×
New!

Bayan Al Islam Encyclopedia Mobile Application

Get it now!

Òjíṣẹ́ awọn mùsùlùmí anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba a) (Èdè Yorùbá)

Wa lekerengo ni:

Description

No Description

Download Book

Mo bẹrẹ pẹlu orúkọ Ọlọhun Ọba Ajọkẹ-ayé Aṣakẹ-ọrun

Òjíṣẹ́ awọn mùsùlùmí anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba a)

Ọrọ ni ṣókí nípa ojiṣẹ ìsìláàmù, Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba a- màá ṣàlàyé orúkọ rẹ, ati iran rẹ ati ìlú rẹ, àti ìgbéyàwó rẹ, àti iṣẹ rírán rẹ, àti ohun tí o pepe si, ati awọn àmì ijẹ anabi rẹ, àti òfin rẹ, àti ihà tí àwọn ọ̀tá rẹ kọ si i.

1- Orúkọ rẹ, ati ìran rẹ, àti ilu ti wọn ti bí i tí o sì dàgbà si.

Ojiṣẹ awọn mùsùlùmí naa ni Muhammad ọmọ Abdullah ọmọ Abdul muttọlib ọmọ Haashim, láti inú arọmọdọmọ Isma'eel ọmọ Ibrahim (ki àlàfíà Ọlọhun máa ba wọn).Anọbi Ibrọ̄hīm- ki alaafia Ọlọhun máa ba a- lọ láti ilẹ Shaamu sí ilẹ Makkah, iyawo rẹ Haajar àti ọmọ rẹ Isma'eel sì wá pẹlu rẹ, o sì wà ni ọmọ òpóǹló, o sì fi àwọn méjèèjì sí Makkah pẹlu aṣẹ lati ọdọ Ọlọhun, nígbà tí Isma'eel wáá dàgbà, anọbi Ibrọ̄hīm wá sí ìlú Makkah, òun àti ọmọ rẹ Isma'eel- ki àlàáfí máa bá àwọn méjèèjì- sì mọ kaaba ilé ọwọ, awọn eniyan si pọ ni ẹgbẹẹgbẹ ilé Olúwa naa, Makkah sì di aaye ti awọn olùjọsìn fún Ọlọhun Ọba máa n lọ, ati awọn ti wọn n ṣojukokoro sibi pípé ọranyan Hajj, awọn eniyan ṣi n tẹ síwájú níbi ìjọsìn fún Ọlọhun ati mímú Un ní Ọkan ṣoṣo ni ìlànà ẹsin anọbi Ibrahim (ki alaafia máa bá a) fún àìmọye ọdún.Leyin naa ni iyapa sì wáyé, èyí ló mú kí ìṣesí erékùsù ilẹ̀ lárúbáwá ko dà bíi ìṣesí awọn ilu àgbáyé tó kù ni àyíká rẹ, ti àwọn ibọrisa ṣi n foju hàn níbẹ̀ gẹgẹ bíi bíbọ̀rìṣà, ati ríri ọmọbinrin mọ́lẹ̀ láàyè, àti ṣíṣe abosi fún awọn obinrin, ati ọrọ èké àti ọtí mímu, àti ṣíṣe awọn ìbàjẹ́, ati jíjẹ owó ọmọ orukan, ati gbigba owó èlé....Ni ààyè yìí ati ni agbègbè yii ni wọn ti bí òjíṣẹ́ awọn mùsùlùmí tii ṣe Muhammad ọmọ Abdullah lati inu arọmọdọmọ Isma'eel ọmọ Ibroheem, ki àlàáfíà Ọlọhun lọ máa ba wọn ni ọdún 571 ti kalẹnda Gregory, baba rẹ ku ṣíwájú bíbí rẹ, iya rẹ naa ku nigba ti o wa ni ọmọ ọdún mẹ́fà, ẹgbọn baba rẹ tii ṣe Abu Tọọlib sì gba a tọ́, ó sì sẹ̀mí ni ọmọ òrukàn ni aláìní, o máa n jẹ, o sì máa n wa ijẹ-imu latara iṣẹ ọwọ rẹ.

2- Igbeyawo alalubarika pẹ̀lú aṣiwaju lobinrin alalubarika.

Nigbati ọjọ orí rẹ wáá pe mẹẹdọgbọn, o fẹ aṣiwaju kan ninu awọn obinrin ilu Makkah, oun ni Khọdeeja ọmọ Khuwaelid, ki Ọlọhun yọnu si i, Ọlọhun sì fi ọmọbinrin mẹẹrin ati ọkunrin meji ta wọn lọrẹ, awọn ọmọkùnrin rẹ sì kú ní ọmọ oponlo, ìbálòpọ̀ rẹ pẹlu iyawo rẹ ati àwọn ẹbí rẹ jẹ pẹlu aanu ati ifẹ ti o pọ púpọ̀; nitori eyi ni iyawo rẹ tii ṣe Khọdeejah fi nífẹ̀ẹ́ rẹ ní ifẹ ti o tóbi, oun náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ pẹlu, kò sì fi igba kankan gbàgbé rẹ rí, koda lẹ́yìn iku rẹ fún àìmọye ọdún, anọbi máa n dúńbú ẹran, yóò sì pin in fún àwọn ọrẹ Khadeeja lati fi ṣe àpónlé fún wọn, ati lati fi sọ ìfẹ́ rẹ.

