Description
Iwe yi so nipa awon ohun ti o je dandan fun Musulumi lati mo ninu esin re papaajulo lori imo adiokan
Altre traduzioni 38
Topics
Adisọkan to ni alaafia ati ohun ti o takò ó, ati awọn nǹkan ti o maa n ba Isilaamu jẹ "
Òǹkọ̀wé
Olùmọ̀ àgbà Sheikh Abdul Aziz bin Abdullah bin Baz "
Pẹlu orukọ Ọlọhun Ọba Ajọkẹ ayé Àṣàkẹ́ ọrun.
Ọrọ isiwaju
Ọpẹ ni fun Ọlọhun nikan, ikẹ ati ọla ki o lọ maa ba ẹniti ko si Anọbi kankan mọ lẹyin rẹ, ati lori awọn ara ile rẹ ati awọn saabe rẹ.
Lẹ́yìn náà: Nígbà tí adisọkan tí ó ní àlàáfíà jẹ ìpìlẹ̀ ẹsin, ìdí nìyẹn ti mo fi wò ó pé ki o jẹ àkòrí idanilẹkọọ naa. Ohun ti a mọ pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí ṣẹria láti inú Kuraani ati Hadiisi ni pé àwọn iṣẹ́ ati ọ̀rọ̀ maa ni àlàáfíà ti wọn si maa jẹ itẹwọgba ti wọn ba jáde latara adisọkan tí ó ni àlàáfíà. Ti adisọkan ko ba ni àlàáfíà, gbogbo nǹkan ti o ba jáde latara rẹ bii iṣẹ ati ọrọ maa bajẹ ni, gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pé: Wọ́n ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fun yín lónìí. Àti oúnjẹ àwọn tí A fún ní tírà, ẹ̀tọ́ ni fun yín.1 Oúnjẹ tiyín náà, ẹ̀tọ́ ni fún wọn. (Ẹ̀tọ́ ni fun yín láti fẹ́) àwọn olómìnira nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin àti àwọn olómìnira lóbìnrin nínú àwọn tí A fún ní tírà ṣíwájú yín, nígbà tí ẹ bá ti fún wọn ní ṣọ̀daàkí wọn; ẹ fẹ́ wọn ní fífẹ́ (bí 'Islām ṣe ní kí ẹ fẹ́ ìyàwó), láì níí bá wọn ṣe sìná (ṣíwájú yìgì) láì sì níí yàn wọ́n lálè.2 Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí ìgbàgbọ́ òdodo, iṣẹ́ rẹ̀ ti bàjẹ́. Ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ó sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò. [Al-Mâ'idah: 5]. Allah tun sọ pe: Dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn t'ó ṣíwájú rẹ (pé) "Dájúdájú tí o bá ṣẹbọ, iṣẹ́ rẹ máa bàjẹ́. Dájúdájú o sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò." [Az-Zumar:65] Awọn Aayah ti o wa pẹlu itumọ yii pọ, ati pe iwe Ọlọhun ti o han ati Hadiisi ojisẹ Rẹ olufọkantan lati ọdọ Ọlọhun rẹ- ki eyi to daa ju ninu ikẹ ati ọla maa ba a- da lori pe adisọkan to ni alaafia kójọ ní ṣókí si ara nini igbagbọ ninu Ọlọhun ati awọn Malaika Rẹ ati awọn iwe Rẹ ati awọn ojisẹ Rẹ ati ọjọ ikẹyin ati ninu kadara, daada rẹ ati aburu rẹ̀.. Nitori naa awọn àlámọ̀rí mẹfẹẹfa yii naa ni awọn ìpìlẹ̀ adisọkan to ni alaafia eleyi ti iwe Ọlọhun Abiyi sọkalẹ pẹlu ẹ, ti Ọlọhun sì gbe Anọbi Muhammad dide pẹlu ẹ (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a). " Gbogbo nkan ti o yẹ ka ni igbagbọ ninu ẹ ninu awọn alamọri kọkọ ni o jẹ jade lati ara awon ipile yii, ati gbogbo nkan ti Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ fun wa ni iro nipa rẹ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati pe awọn ẹri awọn ìpìlẹ̀ mẹfẹẹfa yii wa ninu iwe Ọlọhun ati ọrọ ojisẹ Rẹ pọ gidi gan, ninu rẹ ni ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe: " { Kì í ṣe ohun rere ni kí ẹ kọjú sí agbègbè ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn, àmọ́ (olùṣe) rere ni ẹnikẹ́ni t'ó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu, Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn mọlāika, Tírà (al-Ƙur'ān), àti àwọn Ànábì} Suuratul Baqara: 177 Aayah, ati ọrọ Rẹ, mimọ ni fun Un, ti o sọ pé:" {Òjíṣẹ́ náà (sollalāhu 'alayhi wa sallam) gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀.