Description
Oore ti o po pupo ni o wa nibi irun kiki fun Musulumi. Ohun ni ona ti o dara julo lati wa asunmo si odo Olohun, o si maa nse okunfa aforiji fun Musulumi, bakannaa ni o je oluranlowo fun erusin lati wo ogba idera (al-Jannah).
Ola Ti O Nbe Nibi Irun kiki
Ati Awon Anfaani Re
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Rafiu Adisa Bello
2013 - 1434
فضل الصلاة وفوائدها
« بلغة اليوربا »
رفيع أديسا بلو
2013 - 1434
OLA TI O NBE NIBI IRUN KIKI ATI AWON ANFAANI RE
Ninu egba oro kan ti o fi ese rinle okunrin kan ti oruko re nje Robi'ah omo Ka'ab al-Aslami so wipe: Mo maa nsun pelu ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- mo wa gbe omi ti yoo fi se aluwala ati nkan kan ti o ni bukata si wa fun un, o wa so fun mi wipe: {Beere ohun ti o ba fe}, mo si so wipe: Mo fe ki emi wa pelu re ninu ogba idera (al-Jannah), ojise Olohun tun so wipe: {Iwo ko ri nkan miran ti o le beere ni?}, mo wa so wipe: Ohun kan ti mo fe niyi. Nigba naa ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- wa so wipe: {Ti o ba ri bee, se iranlowo fun mi nitori ara re pelu opolopo iforikanle} [Muslim: 489].
Lai si iruju rara, o ye wa ninu hadiisi yi wipe ki erusin Olohun maa fi ori kanle ni opolopo je ohun ti yoo se okunfa ki o wo ogba idera (al-Jannah), aaye ti erusin Olohun si ti maa nfi ori kanle naa ni ibi irun kiki, eyi ti o fi han wa pe irun kiki je ona nla kan ti o gbooro ti o maa nmu eniyan wo ogba idera (al-Jannah).
Awon Anfaani ati oore nla ti o wa nibi irun kiki:
Pelu awon eri lati inu iwe mimo al-Kurani ati oro ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- a o maa toka si die ninu awon oore nla nla ti o wa nibi irun kiki ati awon anfaani ti o ga ti olukirun maa nri. Ninu awon anfaani naa niyi:
Alakoko: Irun kiki je ona ti o dara julo fun erusin Olohun lati wa asunmo si odo Olohun re, idi niyi ti Olohun fi so wipe: (Fi ori kanle [fun Olohun] ki o si sun mo On) [Suuratu 'Alaki: 19]. Ninu egba oro kan lati odo Abu Huraerah- ki Olohun yonu si i- ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- so wipe: {Igba ti erusin Olohun maa nsun mo Olohun re julo ni igba ti o ba fi ori kanle, ki e maa se adua pupo nibe} [Muslim: 482].
Eleekeji: Irun kiki je ise ijosin ti o dara julo ti o si je oluranlowo fun eniyan lati ranti Olohun re. Olohun- mimo fun Un- so wipe: (Atipe ki o maa gbe irun duro fun iranti Mi) [Suuratu Toohaa: 14].
Ohun ti o je erongba ti o ga julo fun ijosin naa ni iranti Olohun, nitoripe ninu ise ijosin afokanse ni, ohun si ni o maa nse okunfa idunnu fun okan; gbogbo okan ti o ba si ti jinna si iranti Olohun o ti jinna tefetefe si gbogbo oore aye ati orun, o si ti baje patapata, fun idi eyi ni Olohun fi se awon oniran-ran ijosin ni oranyan ki awon erusin Re le maa fi se iranti Re, ninu awon ijosin naa si ni irun kiki. Oro Olohun tun so ni aaye miran wipe: (Ti o si nranti oruko Oluwa [Oba] re, ti o si nkirun) [Suuratu A'alaa: 15].
Eleeketa: Irun kiki maa nse iranlowo fun erusin Olohun lati ri iyonu Olohun, aanu ati ike Re. Itoka lori eleyi ni oro Olohun ti o so wipe: (E wa iranlowo pelu suuru ati irun kiki, dajudaju o [irun] je nkan ti o wuwo, ayafi fun awon ti won paya Olohun) [Suuratu Bakorah: 45].
Olohun- mimo fun Un- tun so ni aaye miran wipe: (Mo pe eyin ti e gba Olohun gbo ni ododo e maa toro iranlowo pelu suuru ati irun kiki, dajudaju Olohun nbe pelu awon onisuuru) [Suuratu Bakorah: 153].