Bibẹrẹ wáàyí (imisi)

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- jẹ oniwa tó dára láti ìgbà tí Ọlọhun ti dá a, awọn ìjọ rẹ sì máa n pe e ni olódodo alafọkantan, o sì máa n ba wọn kopa ninu àwọn iṣẹ ńláńlá, o sì máa n korira awọn ohun ti wọn wa lori rẹ gẹgẹ bíi bíbọ̀rìṣà, kìí sii ba wọn kopa níbẹ̀...

Nígbàtí o wáá pé ọmọ ogoji ọdún, ti o sì wá ni ilu Makkah, Ọlọhun yan án lati jẹ ojiṣẹ, Malaika Jibreel si waa bá a pẹlu ìbẹ̀rẹ̀ suura akọkọ ti o sọkalẹ ninu Kuraani, oun náà ni gbólóhùn Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga:(اقْرَأْ بِاسْمِ رَبِّكَ الَّذِي خَلَقَ (1) Ké (al-Ƙur'ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. (1)خَلَقَ الْإِنسَانَ مِنْ عَلَقٍ (2) Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì. (2)اقْرَأْ وَرَبُّكَ الْأَكْرَمُ (3) Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ. (3)الَّذِي عَلَّمَ بِالْقَلَمِ (4) Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn. (4)عَلَّمَ الْإِنسَانَ مَا لَمْ يَعْلَمْ (5)) Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n. (5)"(Al-Alaq:1-5)"O waa ba iyawo rẹ tii ṣe Khadiija, ki Ọlọhun yọnu sí i, ti ọkàn rẹ sì n gbọn, o wáá sọ nnkan ti o ṣẹlẹ fún un, o sì fi i lọkan balẹ, o wáá mu un lọ sí ọdọ ọmọ ẹgbọn bàbá rẹ (Warakọtu ọmọ Naofal), Kristẹni si ni oun ti o tun ka Taoreeta ati Injiila, Khadiija wáá sọ fún un pe: Irẹ ọmọ ẹgbọn bàbá mi, gbọ́ ọrọ ọmọ ẹgbọn rẹ, ni Warakọt ba sọ fún un pe: Irẹ ọmọ ẹgbọn mi, kini ohun ti o n rí? Ni ojiṣẹ Ọlọhun- kí ìkẹ́ àti ọlà Ọlọhun máa ba a- wáá fún un níròó ohun tí o rí, Warakọt wáá sọ fún un pé:Eleyii ni ofin ti Ọlọhun sọkalẹ fún anọbi Muusa, o wu mi ki emi naa jẹ ọ̀dọ́ nígbà tí ó bá maa di ojiṣẹ, o wu mi ki n maa bẹ láàyè nígbà tí awọn ìjọ rẹ maa le ọ jade, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ báyìí pé: "Ṣe wọn maa le mi jade ni? O sọ pé: Bẹẹni, ẹnìkan ko mu iru ohun ti o mu wa yii ri ayafi ki wọn ba a ṣe ọta, ti ìgbà naa ba maa ṣe ojú mi, maa ràn ọ lọwọ ni iranlọwọ ti o lágbára.{2}.

Ni ilu Makkah, Kuraani n sọkalẹ ni sisẹ-n-tẹle fun un, malaika Jibreel n mu u sọkalẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba gbogbo ẹ̀dá, gẹgẹ bí o ṣe n wáá bá a pẹlu àlàyé ni ẹkunrẹrẹ fun ìránṣẹ́.

O n pe àwọn ìjọ rẹ sínú Islām tí àwọn ìjọ rẹ si n ba a jà, wọn fi oríṣiríṣi nǹkan lọ ọ ki o le fi iṣẹ́ ti wọn ran an silẹ, wọn fi dúkìá àti ọla lọ ọ, gbogbo ẹ ni o kọ, wọn wa sọ fún un gẹ́gẹ́ bí àwọn àgbààgbà ti sọ fún àwọn ojiṣẹ ti wọn ṣíwájú rẹ pé: Opidan ni, okurọ ni, aladapa irọ́ ni, wọn fún ilẹ mọ ọn, wọn ṣe e léṣe, wọ́n fi suta kan àwọn ti wọn tẹle e.Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- n ba ipepe lọ ni Makkah, pàápàá julọ ni àsìkò hajj, ati ninu awọn ọjà ti o ti ni àsìkò ti wọn maa n ná an, o maa n pade àwọn èèyàn nibẹ, o si maa n fi Isilaamu lọ wọn, ko fi ìfẹ́ ayé ati ìjẹ́-olórí pe wọn, ko si fi ida dẹru ba wọn, kii sii ṣe ọlọla tabi ọba, o kede ipenija ni ibẹrẹ ipepe rẹ pe ki wọn mu iru Kuraani wa, ko si yee ma pe àwọn ọ̀tá rẹ nija pẹ̀lú rẹ, àwọn ti wọn gba a gbọ si gba a gbọ ninu awọn saabe alapọn-ọnle (ki Ọlọhun yọ́nú si gbogbo wọn ni àpapọ̀).Ọlọhun pọn ọn le ni Mẹka pẹ̀lú àmì ńlá tii ṣe ìrìn-àjò òru lọ si Baytul-Mak'dis, lẹ́yìn náà ni wọ́n tun mu un gun sanmọ lọ. Ninu nnkan ti a mọ ni pe Ọlọhun gbe anọbi Il'yaas ati anọbi Isa- ki ọla maa ba àwọn méjèèjì- lọ sí sanmọ, gẹgẹ bi o ṣe wa lọdọ àwọn Mùsùlùmí ati awọn Kristẹni.Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- wa gba irun wa lati ọdọ Ọlọhun ni sanmọ, oun naa ni irun ti àwọn Musulumi n ki ni ẹẹmarun-un ni ojúmọ́, ni Mẹka- bákan náà- àmì ńlá mìíràn tun ṣẹlẹ̀, oun naa ni lílà òṣùpá ti àwọn ọṣẹbọ naa si ri i.

