×
New!

Bayan Al Islam Encyclopedia Mobile Application

Get it now!

Itumọ Wiwa Alubarika ati Awọn Ipin rẹ (Èdè Yorùbá)

Pípèsè: Rafiu Adisa Bello

Description

Akosile yi so oro lori ohun ti a npe ni wiwa alubarika bi awon onimimo se se alaye re, leyinnaa o so nipa awon ipin wiwa alubarika eyi ti o pin si meji: eyi ti o leto ati eyi ti ko leto ti oro si tun waye lori awon nkan ti Olohun fi alubarika si ara won ti o si se e leto lati fi won wa alubarika.

Download Book

    Itumọ Wiwa Alubarika

    Ati Awọn Ipin rẹ

    [ Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Lati ọwọ:

    Rafiu Adisa Bello

    Atunyewo:

    Hamid Yusuf

    2014 - 1436

    التبرك معناه وأقسامه

    « بلغة اليوربا »

    كتبها:

    رفيع أديسا بلو

    مراجعة:

    حامد يوسف

    2014 - 1436

    Itumọ Wiwa Alubarika

    Ati Awọn Ipin rẹ

    Ohun ti a npe ni alubarika ni oore ti o pọ, ti o si pe lọwọ ẹniti Ọlọhun Allah ba fun. Itumọ ki eniyan maa fi nkankan wa alubarika ni ki o maa lo nkan ti Ọlọhun pe ni okunfa alubarika lati maa fi wa a.

    Ninu ohun ti o jẹ dandan ki Musulumi ni igbagbọ ti o jindo si ni wipe ọdọ Ọlọhun Allah nikan ni gbogbo oore wa, Oun nikan si ni Ẹniti O le fun ni ni oore.

    Ọlọhun [Ọba mimọ Ọba ti O ga julọ] sọ ninu Alukurani bayi pe: (Wipe: Ọlọhun Olukapa ijọba, Irẹ ni o maa nfi ijọba fun ẹniti O ba fẹ, Irẹ ni O si maa ngba ijọba kuro lọwọ ẹniti O ba fẹ, Irẹ ni nfun ẹniti O ba fẹ ni iyi, Irẹ ni O si nyẹpẹrẹ ẹniti O ba fẹ. Lọwọ Rẹ ni gbogbo oore wa, Irẹ ni Alagbara lori gbogbo nkan.) [Suuratu Al-Imraan: 26].

    Ọlọhun Allah nikan ni o ni alubarika, Oun ni O si maa nfi alubarika si ara ohun ti o ba fẹ, idi niyi ti O fi royin ara Rẹ pẹlu iroyin alubarika, eyi ti ẹlomiran ko si ni ẹtọ si iroyin naa lẹyin Rẹ.

    Ojisẹ Ọlọhun [ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] sọ wipe: “Odọ Ọlọhun nikan ni alubarika ti nwa" [1].

    Awọn ọna ti wiwa alubarika pin si

    Wiwa alubarika pin si ọna meji:

    Ipin Kinni: Wiwa alubarika eyi ti o lẹtọ, ohun naa ni eyi ti o ba ilana Shẹria Islam mu.

    Majẹmu meji ni o gbọdọ wa nibi ipin yii, awọn majẹmu mejeeji naa ni:

    Alakọkọ: Ki ohun ti eniyan fẹ fi wa alubarika ni ọdọ Ọlọhun jẹ nkan ti Ọlọhun ti fi alubarika si ara rẹ, ti O si ti se ni ẹtọ lati wa alubarika pẹlu rẹ.

    Elẹẹkeji: Ki ọna ti eniyan fẹ gba lati fi nkan naa wa alubarika ni ọdọ Ọlọhun jẹ ọna ti o ba ilana ẹsin Islam mu.

    Eleyi tumọ si wipe ko lẹtọ lati wa alubarika pẹlu awọn nkan ti ko si ẹri lati inu Alukurani tabi hadiisi Ojisẹ Ọlọhun [ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] wipe Ọlọhun fi alubarika sibẹ, gẹgẹ bii wiwa alubarika pẹlu oogun ibilẹ ti ko ba ilana Shẹria Islam mu tabi idan pipa. Bakannaa ni ko lẹtọ lati wa alubarika ni ọdọ Ọlọhun ni ọna ti ko ba ilana ẹsin Islam mu koda ki nkan naa wa ninu awọn ohun ti Ọlọhun fi alubarika si ara wọn, gẹgẹ bii wiwa alubarika pẹlu oripa awọn ẹni-rere tabi saare wọn, ati wiwa alubarika pẹlu awọn aaye kan ti ko si ẹri ti o tọka si wiwa alubarika pẹlu wọn.

