Re, erenje ati opin oriire si wa nibi amojuto esin Olohun ati awon ofin Re.

    Sheikh Ibn Taemiyya- ki Olohun maa ke e- so wipe: "Gbogbo eni ti o ba n pepe sibi esin lai mu oro esin naa lati inu tira Olohun Al-kurani ati Sunna Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- irufe eni bee ti pepe sibi adadasile ati ona anu. Gbogbo eni ti o ba n se esin tabi o nso fun elomiran nipa oro esin ti o ba ti je wipe Al-kurani ati sunna ni o di mu sinsin, kosi iye meji wipe Olohun yoo fi eni naa mo ona ti o to. Dajudaju awon ofin esin da gege bi i oko oju omi ti Anabi Nuuhu kan ni igba aye re ti o je wipe eni ti o ba gun un yoo la, eni ti o ba si fi sile ti ko gun un yoo teri" [1].

    Nigbati o je wipe ohun ti o maa n se okunfa ki eniyan ye kuro ni ona ododo naa ni yiyapa Al-kurani ati Sunna, ohun ti yoo maa je iwosan arun yi nigba naa ni siseri pada sibi tira Olohun Al-kurani ati Sunna Ojise Re- ike ati ola Olohun ki o maa ba a. Eni ti o ba si fe wa iso kuro nibi ona anu yi ti ko fe ki ese oun ye kuro nibi ona otito ti o ti wa teletele ohun ti o dara julo lati fi wa iso fun iru eni bee naa ni diduro sinsin pelu tira Olohun Al-kurani ati Sunna Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a. Eni ti o ba woye si isesi awon eni isiwaju ninu esin (lati ori awon Saabe Ojise Olohun ati awon Taabi'uun ati awon ti won tele won ni oju ona rere) yoo ri aridaju wipe ohun ti o mu won la kuro nibi asiso ati asise ati ona anu naa ni wipe won duro sinsin pelu tira Olohun Al-kurani ati Sunna Ojise.

    Sheikh Ibn Taemiyya- ki Olohun ke e- tun so ni aaye miran wipe: "Ninu idera ti o ga julo ti Olohun se fun won (awon eni isiwaju ninu esin) naa ni wipe won je eni ti o duro sinsin pelu Al-kurani ati Sunna, eleyi si ni ipile kan ti afenuko wa lori re lati aye awon Saabe Ojise Olohun ati awon Taabi'uun ati awon ti won tele won ni oju ona otito. Won panu po wipe kosi aaye fun enikankan bi o ti wule ki o ri ki o yapa Al-kurani, yala pelu irori re ni tabi laakaye re tabi osunwon kan ti o gbe kale ni odo ara re. O si je ohun ti o rinle ni odo awon asiwaju wonyi pelu awon eri ti o daju ti o si gbopon wipe ohun ti Ojise Olohun mu wa lati odo Olohun naa ni ona ti o to ati esin ododo, ati wipe Al-kurani je olutosona sibi esin mimo esin ododo" [2].

    Olohun- mimo fun Un- ti se Al-kurani Alaponle ni iwe imona fun gbogbo eda, awon itoka ti o po ni o wa ninu tira naa lori wipe dandan ni fun Musulumi ki o duro sinsin pelu Al-kurani naa ati Sunna Ojise, bakannaa titele awon ase Olohun ati ti Ojise Re.

    Die ninu awon itoka naa niyi:

    Alakoko: Oro Olohun ti o so wipe: {E tele ti Olohun, e si tele ti Ojise naa, ki e si sora, ti e ba yi eyin pada ki e mo pe ise jije de opin nikan ni o je oranyan fun Ojise Wa} [Suuratu Maaida: 92].

    Eleekeji: Olohun- Oba mimo Oba ti O ga julo- tun so wipe: {Mo pe eyin onigbagbo ododo: E tele Olohun ki e si tele ti Ojise naa ati awon alase ninu yin, bi enu yin ko ba ko lori nkan kan laarin ara yin, e da a pada lo si odo Olohun ati Ojise naa, bi o ba je pe eyin gba Olohun gbo ati ojo ikeyin , eyi ni o dara julo ti o si san ni igbeyin} [Suuratu Nisaai: 59]. Imaam Ibn Kesiir- ki Olohun ke e- so nipa aaya yi wipe: "Mujaaid ati awon miran ninu awon eni isiwaju ninu esin so wipe: itumo eleyi ni wipe ki a seri gbogbo ohun ti ifanfa ba wa lori re lo sibi Al-kurani ati Sunna" [3].