Gbogbo ọ̀nà ni àwọn Kèfèrí Kuraeshi sán lati ṣẹri àwọn ènìyàn kúrò nibẹ lati maa da ète si i lọ, wọn fi tipá ti ìkúùkù beere fun àwọn àmì, wọn wa iranlọwọ àwọn Yẹhuudi lati fun wọn ni ẹri ti wọn le fi tako o ti wọn si fi le ṣẹri àwọn ènìyàn kúrò nibẹ.

Nigba ti suta ti àwọn Kèfèrí Kuraeshi fi n kan àwọn Mumini ko dúró, anọbi yọnda fun wọn lati ṣe hijira lọ si ilu Habasha, anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ fun wọn pe: Ọba kan wa nibẹ ti o jẹ onideede ti wọn kii ṣe àbòsí ẹnikẹ́ni ni ọdọ rẹ̀, ọba naa si jẹ Kristẹni. Ikọ̀ meji ni wọn ṣe hijira lọ si Habasha, nígbà tí wọ́n de ibẹ, wọn fi Isilaamu lọ ọba naa, ni o ba gba Isilaamu, o wa sọ pé: Èyí- mo fi Ọlọhun bura- ati nǹkan ti anọbi Musa naa mu wa n jáde láti inú òpó àtùpà kan, àwọn ìjọ rẹ ko dawọ fifi suta kan oun ati awọn saabe rẹ dúró.

Ninu awọn ti wọn gba a gbọ ni asiko naa ni àwọn ti wọn wa láti Mẹdina, wọn si ṣe adehun fun un lati gba Isilaamu ati lati ran an lọ́wọ́ ti o ba wa si Mẹdina. Wọn n pe Mẹdina ni (Yas'rib) nígbà naa, o wa yọnda fun àwọn ti wọn ṣẹku ni Mẹka lati ṣe hijira lọ sí ilu Mẹdina. Wọn wa ṣe hijira, ti Isilaamu sì tan káàkiri ni ilu Mẹdina, titi ti ko fi si ilé kankan afi ki Isilaamu wọ ibẹ.

Lẹ́yìn ti Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ti lo ọdún mẹtala ni ilu Mẹka ni ẹni tí o n pepe si ti Ọlọhun, ni Ọlọhun wa yọnda fun un lati ṣe hijira lọ sí Medina, o ṣe hijira, o si n ba iṣẹ́ ipepe lọ, àwọn òfin ẹsin bẹ̀rẹ̀ si nii sọkalẹ nibẹ léraléra diẹ-diẹ, o wa bẹ̀rẹ̀ si nii ran àwọn ojiṣẹ pẹ̀lú lẹta si awọn olórí àwọn ìdílé, ati awọn ọba, ti o n pe wọn sinu Isilaamu, ninu awọn ti o ranṣẹ si ni: Ọba ilu Róòmù, ati ọba ìlú Farisí, ati ọba ìlú Misira.

Ọsan di òru ni ìlú Mẹdina, ni ẹru ba bẹ̀rẹ̀ si nii ba àwọn èèyàn, ọjọ́ naa wa ṣe deedee ọjọ́ ti Ibrahim ọmọ Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- kú, àwọn èèyàn ba bẹ̀rẹ̀ si nii sọ pe: Torí ikú Ibrahim ni ọsan ṣe di òru, ni Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- wa sọ pe:Dájúdájú oorun ati òṣùpá ko le wọọkun nítorí ikú ẹnikẹni tabi ìsẹ̀mí ẹnikẹ́ni, awọn méjèèjì n bẹ ninu awọn arisami Ọlọhun ni, o sì máa n fi wọn dẹruba awọn ẹrúsìn Rẹ.Ka ni pé anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- bá jẹ òpùrọ́ ti n pe ara rẹ ni nǹkan ti ko jẹ ni, ìbá yára lati fi dẹru ba àwọn èèyàn kúrò nibi pipe e ni opurọ, ìbá sọ pé: Dájúdájú òòrùn wọọkun nítorí ikú ọmọ mi, bawo waa ni ọrọ ẹnití o bá pe mi ni opurọ yóò ṣe rí...

Ojiṣẹ Ọlọrun- kí ikẹ àti ọlà Ọlọhun máa bá a- jẹ ẹni tí Ọlọhun Ọba rẹ ṣe ní ọ̀ṣọ́ pẹlu awọn ìwà ti o pe, O sì tún royin rẹ ninu ọrọ Rẹ pẹlu gbólóhùn:(وَإِنَّكَ لَعَلَىٰ خُلُقٍ عَظِيمٍ) Dájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà àpọ́nlé.Suuratul-Qalam:4Gbogbo iwa daadaa ni o ni gẹgẹ bii òdodo, imọkanga, ìgboyà, déédéé, pípé adehun títí ti o fi dórí àwọn ọ̀tá rẹ, ati ọrẹ-títa, o si nífẹ̀ẹ́ ṣíṣe saara fun àwọn talika ati awọn aláìní, ati awọn opó, àti àwọn ti wọn ni bukaata ati ojúkòkòrò lati fi wọn mọ ona, ati níní àánú wọn, ati rirẹ ara rẹ silẹ fun wọn, debi pe ti àjòjì ba wa lati wa béèrè Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- yoo ṣẹ̀ṣẹ̀ maa beere rẹ lọ́wọ́ àwọn saabe rẹ ti o si wa láàrin wọn, ko si nii da a mọ, yoo waa maa sọ pé: Ewo ni Muhammad nínú yin?