} Suuratul Baqara: 285 Ati ọrọ Rẹ, mimọ ni fun Un, ti o sọ pe:" Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ gbàgbọ́ dáadáa nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí (Allāhu) sọ̀kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti Tírà tí Ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti Ọjọ́ Ìkẹyìn, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà t'ó jìnnà tefétefé. Suuratun-Nisai: 136. Ati ọrọ Rẹ, mimọ ni fun Un, ti o sọ pé:" Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l'Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Dájúdájú (àkọsílẹ̀) ìyẹn wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu. (Al-Hajj:70) Sugbọn awọn Hadiisi ti o ni alaafia ti o da lori awọn ìpìlẹ̀ yii pọ gidi gan, ninu ẹ ni Hadiisi ti o ni alaafia ti o gbajugbaja eleyi ti Muslim gba a wa ninu sohiihu re ninu Hadiisi adari awọn musulumi Umar ọmọ Al-Khattob- ki Ọlọhun yọnu si i- pe dajudaju Jibril- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- bi Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa igbagbọ, ti o si sọ fun un pe: " Igbagbọ ni ki o gbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn Mọlaika Rẹ, ati awọn iwe Rẹ, ati Ojisẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ati ki o gbagbọ ninu kadara, daada rẹ̀ ati aburu rẹ̀Hadiisi, " Ti Bukhari ati Muslim mu u jade ninu Hadiisi Abu Huraira. " Awọn ìpìlẹ̀ mẹfẹẹfa yii: Gbogbo nkan ti o jẹ dandan fun Musulumi lati di sọkan jẹ jade latara wọn nipa iwọ Ọlọhun, mimọ ni fun Un, ati nipa alamọri alukiyaamọ, ati nkan ti o yatọ si iyẹn ninu awọn alamọri kọkọ. "
Igbagbọ ninu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga"
Nini igbagbọ pe dajudaju Allāhu náà ni Ọlọhun ododo ti O lẹtọọ si ijọsin yatọ si gbogbo nkan ti o yatọ si I"
Ninu igbagbọ ninu Ọlọhun, mimọ ni fun Un, ni nini igbagbọ pe dajudaju Òun ni Ọlọhun ti O lẹtọọ si ijọsin yatọ si gbogbo nkan ti o yatọ si I; nitori pe O jẹ Aṣẹ̀dá awọn ẹrusin ti O si jẹ Oluṣe dáadáa si wọn, ti O n mu awọn ijẹ-imu wọn wa fun wọn, ti O ni imọ nipa kọkọ wọn ati gbangba wọn, ti O ni ikapa lati san awọn olutẹle E ninu wọn ni ẹsan, ati lati jẹ awọn oluyapa Rẹ ni iya; nitori ijọsin yii naa ni Ọlọhun ṣe da awọn eeyan ati alujannu, ti O si pa wọn lasẹ pẹlu rẹ, gẹ́gẹ́ bí Ọba ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pé: " Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi. Suuratudh Dhāriyāt: 56. Èmi kò gbèrò arísìkí kan láti ọ̀dọ̀ wọn. Èmi kò sì gbèrò pé kí wọ́n máa bọ́ Mi. "[Adh-Dhâriyât: 57] Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùpèsè, Alágbára líle. [Adh-Dhâriyât: 58] Ọlọhun ti O mọ tun sọ pe : Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó da ẹ̀yin àti àwọn t'ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè ṣọ́ra (fún ìyà Iná). Suratul Baqara: 21 (Ẹ jọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fun yín ní ìtẹ́, (Ó ṣe) sánmọ̀ ní àjà, Ó sọ omi òjò kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì fi mú àwọn èso jáde ní ìjẹ-ìmu fun yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ẹ sì mọ̀ (pé kò ní akẹgbẹ́). (Al-Bakorah 22) Ọlọhun ti ran awọn Ojisẹ, O si ti sọ awọn iwe kalẹ lati ṣe alaye òdodo yii ati pipepe lọ sibẹ, ati ṣiṣe ikilọ kuro nibi nkan ti o tako o, gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun ṣe sọ pe: " Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà." Suratul Nahl: 36 Allah tun sọ pe: A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: "Dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi." Suratul