    Ipin Keji: Wiwa alubarika eyi ti ko lẹtọ, eleyi le jẹ sise ẹbọ nla si Ọlọhun Allah, ti o ba jẹ wipe ẹniti o nwa alubarika pẹlu nkankan ni adisọkan wipe nkan naa ni o nfun ni ni alubarika kii se Ọlọhun Allah. Irufẹ adisọkan bayi le sọ Musulumi di ẹniti yoo se ẹbọ nla si Ọlọhun; nitoripe ọdọ Ọlọhun nikan ni alubarika wa.

    Ni ọna miran, wiwa alubarika eyi ti ko lẹtọ yi si le jẹ adadasilẹ ninu ẹsin nigbati ohun ti eniyan kan ba fi nwa alubarika ni ọdọ Ọlọhun kii se ohun ti ẹri kan tọka si wipe o lẹtọ lati maa fi wa alubarika, ti ẹni naa si ni adisọkan wipe Ọlọhun fi alubarika si ara nkan naa.

    Eewọ ni fun Musulumi lati se eleyi; nitoripe sise bẹẹ ti se okunfa adadasilẹ ninu ẹsin ti ko si ẹri kankan ti o tọka si i, yala lati inu Alukurani ni tabi hadiisi Ojisẹ Ọlọhun, bakannaa ni o ti se nkan ti kii se okunfa, o ti se e ni okunfa, ẹbọ kekere si ni eleyi, ti o si tun le mu eniyan se ẹbọ nla.

    Awọn nkan ti Ọlọhun fi Alubarika si Ara Wọn

    Awọn nkan ti ẹri tọka si lati inu Alukurani ati hadiisi wipe Ọlọhun fi alubarika si ara wọn pin si ọna marun, awọn naa niyii [2]:

    Alakọkọ: Apakan ninu awọn eniyan ti Ọlọhun fi alubarika si ara wọn, gẹgẹ bii Ojisẹ Ọlọhun, Anabi wa Muhammad [ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o ma a ba a] ati awọn eniyan miran ninu awọn onimimọ, ọrẹ Ọlọhun ati ẹni -rere.

    Elẹẹkeji: Awọn ọrọ sisọ ati isẹ sise ti Ọlọhun fi alubarika si ara wọn, gẹgẹ bii ọrọ Ọlọhun Al-kurani Alapọnle ati iranti Ọlọhun bii gbolohun (Subhana Llahi, wal-hamdu Lillahi), ati dida orukọ Ọlọhun ni ibẹrẹ gbogbo nkan, ati sise asalaatu fun Ojisẹ Ọlọhun Muhammad [ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o ma a ba a] ni ọna ti o ba ilana Islam mu.

    Elẹẹkẹta: Awọn aaye ti Ọlọhun fun ni alubarika, gẹgẹ bii ilu Makkah, paapaa julọ Mọsalasi Haramu ti o wa nibẹ, bakannaa ni ilu Madina ati Mọsalasi Kudusi.

    Ninu awọn aaye ti Ọlọhun tun fun ni alubarika ni gbogbo mọsalasi ni ori ilẹ.

    O si tun wa ninu awọn aaye ti o ni alubarika bakannaa ilu Shaamu (Jordan, Syria, Lebanon and Philestine).

    Elẹẹkẹrin: Awọn asiko ti Ọlọhun fi alubarika si inu wọn, gẹgẹ bii osu Ramadan ati awọn Ọjọ mẹwa ibẹrẹ osu Dhul-hijjah, bakannaa ni Ọjọ Jimọh, Ọjọ Ithnain (Monday) ati Ọjọ Khamis (Thursday).

    Elẹẹkarun: Awọn nkan jijẹ ati mimu ti Ọlọhun fi alubarika si ara wọn, gẹgẹ bii igi Saetuun ati eso rẹ ati igi ọpẹ. Ninu awọn nkan mimu ti Ọlọhun tun fi alubarika si ni omi sẹmisẹmi (Zamzam), wara ati oyin.

    Ohun ti o jẹ dandan fun Musulumi lati se akiyesi rẹ daradara ni wipe gbogbo awọn nkan ti Ọlọhun fi alubarika si ara wọn yii, ẹsin Islam ti mu ilana ti Musulumi yoo tọ ti o ba fẹ wa alubarika ni ọdọ Ọlọhun pẹlu lilo awọn nkan wọnyi, o si jẹ dandan ki o tẹle awọn ilana naa ki o ma baa sina. Ki Ọlọhun se alekun itọsọna fun ẹnikọọkan wa.

    [1] Bukhari: (3579).

    [2] Alaye lori ọna ti Musulumi yoo maa gba lati wa alubarika ni ọdọ Ọlọhun pẹlu awọn nkan wọnyi yoo waye ninu akọsilẹ miran laipẹ.

    معلومات المادة باللغة العربية