Iwa rẹ jẹ arisami nibi pípé ati iyì níbi ibalopọ rẹ pẹ̀lú gbogbo èèyàn pátá, ọ̀tá ni tabi ọrẹ, alasunmọ ni tabi ẹni tí ó jìnà, àgbàlagbà ni tabi ọmọde, ọkùnrin ni tabi obìnrin, ẹranko ni tabi ẹyẹ.

Nígbà tí Ọlọhun pé ẹsin fun un, ti o si jẹ iṣẹ́ naa dáadáa, o kú, ti ọmọ ọdún rẹ si jẹ mẹtalelọgọta, o lo ogójì ọdún ṣíwájú ki o to di ojiṣẹ, o si lo ọdún mẹtalelogun ni ijẹ anọbi ati ojiṣẹ.Wọn sin in si ìlú Mẹdina, ko si fi dúkìá tabi ogún kankan silẹ, ayafi ìbaaka rẹ funfun ti o maa n gun, ati ilẹ̀ kan ti o fi ṣe saara fun onirin-ajo ti agara dá.

Onka àwọn ti wọn gba Isilaamu ti wọn gba a ni ododo ti wọn si tẹle e pọ̀, àwọn ti wọn si ṣe hajj idagbere pẹ̀lú rẹ ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún lọ, iyẹn ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó ku nǹkan bíi oṣù mẹ́ta tí ó máa kú, bóyá èyí náà wà nínú àwọn àṣírí sisọ ẹ̀sìn rẹ àti titanka rẹ̀, àwọn saabe rẹ ti o re wọn lori awọn iwa dáadáa ti Isilaamu ati awọn ìlànà rẹ jẹ onideedee, ti wọn rayesa ti wọn ni àsàjẹ, ati pipe àdéhùn ati ninawo fun ẹsin ńlá ti wọn gbagbọ ninu rẹ yii.

Àwọn ti wọn tobi ju ninu awọn saabe rẹ pátápátá ni ìgbàgbọ́ ati ìmọ̀ ati iṣẹ́ ati imọkanga, ati gbigba ni olododo, ati ninawo, ati nini ìgboyà, ati títa ọrẹ, àwọn naa ni: Abubakr As-Siddiik, ati Umar ọmọ Al-Khọttọọb, ati Uthmaan ọmọ Affaan, ati Aliyy ọmọ Abuu Tọọlib, ki Ọlọhun yọ́nú sí gbogbo wọn, àwọn ni àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti wọn kọ́kọ́ gba a gbọ́ ti wọn si gba a ni olododo, àwọn naa si ni khaleefa lẹ́yìn rẹ ti wọn gbé àsìá ẹsin yii dání lẹ́yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn ko ni ìròyìn kankan nínú àwọn iroyin ijẹ anọbi, ko si da wọn salẹsa pẹ̀lú nǹkan kan láàrin àwọn saabe to ṣẹku.

Ọlọhun da aabo bo Tira rẹ ti o mu wa ati sunna rẹ, ati ìtàn ìgbésí ayé rẹ, ati awọn ọ̀rọ̀ rẹ, ati awọn iṣe rẹ pẹ̀lú èdè rẹ ti o sọ, wọn ko sọ ìtàn ìgbésí ayé ẹni kankan ri nínú ìtàn gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe sọ ìtàn ayé rẹ- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- kódà wọn sọ bi o ṣe n sùn, ati bi o ṣe n jẹ, ati bi o ṣe n mu, ati bi o ṣe n rẹẹrin.Bawo ni o ṣe máa n ba awọn aráalé rẹ lo ninu ilé?Gbogbo iṣesi rẹ pata ni wọ́n ṣọ ti wọn si kọ sínú ìtàn ìgbésí aye rẹ, abara ni, ojiṣẹ si ni, ko ni ìròyìn ijẹ-oluwa, ko si ni ikapa lati ṣe ara rẹ ni anfaani tabi fi ìnira kankan kan ara rẹ.

4 - Iṣẹ-riran rẹ̀.

Ọlọhun ran Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ni iṣẹ lẹ́yìn ti ẹbọ ati aimọkan ti gba gbogbo orí ilẹ̀, ko si ẹni ti n sin Ọlọhun lórí ilẹ̀ lai ṣe ẹbọ pẹ̀lú Rẹ ayafi àwọn díẹ̀ nínú àwọn ahlul-kitaab. Ọlọhun wa ran anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ki o jẹ igbẹyin àwọn anọbi ati awọn ojiṣẹ, Ọlọhun fi imọna ran an, ati ẹsin ododo si gbogbo ayé pátá, ki o le fi borí àwọn ẹsin mìíràn pátápátá, ati ki o le mu àwọn èèyàn kuro nibi okunkun ibọrisa ati keferi ati aimọkan lọ sibi imọle imọ-Ọlọhun-lọkan ati ìgbàgbọ́, iṣẹ́ ti o wa jẹ yii jẹ nǹkan ti o n pé iṣẹ àwọn anọbi ti wọn ṣíwájú (ki ikẹ ati ọla maa ba wọn)

