×
New!

Bayan Al Islam Encyclopedia Mobile Application

Get it now!

Diẹ ninu awọn Iranti Ọlọhun ti o wa lati ọdọ Ojisẹ Ọlọhun [Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a] (Èdè Yorùbá)

Pípèsè: Sa’id Bn Ali Bn Wahf Al-Qahtaani

Description

Diẹ ninu awọn iranti Ọlọhun ti o yẹ ki Musulumi o mọ ki o si maa se ni ojoojumọ lati inu iwe Husnul Muslim.

Download Book

    Diẹ ninu awọn Iranti Ọlọhun Ojoojumọ lati ọdọ Anabi Muhammad

    (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a ).

    [Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Lati ọwọ:

    Dr.Mubarak Zakariya Al imam

    Atunyẹwo:

    Hamid Yusuf

    2015 - 1436

    بعض الأذكار اليومية الواردة عن النبي صلى الله عليه وسلم

    « بلغة اليوربا »

    كتبها:

    د. مبارك زكريا الإمام

    مراجعة:

    حامد يوسف

    2015 - 1436

    Iranti Ọlọhun jẹ ọkan pataki ninu awọn asẹ ti Ọlọhun pa fun awa onigbagbọ ododo, ti O si fẹ ki a maa se ni ọpọlọpọ asiko, Ọlọhun sọpe: (ẹyin onigbagbọ ododo, ẹ maa ranti Ọlọhun ni ọpọlọpọ.) [suurat ahzaab: 41].

    Eyi tumọ si wipe, Ọlọhun fẹ ki a maa fi gbogbo igba ati asiko se iranti Oun.

    Ki asẹ Ọlọhun yii o le baa ye wa daradara, Anabi Muhammad (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a) se agbekalẹ awọn ọna ti o dara fun wa lati mu asẹ Ọlọhun yii sẹ. Ninu rẹ ni wipe, ki a maa wi awọn gbolohun kan ni ojoojumọ, ni awọn aaye ati asiko kọọkan, gẹgẹ bii ti a ba ji ni aarọ, ti a ba fẹ sun ni alẹ, ti a ba fẹ jẹ ounjẹ, ti a ba jẹun tan, ati bẹẹbẹẹ lọ, ninu awọn nkan ti a maa n se ni ojumọ.

    Diẹ ninu awọn gbolohun iranti naa niyi:

    1- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba ji ni aarọ:

    {ALHAMDULILLAH, ALLADHI RODDA ILAYYA RUUHI, WA ADHINA LI BIDHIKRIHI}.

    2- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ wọ ile iwẹ tabi ile igbansẹ:

    {ALLAHUMA, INNI AUDHU BIKA, MINAL KHUBUTHI WAL KHABAAITH}.

    3- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba jade kuro ninu ile iwẹ tabi ile igbansẹ: {GUFRAANAK}.

    4- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ wọ asọ: {ALLAHUMA, INNI AS-ALUKA KHAERAHU, WA KHAERA MA SUNIA LAHU, WA AUDHU BIKA MIN SHARIHI, WA SHARI MA SUNIA LAHU}.

    5- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ bọ asọ silẹ: {BISMILLAH}.

    6- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ jẹun:{BISMILLAH}.

    7- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ wọ asọ: {ALHAMDULILLAH}.

    8- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ jade kuro ninu ile: {BISMILLAH, TAWAKKALTU ALALLAH, WA LAA HAOLA, WALA QUWWATA ILLA BILLAH}.

    9- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ wọ ile: {BISILLAHI WALAJNA, WA BISMILLAHI KHARAJNA, WA ALALLAHI RABBINA TAWAKKALNA, SALAAMU ALAIKUM}.

    10- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ se aluwala: {BISMILLAH}.

    11- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba se aluwala tan:{ASH-HADU, ALLAA ILAAHA ILLALLAH, WAHDAHU, LAA SHARIKA LAHU, WA ASH-HADU ANNA MUHAMMADAN RASULULLAH}.

    12- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ wọ mọsalasi: {BISMILLAH, WA SSALATU, WA SSALAMU ALA ROSULILLAH, ALLAHUMMAF TAHLI ABUWAABA RAHMATIK}.

    13- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ jade kuro ninu mọsalasi: {ALLAHUMA, INNI AS-ALUKA, MIN FADLIKA}.

    14- Adua ti o yẹ ki a se ti a ba fẹ sun:

    A o tẹ ọwọ wa mejeeji, a o wa se adua yi:

    - AYATUL KURSIY, allahu laa ilaaha illa huwa, al hayul kayyum… titi de ipari ni ẹẹmẹta. (3).

    - KUL HUWAL LAHU, MẸTA (3).

    - KUL AUUDHU BIROBIL FALAKi, MẸTA (3).

    - KUL AUUDHU BIROBIN NAAS, MẸTA (3).

    A O TU ITỌ DIẸ SI ỌWỌ LẸYIN TI A KA AWỌN ADUA YI, A O FI RA AYIKA ARA WA.

    Eleyi ni diẹ ninu awọn adua ti Anabi Muhammad (Ikẹ ati ọla Ọlọhun ki o maa ba a) fi kọ wa lati maa se ni ojoojumọ, eyi ti yoo maa jẹ imusẹ fun asẹ ti Ọlọhun pa fun wa, ti yoo si tun maa jẹ isọ ati aabo fun wa, ninu aburu awọn eniyan ati gbogbo awọn ẹda buruku eyi ti a mọ, ati eyi ti a ko mọ, ti a ko ni agbara lori wọn, sugbọn ti Ọlọhun mọ wọn, ti O si ni agbara lori wọn.

    Wal hamdulillah Rabbil A'lamin.

    معلومات المادة باللغة العربية