Description
Ibeere ti o waye ni aaye yi lo bayi pe: iko kan nso wipe: Ko leto ki a maa wa iranlowo ni odo awon anabi Olohun ati awon ore Olohun, iko miran nso wipe: o leto nitoripe ore Olohun ati aayo Re ni awon eniyan yi, ewo ninu iko mejeeji ni o wa lori ododo?
Idajo Wiwa Iranlowo Ni Odo Awon Anabi Olohun Ati Awon Ore Olohun
[ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]
Igbimo iwadi ijinle lori imo esin ati idahun fun ohun ti o ruju ninu esin ni ilu Saudi Arabia
Eni ti o tumo re ni: Rafiu Adisa Bello
2013 - 1434
حكم الاستعانة بالأنبياء والأولياء
« بلغة اليوربا »
الرئاسة العامة للبحوث العلمية والإفتاء
في المملكة العربية السعودية
ترجمة: رفيع أديسا بلو
2013 - 1434
IDAJO WIWA IRANLOWO NI ODO AWON
ANABI OLOHUN ATI AWON ORE OLOHUN
Ibeere:
Awon iko meji kan wa: Iko alakoko nso wipe: Ebo sise ni ki eniyan maa wa iranlowo pelu awon anabi Olohun ati awon ore Olohun, won sin mu eri wa lati inu al-Kurani ati Sunna ojise Olohun. Iko eleekeji nso wipe: O leto ki eniyan maa wa iranlowo pelu awon anabi Olohun ati awon ore Olohun; nitoripe ayanfe Olohun ni won je, erusin Re ti O sa lesa si ni won. Ejowo, ewo ninu awon iko mejeeji yi ni o wa ni ori ododo?
--------------------------------------------------------------------
Idahun:
Wiwa iranlowo ni odo elomiran ti o yato si Olohun Allah fun iwosan kuro nibi aisan, tabi ki ojo le ro, tabi ki emi eniyan le gun ati gbogbo ohun ti o jo eleyi ninu awon nkan ti o je wipe elomiran ko ni abgara lori re ayafi Olohun Allah ninu ebo ti o tobi julo ni o wa, ti o si maa nyo eniti o ba se e kuro ninu esin Islam. Bakannaa ni wiwa iranlowo lodo eniti o ti ku tabi eniti ko si ni odo oluwaranlowo pelu re, yala eniti won nwa iranlowo ni odo re je malaika ni tabi alijoonu tabi eniyan, ti eni naa nwa iranlowo lati ri oore kan tabi lati le aburu kan jinna si ara re, ebo nla ni gbogbo eleyi ti o je wipe Olohun ko le se aforijin fun eniti o ba se e, ayafi ti o ba wa aforijin ti o si ronu piwada lo si odo Olohun.
Ohun ti o je ki oro ri bayi ni wipe irufe awon wiwa iranlowo yi ninu ijosin ni o wa, ninu awon nkan ti erusin si fi maa nwa asunmo si odo Olohun ni o wa; ko si leto rara lati se e fun elomiran yato si Olohun Allah. Ninu awon eri lori ohun ti a so yi ni gbolohun ti Olohun ko awon erusin re pe ki won maa wi ninu suuratu Faatihah: (Ire [Olohun] nikan ni awa yoo maa sin, odo Re nikan ni awa yoo si maa wa iranlowo) [Suuratu Faatihah: 5].
Ati oro Olohun ti o so wipe: (Atipe Oluwa re pase pe: E ko gbodo josin fun kinikan ayafi Oun) [Suurati Israai: 23].
Beenaani gbolohun Olohun ti o so wipe: (A ko pa won lase ju pe ki won josin fun Olohun lo, ni eniti o nse afomo esin fun Un) [Suuratu Bayyinah: 5].
Bakannaa ni oro Olohun ti o so wipe: (Atipe dajudaju ti Olohun ni awon mosalaasi je; nitorinaa ki eyin mase pe nkankan pelu Olohun [nibe]) [Suuratu Jinni: 18].
Ninu awon eri ninu sunna ni hadiisi kan ti o fi ese rinle lati odo omo Abbaas- ki Olohun yonu si i- pe ojise Olohun- ki ike ati ola Olohun maa ba a- so fun un wipe: {Ti iwo ba fe beere nkankan ki o beere ni odo Olohun, ti iwo ba si fe wa iranlowo ki o wa iranlowo ni odo Olohun} [Tirmisi: 2516, Ahmad: 2763, Sohihul Jaami' Sogiir Wasiyaadatuhu: 3051].
Ojise Olohun- ike ati ola Olohun ki o maa ba a- tun so fun saabe alapole Ma'as omo Jabal- ki Olohun yonu si i- wipe: {Iwo Olohun lori awon erusin Re ni ki won maa josin fun Un ki won si mase se ebo pelu Re} [Bukhari: 2856, Muslim: 30].
Ninu hadiisi miran, ojise Olohun tun so wipe: {Eniti o ba ku ti o si npe elomiran yato si Olohun yoo wo inu ina} [Bukhari: 4497].
Sugbon awon nkan ti o yato si ohun ti a ti so siwaju yi gege bii wiwa iranlowo lodo eniti o yato si Olohun ninu awon nkan ti Olohun funra Re se ni okunfa (sababi), awon nkan ti Olohun se awon eda Re ni okunfa (sababi) fun, ti O si fun won ni agbara lori won: Gege bii wiwa iranlowo pelu onisegun oyinbo (dokita) fun iwosan kuro nibi aisan, tabi wiwa iranlowo pelu eniti o ni ounje ki o fun elomiran ti ko ni ounje, tabi eniti o ni omi ki o fun elomiran ti ko ni omi, tabi ki eniti o roro (olowo) fun alaini (talaka) ni owo, ati gbogbo ohun ti o jo bayi kosi ninu sise ebo pelu Olohun eyi ti a so siwaju, ninu riran ara eni lowo laarin awon eda ati ifowosowopo laarin awon eniyan ni eleyi wa.
Ni afikun, ki eniyan wa iranlowo lodo eniti kosi pelu re ni ona kan ti ko ni iruju ninu, gege bii ki eniyan ko iwe (leta) si eni naa tabi ki o baa soro pelu ero ibanisoro, gbogbo eleyi kosi ninu sise ebo si Olohun tabi dida nkan po mo On.
Siwaju si, isemin awon anabi Olohun ati awon ti won ku si oju ona Olohun ati awon miran ninu awon ore Olohun kii se bii isemin won ni ile aye, isemin kan laarin aye ati ojo ajinde ni, Olohun nikan ni O si mo paapaa bi o ti se ri. Fun idi eyi, o ti fi oju han wipe iko alakoko ni o wa ni ori ododo, eyi ti o so wipe: Ebo ti o tobi ni ki eniyan maa wa iranlowo ni odo awon anabi Olohun ati awon ore Olohun lori awon nkan ti enikankan ko ni agbara lori won ayafi Olohun Allah. Ki Olohun fi enikookan wa se konge itosona Re.