O pepe si gbogbo nǹkan ti àwọn anọbi ati awọn ojiṣẹ pepe si, bii: Nuuh, ati Ibrahim, ati Musa, ati Sulaiman ati Daud, ati Isa, ohun ti wọn pepe si naa ni ìní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa pe Oun ni Ọlọhun, Aṣẹ̀dá, Olupese, Olusọni-di-alaaye, Olusọni-di-oku, Olukapa ìjọba, Oun ni n ṣètò ọ̀rọ̀ ẹ̀dá, Aláàánú Onikẹẹ ni, Oun ni O da gbogbo nǹkan ti n bẹ ni ayé ninu nǹkan ti a n ri ati nǹkan ti a o ri, ẹ̀dá ni gbogbo nǹkan ti o ba ti yàtọ̀ si Ọlọhun.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pepe si ijọsin fun Ọlọhun nìkan, ati fifi ìjọsìn fun nǹkan ti o yatọ si I silẹ, o si ṣàlàyé yekeyeke pe ọkan ṣoṣo ni Ọlọhun ko ni orogun nibi ijọsin Rẹ ati ijọba Rẹ, ati dida ẹ̀dá Rẹ, ati ṣíṣe ètò Rẹ, o ṣi ṣàlàyé pe Ọlọhun ko bimọ, ẹni kankan ko si bi I, Kò sì sí ẹnì kan tí ó jọ Ọ́, ki i bọ sára nǹkan kan nínú ẹ̀dá Rẹ, ki i sii gbe awọ èèyàn wọ

O pepe lọ si ìgbàgbọ́ ninu awọn tira Ọlọhun bii tákàdá (Ànábì) 'Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā, ati Taorāh àti Zabbuur, ati 'Injīl gẹgẹ bi o ṣe pepe si ìgbàgbọ́ ninu awọn ojiṣẹ pátá (ki ọla maa ba wọn), o si ka ẹni ti o ba pe Anọbi ẹyọ kan pere ni opurọ pe ẹni naa ti ṣe Kèfèrí si gbogbo àwọn Anọbi to ṣẹku.

O fun àwọn èèyàn ni iro idunnu ikẹ Ọlọhun, ati pe Ọlọhun ni yoo to wọn ni ilé ayé, ati pe Ọlọhun ni Olúwa Onikẹẹ, Oun ni yoo ṣe iṣiro iṣẹ́ àwọn ẹ̀dá ni ọjọ́ alukiyaamọ nígbà tí Ó ba gbe wọn dide lati inu sàréè wọn, Oun si ni yoo san àwọn Mumini ni ẹsan lori iṣẹ rere ni ilọpo mẹ́wàá ati lori iṣẹ́ burúkú pẹ̀lú irú rẹ, idẹra gbere n bẹ fun wọn ni ọjọ́ ìkẹyìn, ẹni tí ó bá ṣe Kèfèrí tí o ṣe iṣẹ́ buruku, yoo gba ẹsan rẹ ni ayé ati ni ọrun.

Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ko babara ìdílé rẹ tabi ìlú rẹ tabi ara rẹ nibi iṣẹ́ ti o jẹ, kódà wọn dárúkọ àwọn Anọbi bii Nuuh, ati Ibrahim, ati Musa, ati Isa ninu Kuraani ju orúkọ Muhammad gan lọ, wọn o si dárúkọ ìyá rẹ ati awọn iyawo rẹ ninu Kuraani, ti wọn dárúkọ ìyá Musa ju ẹẹkan lọ, wọn si dárúkọ Maryam ni ìgbà maarun-le-lọgbọn.

A ṣọ Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- kuro nibi gbogbo nnkan ti o ba tako shẹria, ati làákàyè, ati adamọ, tabi iwa daadaa; tori pe a ṣọ àwọn Anọbi kuro nibi àṣìṣe níbi iṣẹ́ ti wọn n ba Ọlọhun jẹ; tori pe wọn la jijiṣẹ Ọlọhun fun àwọn ẹrú Rẹ bọ wọn lọrun, àwọn Anọbi yii ko ni ìròyìn ijẹ Oluwa lara tabi iroyin ini ẹtọ si jijọsin fun; ẹda abara ni wọn ti Ọlọhun ran wọn ni iṣẹ́.

Ninu ẹri ti o tobi ju ti o n tọka si pe ijẹ ojiṣẹ Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- jẹ imisi lati ọdọ Ọlọhun naa ni pe o n bẹ titi di oni gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wa nígbà ayé rẹ, àwọn Musulumi ti wọn n tẹle e si ju mílíọ̀nù lọ́nà ẹgbẹ̀rún lọ, wọn n ṣe amulo àwọn ọranyan rẹ bii irun, ati saka, ati aawẹ, ati hajj, ati awọn nǹkan mìíràn, lai yi i pada rárá

5- Awọn arisaami jijẹ anọbi rẹ ati awọn àmì rẹ, ati awọn ẹri rẹ.

Ọlọhun maa n ran àwọn Anọbi lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn àmì ti n tọka si ijẹ anọbi wọn, O si tun maa n fun wọn ni àwọn ẹri ti n jẹrii si riran wọn ni iṣẹ́, Ọlọhun ti fun anọbi kọọkan ni àwọn àmì ti o to fun ẹ̀dá abara lati di olugbagbọ latara rẹ, eyi ti o tobi ju nínú àwọn àmì ti wọn fun àwọn anọbi ni àwọn ami ti O fun Anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a). O fun un ni Kuraani Alapọn-ọnle, oun si ni ami ti yoo ṣẹku ninu awọn ami àwọn Anọbi titi di ọjọ alukiyaamọ, Ọlọhun tun kun un lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn iṣẹ iyanu nla, àwọn àmì Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- pọ, ninu rẹ ni:

Ìrìn-àjò òru àti gigun sanmọ lọ, ati lila si meji oṣupa, ati rirọ ojo ni igba ti o pọ lẹ́yìn ti o ba ṣe adua ki Ọlọhun rọ ojo fun àwọn èèyàn lẹ́yìn tí ọ̀dá ti da wọn.