Eleyi fi nye wa pe irun kiki maa npese agbara ti inu emi fun erusin Olohun ti yoo fi le maa se igbiyanju lati wa iyonu Olohun pelu titele ase Re, bakannaa ni yoo si maa ran an lowo lati le maa se awon ise ile aye ni aseyori ti yoo si maa bori awon isoro ti o ba koju re pelu agbara ti irun naa npese fu un.
Eleekerin: Irun kiki ni anfaani ti o ga fun enikookan ti o ba nki i, ninu ki erusin Olohun maa ki irun bi o ti to ati bi o ti se ye ni oriire aye ati orun wa, inu re naa si ni irorun ati ifokanbale wa, eyi ti yoo je ki erusin Olohun mo amodaju wipe oore kan ko le sele si oun ayafi pelu iyonda Olohun, aburu kan ko si le sele si oun ayafi ohun ti o ba ti wa ni akosile ni odo Olohun, amodaju yi ni yoo si je ki erusin Olohun maa hu awon iwa daradara ti Olohun nferan ti O si nyonu si, ti yoo si maa mu un jinna si awon iwa buburu ti Olohun korira ti O si nbinu si.
Olohun- Oba mimo Oba ti O ga- so nigbati O nse adayanri awon olukirun wipe: (Dajudaju A da eniyan ni [alaini suuru] olukanju # Nigbati aburu ba sele si i yoo maa kanra # Nigbati oore ba si sele si i yoo maa se ahun # Ayafi awon ti won maa nki irun # Awon eniti won maa ntera mo irun ti won nki) [Suuratu Ma'ariji: 19- 23].
Eleekarun: Bi o ti je wipe irun kiki je ise ijosin ti o ko opolopo awon ise ijosin miran sinu, gege bii awon ise ijosin afokanse: ipaya ati iraworase fun Olohun, beenaani o je okunfa imototo, imora ati oso; nitoripe Olohun- mimo fun Un- ti se imora ni majemu fun gbogbo erusin Re ti o ba fe ki irun, ara olukirun gbodo wa ni mimo, aso re ti o fe fi ki irun gbodo wa ni mimo, bakannaa ni aaye ti yoo ti ki irun gbodo wa ni mimo, {Dajudaju Olohun Oba mimo ni, ko si ni tewo gba nkankan ayafi ohun ti o ba mo} [Muslim: 1015].
Olohun se ni oranyan ki Musulumi se imora siwaju ki o to ki irun, majemu si ni imora [Iwe oranyan tabi aluwala] je fun erusin Olohun ti o ba fe ki irun. Olohun- mimo fun Un- so wipe: (Eyin onigbagbo ododo nigbati e ba dide lati ki irun ki e san awon oju yin ati awon owo yin titi de igbunwo, ki e si [fi omi] pa awon ori yin ati [ki e fo] awon ese yin titi de kokose mejeeji. Ti eyin ba je eniti o ni egbin lara ki e we iwe imora. Ti eyin ba je alaisan tabi e wa lori irin-ajo tabi enikan ninu yin de lati ibi [ti o ti lo ya] igbe tabi e sunmo awon obinrin ti e ko si ri omi, nigbanaa e se aluwala pelu yeepe ti o mo, e fi pa awon oju yin ati awon owo yin ninu re. Olohun ko fe lati se isoro kan fun yin ninu esin. Sugbon Olohun nfe lati fo yin mo ati ki o le se asepe idera Re fun yin, ki e le maa dupe) [Suuratu Maaidah: 6].
Eleekefa: Irun kiki maa nse okunfa aforiji ese fun Musulumi. ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- so wipe: {Se ki ntoka yin si ohun ti Olohun maa fi npa ese re ti O si fi nse agbega fun erusin Re}, awon omoleyin re [Saabe] so wipe: toka re fun wa ire ojise Olohun. Ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- wa so wipe: {Sise aluwala de awon aaye ti okan ko nibi awon orikerike ara [nitori otutu tabi ohun miran ti o nfa inira], ati ririn lo si masalaasi fun irun, ati rireti irun miran leyin irun kan, eleyi gan an ni ojulowo ifi ara eni sile fun oju ona Olohun} [Muslim: 251].
Eleekeje: Imole ni irun kiki je, okunfa lila kuro nibi iya Olohun si ni. Abdullahi omo 'Amru omo 'Aas so wipe: Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- nsoro nipa irun kiki ni ojo kan, o wa so wipe: {Eniti o ba so irun [ti o nki deede] yoo je imole fun un, yoo si je awijare fun lori pe onigbagbo ododo ni, bakannaa yoo si je okunfa lila kuro nibi iya Olohun ni ojo ajinde. Sugbon eniti ko ba so o ko ni je imole fun un, ko si ni je awijare fun un, bee ni ko ni je okunfa lila kuro nibi iya Olohun. Ni ojo ajinde won yoo gbe eni naa dide pelu awon Kaaruuna ati Fir'aona ati Aamaana ati Ubay omo Khalaf [awon ti won je keeferi ponbele]} [Ahmad: 6576, ad-Daarimi: 2763, Mishkaatil Masoobih: 15].