Anbiyaa: 25 Ọba ti O niyi ti O si tobi sọ pe: 'Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà tí wọ́n ti to àwọn āyah inú rẹ̀ ní àtògún régé, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán. (A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé ẹ má jọ́sìn fún kiní kan àfi Allāhu. Dájúdájú emi ni olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. [Huud:1 - 2]. Paapaa ijọsin yii n bẹ nibi mimu Ọlọhun ti O mọ ni ọkan ṣoṣo nibi gbogbo ohun ti ẹru yoo maa fi ṣe ijọsin bíi ṣiṣe adua, pipaya, ṣiṣe agbiyele, kiki irun, gbigba awẹ, didunbu nnkan, ṣiṣe ileri ati awọn nnkan miran ninu awọn onírúurú ijọsin lojupọna titẹriba fun Un, ati nini ojukokoro nnkan ati ibẹru pẹlu ki ifẹ ti o pe perepere o wa fun Un (Ọba ti O mọ) ati yi yẹpẹrẹ ara ẹni fun titobi Rẹ, ọpọlọpọ Alukurani si sọkalẹ nípa ìpìlẹ̀ nla yii, gẹgẹ bii ọrọ Rẹ (Ọba ti O mọ): Nítorí náà, jọ́sìn fún Allāhu ní olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un. Gbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́. Sūratuz Zumar: 2-3 Ọrọ Ọlọhun ti O mọ sọ pe: Olúwa rẹ pàṣẹ pé: "Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan Al-Isroo: 23 Ọba ti O niyi ti O si tobi sọ pe: Nítorí náà, ẹ pe Allāhu ní ti olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira Rẹ̀. [Gaafir: 14]. Ninu Saheehu mejeeji, lati ọdọ Muaadh - Ki Ọlọhun ba wa yọnu si i - dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin Rẹ ni pe ki wọn maa jọsin fun Un, bakannaa ki wọn si ma mu orogun kankan pẹlu Rẹ.
Nini igbagbọ si gbogbo ohun ti O ṣe ni dandan ati ni ọranyan lori awọn ẹrusin Rẹ nipa awọn origun Isilaamu maraarun ti o fojú hàn kedere
Ninu ìní igbagbọ si Ọlọhun bakannaa ni nini igbagbọ si gbogbo ohun ti O ṣe ni dandan ati ni ọranyan lori awọn ẹrusin Rẹ nipa awọn origun isilaamu maraarun ti o fojú hàn kedere. Oun naa si ni jijẹri pe ko si Ọba kankan ti ijọsin ododo tọ si ayafi Ọlọhun ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Ọlọhun, ati mimaa gbe irun duro, yiyọ Zakah, gbigba awẹ Ramadan, ati lilọ si ile Oluwa Abiyi fun ẹniti o ba ni ikapa rẹ, ati awọn nnkan miran ninu awọn nnkan ọranyan ti ṣẹria mu wa ti o mọ.
Eleyii ti o pataki ti o si tobi julọ ninu awọn origun yii ni jijẹri pe ko si Ọba kankan ti ijọsin ododo tọ si ayafi Ọlọhun ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Rẹ. Jijẹrii pe ko si Ọba kankan ti ijọsin ododo tọ si ayafi Ọlọhun ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Rẹ yoo maa bukaata si nini imọkanga si ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo ati lile ohun ti o ba yatọ si i jina. Eleyii ni itumọ 'Laa ilaaha illa Laah', itumọ rẹ si ni pe ko si Ọba kankan ti ijọsin ododo tọ si ayafi Ọlọhun nikan. Gbogbo ohun ti wọn ba si jọsin fun yatọ si I ninu eeyan, malaika, alijannu ati awọn nnkan miran yoo ma jẹ ijọsin irọ, eniti eeyan le jọsin fun lododo naa ni Allaah nikan gẹgẹ bi Ọba ti O mọ ṣe sọ: Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Ó ga, Ó tóbi. [Hajj:62] Alaye ti ṣaaju lori pe Ọlọhun (Ọba ti O mọ) da awọn alijannu ati eeyan nitori ipilẹ ojúlówó yii, O si pa wọn laṣẹ rẹ, O si tori rẹ ran awọn ojiṣẹ Rẹ ni iṣẹ, O si titori rẹ sọ awọn tira Rẹ kalẹ. Woye si i daadaa, ki o si tun ronu si i lọpọlọpọ ki o le baa han si ọ ohun ti ọpọlọpọ musulumi ko sinu rẹ latari ṣiṣe aimọkan ti o tobi si ipilẹ ojúlówó yii ti o si mu wọn jọsin fun nnkan miran yatọ si I, ti wọn si tun yi iwọ Rẹ ti o foju han si ẹlomiran, Ọlọhun ni Oluranlọwọ.