Ati sisọ ounjẹ ati omi kekere di pupọ, ti awọn eeyan to pọ o si maa jẹ ninu rẹ abi ki wọn mu ninu rẹ.

Ati fi fun ni ni iro nipa awọn ohun ti o pamọ ti o ṣaaju, eleyii ti ẹnikan kan o mọ awọn alaye rẹ, pẹlu ohun ti Ọlọhun fun un ni iro nipa rẹ, gẹgẹ bii awọn itan awọn Anabi (ki alaafia Ọlọhun maa ba wọn) pẹlu awọn ijọ wọn, ati itan àwọn ará inú ihò àpáta.

Ati fifun ni ni iro nipa awọn nnkan ti o pamọ ti yoo maa pada ṣẹlẹ, eleyii ti o papa ṣẹlẹ̀, lẹyin igba ti Ọlọhun ti O mọ ti fun un ni iro rẹ, gẹgẹ bii iro nipa ina eleyii ti yoo jade lati ilẹ Hijaaz, awọn ti wọn wa ni ilu Shaam si ri i, ati ki awọn eeyan maa fi iga gbága nibi kikọ ilé gogoro.

Ati tito ti Ọlọhun to fun un, ati didaabo bo o lọwọ awọn eeyan.

ati mimu adehun ti o ṣe fun àwọn saabe rẹ ṣẹ, gẹgẹ bii ọrọ rẹ ti o sọ fun wọn pe:(Wọn o ṣi Farisí ati Roomu fun yin, wọn si maa na àpótí-ọrọ̀ awọn ilu mejeeji si oju ọna Ọlọhun).

Ati kikun ti Ọlọhun kun un lọwọ pẹlu awọn Malaaika.

Ati fifunni ni iro ti awọn Anabi (ki alaafia Ọlọhun maa ba wọn) fun awọn ijọ wọn ni iro nipa jijẹ Anabi ojiṣẹ tii ṣe Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a), ninu awọn ti wọn fún àwọn ìjọ wọn ni iro naa ni Mûsa, Dăud, Sulaiman ati Isa (Ki alaafia Ọlọhun maa ba wọn), ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn anọbi awọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Ati pẹlu awọn ẹri ti o ba laakaye mu, ati awọn àpẹrẹ ti wọn fi lélẹ̀, eleyii ti laakaye ti o ni alaafia o maa gbà fún.

Àwọn àmì ati awọn àpẹrẹ ti o ba làákàyè mu yii wa káàkiri ninu Kuraani ati Sunna Anọbi, àwọn àmì rẹ pọ ju nǹkan ti a le sọ pé iye bayii ni, ẹni tí o ba fẹ mọ wọn ki o yẹ Kuraani ati awọn tira sunna wo ati awọn tira itan ìgbésí ayé Anọbi, ìró ti o dájú nipa àwọn àmì yii wa ninu wọn.

Awọn aaya ti o tobi yii, ti kii ba ṣe pe wọn ṣẹlẹ ni, àwọn ọ̀tá rẹ bii awọn keferi Kuraeshi, ati awọn Yẹhuudi, ati awọn Nasaara ti wọn wa ni erekusu ilẹ larubawa, wọn o ba ri ọna lati le baa fi pe e ni opurọ, ati lati le baa fi le àwọn èèyàn sa kuro lọdọ rẹ.

Kuraani ni tira ti Ọlọhun fi ranṣẹ si Anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a), oun si ni ọrọ Olúwa àwọn ẹ̀dá, o si fi pe àwọn èèyàn ati awọn alujannu nija lati mu iru rẹ wa tabi iru suura kan bii ti ẹ wa, ipenija naa ṣi n lọ titi di oni, Kuraani si n fesi si awọn ibeere ti o pọ ti o n ko idaamu-daabo ba àìmọye ninu awọn èèyàn. Wọn ṣọ Kuraani titi di oni pẹ̀lú ede larubawa ti o fi sọkalẹ, arafi kan ko dínkù ninu ẹ, wọn tẹ ẹ jade, wọn si pin in káàkiri, iwe ńlá ni ti n kagara ba ẹni ti o ba fẹ mu iru rẹ wa, oun ni iwe ti o tobi ju ti o de wa ba àwọn èèyàn, o ni ẹtọ si kíkà tabi kika ìtumọ̀ rẹ si èdè mìíràn. Ẹni ti ko ba ka a ti ko si ni igbagbo ninu rẹ, gbogbo oore pátá ni o ti bọ mọ ọn lọ́wọ́.Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ pé sunna Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ati imọna rẹ, ati ìtàn rẹ jẹ nǹkan ti a ṣọ ti a si gbà wá lati ipasẹ àwọn ti wọn maa n gba ìtàn wa ti a le gbára lé, wọn tẹ ẹ jade pẹ̀lú èdè larubawa tii ṣe èdè Anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) gẹ́gẹ́ bii pe o n ṣẹmi laarin wa, wọn si ti túmọ̀ rẹ si èdè ti o pọ, Kuraani ati Sunna naa si ni ipilẹ kan ṣoṣo fun àwọn idajọ Isilaamu ati awọn ofin rẹ.

6- Ofin ti ojiṣẹ tii ṣe Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) mu wa -

Ofin eleyii ti ojiṣẹ tii ṣe Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) mu wa naa ni ofin Isilaamu, oun si ni ipari gbogbo awọn ofin ati iṣẹ-riran lati ọdọ Ọlọhun. Ó jọ àwọn ofin awọn Anabi ti wọn ti ṣaaju nibi awọn ipilẹ wọn, ṣùgbọ́n ọna tí a n gba ṣe àmúlò wọn ni o yatọ.