    Eleeketa: Hadiisi ti a gba wa lati odo Ibn 'Abbaas- ki Olohun yonu si ohun ati baba re- o so wipe: Ojise Olohun ba awon soro nibi Haj idagbere, o wa so wipe: (Mo pe eyin eniyan, dajudaju mo ti fi awon nkan kan sile fun yin ti o je wipe ti e ba di won mu sinsin eyin ko le sonu lailai: Tira Olohun [Al-kurani] ati Sunna mi) [4].

    Eleekerin: Hadiisi ti o wa lati odo Jaabir bin Abdullah- ki Olohun yonu si ohun ati baba re- o so wipe: Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- maa n so ninu ibanisoro [Khutba] re bayi pe: (Leyinnaa, dajudaju eyi ti o loore julo ninu oro ni oro Olohun, imana ti o loore julo naa si ni imana ti Muhammad, eyi ti o si buru julo ninu oro esin naa ni adadasile, gbogbo adadasile si ni anu) [5].

    Itumo siseri sibi Al-kurani ati Sunna ati diduro sinsin pelu won naa ni pe ki Musulumi mo ni otito ati ni ododo wipe awon ipile mejeeji yi dandan ni ki ohun maa tele ohun ti o ba wa ninu won, ki o maa tele awon ohun ti won ba pase re, ki o si maa jinna si awon ohun ti won ba se ni eewo.

    Musulumi ko gbodo so pe Al-kurani nikan ni ohun gba gbo, sugbon nkan kan wa ni okan oun nipa Sunna Ojise, bikosepe oranyan ni ki o gba mejeeji gbo.

    Al-miqdaam bin Ma'ad-yekrib- ki Olohun yonu si i- so wipe: Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- so wipe: (E teti ki e gbo, dajudaju Olohun fun mi ni Al-kurani ati iru re miran pelu re. E teti ki e gbo, o ku saata [o fe e ya] ki okunrin kan jeun yo, ti yoo si fi eyin lele si ori aga agbantara re, ti yoo maa so pe: Ki e maa tele oro inu Al-kurani yi, ohun ti e ba ri ninu re ti o je eto [halaal] ki e se e ni eto, ohun ti e ba si ri ninu re ti o je eewo [haraam] ki e se e ni eewo) [6]. Afikun lori hadiisi yi ni odo imaam Tirmisi lo bayi pe: (Dajudaju ohun ti Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- ba se ni eewo gege bii ohun ti Olohun se ni eewo ni) [7].

    Agboye hadiisi yi ni wipe "Ojise Olohun n se ikilo fun awa Musulumi wipe ki a mase maa tapa si awon ofin ti o ba wa ninu Sunna sugbon ti a ko ri ninu Al-kurani, gege bi awon kan ninu awon ti won n se adadasile ninu esin ti maa n se, bi awon Khawaarij ati Rawaafidh, awon ti o se wipe won di ohun ti o wa ninu Al-kurani mu gedegbe, sugbon ti won lodi si ohun ti o wa ninu Sunna, ti o si je wipe Sunna yi ni o je alaye lekunrere fun Al-kurani, eleyi si se okunfa ki won ma mo paapaa ohun ti won n se, ti won si di eni anu" [8].

    Ayyuub Sakhtayaani- ki Olohun ke e- naa so wipe: "Ti iwo ba n ba eni kan soro nipa Sunna ti o wa so wipe: Fi eyiini sile ki o ba wa soro nipa ohun ti o wa ninu Al-kurani, ki o mo dajudaju pe irufe eni bee eni anu ti o si ma n so awon eniyan nu ni o je" [9].

    _______________________________________________

    Awon Tira Ti A Se Anfaani Ninu Won:

    [1] Dar'ut- Ta'arud: 1/234.

    [2] Majmuu' Fatawa: 13/28.

    [3] Tefsiir Ibn Kesiir: 1/518.

    [4] Muatta Maalik: 2/899. Mustadrak Haakim: 1/93. Mishkaatul- masoobih: 1/66.

    [5] Muslim: (Hadiisi: 867).

    [6] Sunan Abi Daauud: (Hadiisi: 4604). Sunan Tirmisi: (Hadiisi: 2663, 2664). Sunan Ibn Maja: (Hadiisi: 12, 13).

    [7] Sunan Tirmisi: (Hadiisi: 2664).

    [8] Ma'alimus-sunan: 7/7.

    [9] Al-kifaaya: 16.

    معلومات المادة باللغة الأصلية