×
New!

Bayan Al Islam Encyclopedia Mobile Application

Get it now!

Pataki Adua ninu Islam (Èdè Yorùbá)

Description

Akọsilẹ ti o sọ nipa anfaani ti o n bẹ nibi adua fun Musulumi ododo ati bi o se jẹ ohun ti Ọlọhun fẹran lati ọdọ ẹru Rẹ.

Download Book

    Pataki Adua ninu Islam

    [Yorùbá -Yoruba - يوربا ]

    Lati ọwọ:

    Dr.Mubarak Zakariya Al imam

    Atunyẹwo:

    Rafiu Adisa Bello

    Hamid Yusuf

    2015 - 1436

    أهمية الدعاء في الإسلام

    « بلغة اليوربا »

    كتبها:

    د. مبارك زكريا الإمام

    مراجعة:

    رفيع أديسا بلو

    حامد يوسف

    2015 - 1436

    Adua ni ki eniyan o beere nkan lọwọ Ọlọhun, pẹlu itẹriba ati iwariri, ati gbigba wipe a n fẹ iranlọwọ ati agbara Rẹ lori awọn bukaata wa. O si tun jẹ ọkan ninu awọn ọna ti Islam la silẹ fun wa lati fi jọsin fun Ọlọhun Ọba, ati lati se afihan wipe ẹru ni a jẹ si I ni otitọ ati ni ododo. Eleyi n tumọ si wipe bi adua se jẹ itọrọ ati ibeere nkan lọwọ Ọlọhun, gẹgẹ bẹẹ naa ni o tun jẹ ijọsin fun Ọlọhun.

    Ninu atẹjade yii, a o tọka si diẹ ninu pataki adua, ki a le mọ bi o se jẹ pataki to ninu ẹsin Islam.

    1- Adua jẹ ọkan ninu awọn ijọsin ti Ọlọhun n fẹ lati ọdọ awa ẹru Rẹ. Ọlọhun sọpe:

    (وقال ربكم ادعوني أستجب لكم)

    Itumo: (Atipe Oluwa yin sọ wipe: Ẹ pe Mi, Emi yoo dayin lohun) [Suuratu gaafir: 60].

    2- Sise adua jẹ amin itẹriba fun Ọlọhun, atipe a gba wipe alaini ni wa, Ọlọhun nikan ni o to tan. Eyi jẹ ki a mọ wipe ẹniti ko ba se adua, onitọhun ti se igberaga si Ọlọhun, ẹniti o ba si se igberaga si Ọlọhun, onitọhun ti di ọmọ ina, gẹgẹ bi Ọlọhun se sọ pe:

    (إن الذين يستكبرون عن عبادتي سيدخلون جهنم داخر)

    Itumọ: (Dajudaju awọn ti wọn n se igberaga ti wọn gbunri kuro nibi ijọsin Mi, wọn yoo wọ ina Jahanama ni ẹni yẹpẹrẹ) [Suratu gaafir: 60]. Eleyi n jẹ ki a mọ wipe adua sise kii se ti o ba wuwa, bikosepe ọranyan ni, gẹgẹ bi irun, aawẹ, hajj, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Idi niyi ti anabi Muhammad (ki ikẹ ati alaafia Ọlọhun o maa ba a) se sọ wipe: (Ọlọhun n binu si gbogbgo ẹniti kii beere nkan lọdọ Rẹ), ti kii se Adua.

    3- Adua sise jẹ ohun ti o se pataki, ti o si ni apọnle ju ni ọdọ Ọlọhun, gẹgẹ bi anabi Muhammad (ki ikẹ ati alaafia Ọlọhun o maa ba a) se sọ wipe: (ko si ohun ti o ni apọnle ni ọdọ Ọlọhun ti o ju adua lọ).

    4- Adua sise jẹ ohun ti Ọlọhun nifẹ si pupọ, gẹgẹ bi ibn masu'd (ki Ọlọhun yọnu si i) se sọ wipe: (Ẹ maa beere ọla Ọlọhun, ni ọdọ Ọlọhun, nitoripe Ọlọhun n fẹ ki awọn ẹru Rẹ maa beere n kan lọdọ Oun).

    5- Adua jẹ okunfa ti o maa n gbe ibinu Ọlọhun jina si ẹda, Anabi Muhammad (ki ikẹ ati alaafia Ọlọhun o ma ba a) sọ wipe: (Ọlọhun n binu si gbogbo ẹniti kii beere nkan lọdọ Ọlọhun), ti kii se Adua, ni idakeji, Ọlọhun ko nii binu si ẹniti o ba n se adua, ti o si nbere nkan lọdọ Rẹ.

    6- Adua jẹ ọkan ninu awọn amin ti a o fi mọ dajudaju wipe gbigbe ara ati ọkan le Ọlọhun n bẹ fun ẹniti o ba n se adua, ti ko ba ri bẹẹ ko nii beere nkan lọdọ Ọlọhun, nitotipe awọn eniyan kan gba wipe agbara n bẹ fun awọn lati se ohun ti awọn n fẹ, awọn eleyi gbe ara ati ọkan le agbara ati ipo ti wọn ni, awọn eniyan miran gba wipe pẹlu ọgbọn ati imọ ati oye ti awọn ni, ọwọ awọn yoo tẹ gbogbo nkan ti awọn n fẹ, awọn eleyi gbe ara ati ẹmi wọn le ọgbọn ati oye wọn. Awọn ẹlominran gba wipe oogun sise ati sise ẹgbẹ awo ati ẹgbẹ okunkun ni awọn yoo fi ri ohun ti awọn nfẹ. Gbogbo awọn yii, kii se Ọlọhun ni wọn gbe ara le.

    7- Adua jẹ ọkan ninu awọn amin ti a o fi mọ dajudaju wipe igbagbọ si Ọlọhun ati si awọn orukọ ati iroyin Rẹ n bẹ ni ọkan ẹni ti o n se adua, a wọn iroyin bii: jijẹ alagbara, jijẹ Olugbọ ati Olugba adua, Oni ikẹ ati aanu, Onimimọ julọ, ati bẹẹbẹẹ lọ, ninu awọn ohun ti o so pọ mọ adua sise.

    8- Adua jẹ ohun ti o daju wipe Ọlọhun yoo gbọ, ti yoo si dahun si, eleyi wa ni ibamu si ọrọ anabi Muhammad (ki ikẹ ati alaafia Ọlọhun o maa ba a) ti o sọ wipe: (ko si ẹnikẹni ti yoo beere nkan ni ọdọ Ọlọhun, ti Ọlọhun ko nii fun ni ohun ti o n fẹ, tabi bẹẹkọ, ki o di ọna aburu fun, pẹlu majẹmu: ti ko ba ti jẹ wipe ohun ti Ọlọhun se ni eewọ ni o nfẹ, ti ko si jẹ adua ti yoo tu ẹbi).

    9- Adua wulo pupọ lati fi ti ilekun aburu, siwaju ki o to sẹlẹ si ẹda, ojisẹ Ọlọhun sọpe: (ko si nkan ti o le gbe akọsilẹ aburu kuro lori eniyan ti o ju adua lọ).

    10- Adua sise wulo fun awọn aburu ati adanwo lẹyin igbati o ti sẹlẹ. Ojisẹ Ọlọhun sọpe: (Adua sise ni anfaani ti yoo se lara aburu eyi ti o sẹlẹ si eniyan, tabi eyi ti ko tii sẹlẹ rara). Anfaani nla ni eleyi jẹ fun gbogbo ẹniti o wa ninu isoro, ki a mọ wipe ọna abayọ si tun wa si isoro oun, nitoripe ti adua ko ba gba ni igba akọkọ si ibi nkan ti a nfẹ, o sile gba ni ẹẹkeji, ti yoo si ba wa da aburu duro, ti yoo si se idapada awọn oore ti o ti bọ sọnu, gẹgẹ bi Ọlọhun ti se fun anabi Ayuba, ti Ọlọhun da awọn oore rẹ pada fun ni ilọpo.

    Awọn wọnyi ni diẹ ninu ọla ati pataki adua, nitorinaa ki a gbiyanju lati dunni mọ adua, ki a si mọ wipe Ọlọhun ti a n pe nikan ni Alagbara, Alaaye, Olugbọ, Olumọ julọ, Alese ohun-gbogbo, ti o le se gbogbo nkan ti a nfẹ.

    Wal hamdulillah Rabbil A'lamin.

    معلومات المادة باللغة العربية