Oun ni ofin ti o pe perepere, ti o si dara fun gbogbo igba ati aaye, ti ohun ti yoo tun ẹsin awọn eeyan ṣe si wa nibẹ ati ile aye wọn, o si ko gbogbo awọn ijọsin sinu, eleyii ti yoo maa jẹ dandan lori gbogbo awọn ẹrusin Ọlọhun, Olúwa gbogbo aye, gẹgẹ bii kiki irun ati yiyọ sàká. Yoo si tun maa ṣalaye fun wọn nípa biba ara ẹni lo ti o jẹ mọ́ owo, ati ti isuna, ati ti àwùjọ, ati ti òṣèlú, ati ti jijagun, ati ti ayika, eyi ti o lẹtọọ ati eyi ti ko lẹtọọ, ati ohun ti o yatọ si i ninu ohun ti isẹmi ọmọniyan ati pipada wọn lọ si ọdọ Ọlọhun n bukaata si.

Ofin yii o maa ṣọ ẹsin awọn eeyan, awọn ẹjẹ wọn, ọmọluwabi wọn, awọn dukia wọn, awọn laakaye wọn, ati awọn arọmọdọmọ wọn. O si ko gbogbo iwa rere ati ṣíṣe dáadáa sinu, yoo si maa ṣọ wọn lara kuro nibi iwa iyẹpẹrẹ ati iwa buruku. O si tun pe awọn eeyan lọ sibi pipọn awọn eeyan le ati wiwa ni iwọntun-wọnsi, ati ṣiṣe deedee, nini imọkanga, mimọra, ṣíṣe nǹkan dáadáa, nini ifẹ, nini ifẹ oore fun awọn eeyan, didena tita ẹjẹ silẹ, nini alaafia ilu, ṣiṣe didẹru ba àwọn èèyàn ni eewọ, ati didẹru ba wọn láìní ẹtọ. Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- maa n gbogun ti ikọja ààlà, ati ìwà ibajẹ pátápátá, o si tun tako ìgbàgbọ́ asán, ati títa kété sí àwọn èèyàn ati rirayesa.

Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ṣàlàyé pe Ọlọhun ṣe apọnle ọmọniyan- ati ọkùnrin ati obìnrin- O si ṣọ ẹtọ onikaluku fun un ni pípé, O si ṣe e ni ẹni ti o maa dahun fun gbogbo nnkan ti o ba n ṣe ni iṣẹ ti o si n hu ni ìwà, O si tun di i ru u dídáhùn fun èyíkéyìí iṣẹ ti o ba ko inira ba ẹmi ara re tabi ko inira ba ẹlomiran. O si ṣe ọkùnrin ati obinrin bakan naa nibi ìgbàgbọ́ ati ojúṣe, ati ẹsan. Shẹria yii ni akolekan lọtọ fun obìnrin, yálà iya ni, tabi ìyàwó, tabi ọmọbìnrin, tabi ẹgbọn lóbìnrin tabi àbúrò lobinrin.

Ofin ti Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- mu wa wa lati wa dáàbò bo làákàyè ati lati ṣe gbogbo nǹkan ti o ba le ba a jẹ ni eewọ, gẹgẹ bii mímu ọtí. Isilaamu ka ẹsin kun imọlẹ ti n tan imọlẹ si oju ọna fun làákàyè ki ọmọniyan le maa sin Ọba rẹ lórí amọdaju ati imọ, shẹria si babara làákàyè o si ṣe e ni okùnfà lila ofin ẹsin bọ ni lọrun, o si la a kuro nibi ẹwọn ìgbàgbọ́ asán ati ibọriṣa

Shẹria Isilaamu n babara imọ ti o ni alaafia, o si n ṣe ni ni ojúkòkòrò lati ṣe ìwádìí ti imọ ti ko si ifẹ-inu nibẹ, o si n pepe si wiwoye ati rironu nipa ẹmi ati ayé, ati awọn abajade ti imọ ti o ni alaafia ti ko tako nnkan ti Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) mu wa.

Ninu shẹria, ko si dida iran kan yatọ si iran mìíràn nínú àwọn èèyàn, ko si si gbigbe ajulọ fun ìjọ kan lori ìjọ mìíràn nínú ẹ, bakan naa ni gbogbo àwọn èèyàn ṣe ri ni iwaju àwọn idajọ rẹ; tori pe àwọn èèyàn pátá dọ́gba ni ipilẹ wọn, ko si ajulọ fun iran kan lori iran kan, ko si si fun ìjọ kan lori ìjọ kan ayafi pẹ̀lú ìpayà, Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- sọ pé gbogbo ọmọ ti wọn ba n bi pátá ni wọn maa n bi lori adamọ, ko si abara kan ti wọn maa bi ni ẹlẹṣẹ tabi ni ẹni ti o maa jogun ẹṣẹ ẹlòmíràn.