Eleekejo: Irun kiki je ona kan ti o rorun julo ti o si ya julo fun erusin Olohun lati ke pe Olohun Eleda re, ona iwa asunmo si odo Olohun ni irun je, {ojise Olohun- ike Olohun ati ola Re ki o maa ba a- je eniti o maa nyara lo sibi irun nigbakiigba ti o ba ri nkan kan ti o ba a ninu je, tabi nkan ti o lagbara ti okan re ko} [Abu Daud: 1319, Ahmad: 23299, Sohiihul Jaami' Sogiir Wasiyaadatuhu: 4703].
Okunfa isinmi ati ifokanbale ni irun je, ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- maa nso wipe: {Gbe irun duro ire Bilaal, ki a ri isinmi ati ibale okan pelu re} [Abu Daud: 4985, Sohihul Jaami' Sogiir Wasiyaadatuhu: 2986].
Ti a ba woye si hadiisi yi, ti a si ronu jinle si i a o ri wipe isesi ojise Olohun- ike Olohun ati ola Re ki o maa ba a- yato si isesi awa Musulumi ni asiko yi patapata; opolopo ninu awa Musulumi ni asiko ti a wa yi ni o je wipe igba die ti o ye ki o fi ki irun re ki o si fi okan si irun naa, ki o ki irun naa pelu iberu Olohun ati ipaya Re, ko ni se bee, bikosepe royiroyi ile aye ni yoo gba okan re ni ori irun, yoo ki irun naa bii pe won fi ogunna si abe ese re.
Sugbon ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- maa nri awon ise aye yoku gege bii ohun ti o nfa inira, ti o si maa nri irun kiki ni nkan irorun ati okunfa isinmi pelu ifokanbale, idi niyi ti ojise Olohun fi maa nso wipe: {Olohun fi ohun ti o nse oju loyin fun mi sibi irun} [Tobaraani: 1012, Silsilatul Ahaadisi Sohiiha: 3291]. Eleyi ni ohun ti o ye ki o je awokose fun gbogbo Musulumi; nitoripe anabi wa Muhammad ni Olohun pe ni awokose fun gbogbo wa.
Eleekesan: Erongba erusin Olohun maa npapo mo erongba Olohun ninu irun, yoo si maa ri ohun ti o ba beere fun ni odo Olohun Eleda re. Olohun- mimo fun Un- so ninu hadiisi qudsi kan wipe: {Mo pin irun si meji laarin Emi ati eru Mi, yoo si maa je ti eru Mi ohun ti o ba beere fun ….. Nigbati erusin Mi ba so wipe: (Ire [Olohun] nikan ni awa yoo maa sin, odo Re nikan ni a o si maa toro iranlowo), Olohun yoo so wipe: Eleyi wa laarin Emi ati eru Mi, ki o si maa je ti eru Mi ohun ti o ba beere fun. Nigbati o ba so wipe: (To wa si ona taara. Ona awon eniti o se idera Re fun. Ti kii se [ona] awon ti O binu si, ti kii si se [ona] awon ti won sina), Olohun yoo so wipe: Eleyi ki o maa je ti eru Mi, yoo si maa be fun eru Mi ohun ti o ba beere fun} [Muslim: 395].
Ipo ti o ga ni irun kiki wa ninu Islam, anfaani ti o po si wa ninu re fun eniti o ba nki i. Irun je ise ijosin kan ti o nfun ni ni eko, o maa ngbin awon iwa rere ati isesi ti o dara si inu okan, o si maa ngbe okan jinna si awon iwa buburu, o maa nse atoka fun onigbagbo ododo lo sibi ise rere ati jijinna si ise buburu, o maa nje ohun iranlowo fun olukirun lati gbe awon oro isokuso ati awon nkan ti okan ko sile, o maa nje ki erusin Olohun le ni amumora nigbati adanwo ba sele. Ni afikun, irun kiki maa ngbin si okan Musulumi ododo siso enu aala Olohun ati tite ife inu mole, o si maa nran Musulumi lowo lati maa so asiko ati adehun.
Ni ipari, a nbe Olohun ninu aanu Re ki O se enikookan wa ni eniti yoo le maa ki irun re ni bi o ti to ati bi o ti ye, ti yoo maa ki i ni asiko ati ni ojupona bi ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- ti ki i ti o si pase pe ki a maa ki i.