Ninu shẹria Isilaamu, Ọlọhun ṣe tituuba ni òfin, oun naa ni: Ki ọmọniyan ṣẹri pada si ọdọ Olúwa rẹ, ati fifi ẹṣẹ silẹ, Isilaamu maa n wo àwọn ẹṣẹ ti èèyàn ba ti ṣẹ ṣíwájú ki o too wọnú rẹ, bẹ́ẹ̀ náà si ni tituuba naa, o maa n pa ẹṣẹ ti o ba ṣáájú rẹ rẹ, ọmọniyan ko bukaata si ki o jẹwọ ẹṣẹ rẹ ni ojú àwọn èèyàn, nínú Isilaamu, ajọṣepọ maa wa laarin ọmọniyan ati Ọlọhun tààrà ni, o ò ni bukaata si ki ẹnikan jẹ alagata laarin rẹ ati Ọlọhun. Isilaamu kọ ki a sọ àwọn ẹ̀dá abara di ooṣa, tabi ki a sọ wọn di orogun fun Ọlọhun nibi ijẹ Olúwa Rẹ ati ini ẹtọ Rẹ si ijọsin.

Ofin ti Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- mu wa ti pa àwọn to ṣíwájú rẹ rẹ, tori pe ọdọ Ọlọhun ni ofin Isilaamu ti wa, oun si ni opin àwọn ofin titi di ọjọ alukiyaamọ, gbogbo ayé pata ni o wa fun, tori ẹ ni o ṣe pa gbogbo ofin ti o ṣíwájú rẹ rẹ, gẹgẹ bi àwọn ofin ti wọn ṣíwájú ṣe pa ara wọn rẹ, Ọlọhun ko nii gba ofin mìíràn yàtọ̀ si ofin Isilaamu, ko si nii gba ẹsin mìíràn yàtọ̀ si ẹsin Isilaamu ti Anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) mu wa, ẹni tí ó bá gba ẹsin mìíràn yàtọ̀ si Isilaamu, wọn o nii gba a lọ́wọ́ rẹ, ẹni tí ó ba fẹ mọ àlàyé ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nipa àwọn ìdájọ́ shẹria yii, ki o wa a ninu awọn tira ti a le fọkàn tan ti o sọ̀rọ̀ nipa Isilaamu.

Dájúdájú erongba shẹria Isilaamu- gẹgẹ bi o ṣe jẹ erongba gbogbo iṣẹ-riran ti ati ọdọ Ọlọhun- ni ki ẹsin ododo gbe ọmọniyan ga ti yoo fi wa jẹ ẹrú ti yoo mọ kanga fún Ọlọhun Ọba gbogbo ẹ̀dá, ti yoo si la a kuro nibi ijẹ ẹru fun ọmọniyan, tabi fun ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, tabi fun ìgbàgbọ́ asán.

Dájúdájú ofin Isilaamu ba gbogbo igba ati aaye mu, ko si si ninu rẹ ohun ti o tako anfaani ọmọniyan ti o ni alaafia; tori pe ọdọ Ọlọhun ni o ti sọkalẹ, Ọba ti O mọ nǹkan ti èèyàn n bukaata si, awọn èèyàn si n bukaata si ofin ti o ni alaafia funra rẹ, ti ko nii maa tako ara wọn, ti yoo si tun àwọn èèyàn ṣe, ti ko nii jẹ pe ọdọ ẹ̀dá abara ni yoo ti wa, bi ko ṣe pe ọdọ Ọlọhun ni yoo ti wa, ti yoo maa fi ọna rere mọ àwọn ènìyàn, ti wọn ba si ti ko ẹjọ lọ ba a ti ọrọ wọn maa gbọ́, ti wọn si maa la kuro nibi iṣe abosi si ara ẹni.

7- Ihà ti àwọn ọta rẹ kọ si i, ijẹrii wọn fun un.

Ko si iyèméjì pe gbogbo anọbi kọ̀ọ̀kan ni o ni àwọn ọta ti wọn maa n gbogun ti i, ti wọn o si nii jẹ ki o ri ipepe rẹ ṣe, ti wọn o si maa ṣẹri àwọn èèyàn kúrò nibi ini ìgbàgbọ́ si i. Anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ni àwọn ọ̀tá ti o pọ ni igba aye rẹ ati lẹ́yìn ikú rẹ, Ọlọhun si mu u borí gbogbo wọn pátá, ọpọlọpọ ninu wọn- tipẹ tipẹ ati nsinyii- ni wọn jẹrii pe Anọbi ni, ati pe nǹkan ti àwọn anọbi ti wọn ṣíwájú mu wa ni oun naa mu wa, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá wọn, wọn si mọ pe ori ododo ni o wa, ṣùgbọ́n àwọn idiwọ ti o pọ ni ko jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn le ni ìgbàgbọ́ si i, gẹgẹ bii ìfẹ́ ijẹ-adari tabi ibẹru àwùjọ, tabi pipadanu owó ti o n ri nibi ipò rẹ.

Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Ojogbon Muhammad omo Abdullaah As-Suhaym ni o kọ ọ.

Olukọ imọ adisọkan ni ẹka awọn ẹkọ Isilaamu (ni igba kan rí)

Kọlẹẹji imọ-ẹkọ, ni ile-ẹkọ gíga ti Al-Malik Suhuud.."

Ar-Riyaadh, Kingdom of Saudi Arabia.. "

Òjíṣẹ́ awọn mùsùlùmí anọbi Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba a)

1- Orúkọ rẹ, ati ìran rẹ, àti ilu ti wọn ti bí i tí o sì dàgbà si.

2- Igbeyawo alalubarika pẹ̀lú aṣiwaju lobinrin alalubarika.

Bibẹrẹ wáàyí (imisi)

4 - Iṣẹ-riran rẹ̀.

5- Awọn arisaami jijẹ anọbi rẹ ati awọn àmì rẹ, ati awọn ẹri rẹ.

6- Ofin ti ojiṣẹ tii ṣe Muhammad (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) mu wa -

7- Ihà ti àwọn ọta rẹ kọ si i, ijẹrii wọn fun un.

معلومات المادة باللغة العربية