Nini igbagbọ si Ọlọhun lori pe Oun ni Aṣẹ̀dá aye, Oludari gbogbo alamọri wọn, ati Oluṣe akoso laarin wọn pẹlu imọ ati ìkápá Rẹ.
Ninu nini igbagbọ si Ọlọhun (Ọba ti O mọ) naa ni nini igbagbọ pe Oun ni Adẹdaa aye, Oludari gbogbo alamọri wọn ati Oluṣe akoso laarin wọn pẹlu imọ ati ìkápá Rẹ gẹgẹ bi o ba ṣe wu U. Ati pe Oun ni Olukapa aye ati ọrun ati Olúwa gbogbo ẹda lapapọ, ko si Aṣẹ̀dá kankan ti o yatọ si I, ko si si Olúwa kankan ti o yatọ si I. Ati pe dajudaju Ọlọhun Ọba ran awọn ojisẹ, O si sọ awọn tira kalẹ fun atunṣe awọn ẹrusin ati lati pe wọn lọ sí ibi ti ọlà ati dídára wọn wa ni aye ati ọjọ igbende. Ati pe dajudaju Ọlọhun Ọba ti O ga julọ, ko si orogun fun Un nibi gbogbo iyẹn, gẹgẹ bi Ọlọhun ṣe sọ pé: " Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan. [Zumar: 62] Allah tun sọ pe: Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá. Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá. Ṣūratul A'rōf: 54.
Nini igbagbọ pẹlu awọn orukọ Ọlọhun Ọba ti o dara julọ ati awọn iroyin Rẹ laisi ayipada tabi sisọ pe ko ri bẹ́ẹ̀, tabi sísọ bi o ṣe rí, tabi isafiwe "
Ninu ìgbàgbọ́ ninu Ọlọhun naa ni ìgbàgbọ́ ninu awọn orúkọ Rẹ ti o dara ju, ati awọn ìròyìn rẹ ti o ga julọ ti o wa ninu Kuraani ati eyi ti o rinlẹ lati ọdọ ojiṣẹ Rẹ ti o ṣee fi ọkàn tán, laisi ayipada tabi sisọ pe ko ri bẹ́ẹ̀, tabi sísọ bi o ṣe rí, tabi isafiwe,dandan ni ki o lọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wa lai sọ bi o ṣe rí, pẹ̀lú ini ìgbàgbọ́ si nǹkan ti o n túmọ̀ sí tii ṣe àwọn iroyin Ọlọhun- Alágbára ti O gbọnngbọn- dandan ni ki a fi ròyìn Rẹ ni ọna ti o yẹ Ẹ́ láìní jọ ẹ̀dá Rẹ rara nibi awọn ìròyìn Rẹ, gẹgẹ bi Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pé: "ko si nkankan ti o da bii Rẹ, Oun si ni Ọba ti ngbọ gbogbo nkan ti O si nri gbogbo nkan" Suuratu Shuuroh: 11. Ọlọhun- Alágbára ti O gbọnngbọn- sọ pé: Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn àkàwé náà lélẹ̀ nípa Allāhu. Dájúdájú Allāhu nímọ̀; ẹ̀yin kò sì nímọ̀. Suurotun Nahl: 74 Eyi ni adisọkan àwọn Ahlu Sunnah Wal Jamaa'ah ninu awọn sàábé ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ati awọn olùtẹ̀lé rẹ pẹ̀lú dáadáa, oun naa ni Imam Abul Hasan Al-Ash'ariy- ki Ọlọhun kẹ ẹ- gbé wa ninu tira rẹ "AL-MAQAALAATU AN AS'HAABIL HADIITH WA AHLIS SUNNAH", àwọn mìíràn yàtọ̀ si i naa si gbe e wa nínú àwọn onímímọ̀ ati ìgbàgbọ́ Alfa Aozaahii- ki Ọlọhun ba ni kẹ ẹ- sọ pe: Wọn beere lọwọ Az'zuurih ati Mak'huulu nipa awọn aaya ti wọn n tọka lori iroyin Ọlọhun, wọn si dahun pe: Ẹ jẹ́ ki ó lọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wá Al-Waleed bn Muslim- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- sọ pe: Wọn beere lọwọ Maalik ati Al-Aozaahii ati Laethu bn Sa'd ati Sufyaanu Thaorii nipa awọn iro ti wọn wa ninu awọn iroyin, gbogbo wọn waa sọ lapapọ pe: Ẹ jẹ́ ki ó lọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wá lai sọ bi o ṣe rí. Al-Aozaa'hiy- ki Ọlọhun kẹ ẹ- sọ pe: "A maa n sọ lójú àwọn taabihuun pe Ọlọhun n bẹ lókè àga alaaraṣi Rẹ, a sì ni ìgbàgbọ́ si ohun ti o wa ninu sunna ninu awọn ìròyìn. Nigba ti wọn bi Rabeehah ọmọ Abu Abdur-Rahmaan tii ṣe àlùfáà fun Maalik- ki Ọlọhun kẹ àwọn méjèèjì- léèrè nipa ìgúnwà, o sọ pé: Ìgúnwà, kii ṣe nǹkan ti a kò mọ̀, ki a fẹ mọ bi o ṣe ri ko ba làákàyè mu, ọdọ Ọlọhun ni ìránṣẹ́ ti wa, ti ojiṣẹ ni ki o jiṣẹ, tiwa si ni ki a gba a ni ododo. Nigba ti wọn bi Imam Maalik- ki Ọlọhun kẹ ẹ- leere nipa ìyẹn, o sọ pé: (Ìgúnwà, nǹkan ti a mọ ni, bi o ṣe ri ni a o mọ̀, o si di dandan ki a gba a gbọ́, adadaalẹ si ni ki a maa beere nípa rẹ̀) Lẹyin naa ni o wa sọ fún onibeere pe: Mi o ri ọ si nǹkan kan ju èèyàn burúkú lọ, o wa sọ pe ki wọn lé e bọ́ síta. Wọn si gba itumọ yii wa lati ọdọ iya awọn muumini ummu salamọ (ki Ọlọhun ba ni yọnu si i). Imaamu abu Abdirrohmaan bn Mubaarok- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- sọ pe :" A mọ̀ pe Olúwa wa n bẹ loke àwọn sánmà Rẹ lori àga alaaraṣi Rẹ, O si takété si ẹ̀dá Rẹ. Ọrọ àwọn imaamu nipa àkòrí yii pọ̀ gan, a o le gbe e wa nibi idanilẹkọọ yii, ẹni tí ó ba fẹ mọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ninu ẹ, ki o lọ ṣe àyẹ̀wò ohun ti àwọn onímímọ̀ sunna kọ nípa àkòrí yii, gẹ́gẹ́ bíi tira "AS-SUNNAH" ti Abdullaah ọmọ Imam Ahmad, ati tira "AT-TAOHEED" ti Imam agba Muhammad ọmọ Khuzaymah, ati tira "AS-SUNNA" ti Abul Qaasim Al-Laalakaa'iy At-Tabariy, ati tira "AS-SUNNA" ti Abu Bakr ọmọ Haasim, ati èsì sheikhul Islaam Ibnu Taymiyyah fun àwọn ará Hamaat, esi ńlá si ni ti o kun fun anfaani, o ṣàlàyé adisọkan àwọn ahlus sunna ninu ẹ, o si gbe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọn wá nínú ẹ, ati awọn ẹri ti ṣẹria ati ti làákàyè lórí ìní àlàáfíà ohun ti àwọn ahlu sunna sọ, ati ibajẹ ohun ti àwọn alátakò wọn sọ Báyìí naa ni tira rẹ ti o n jẹ AT-TADMURIYYAH, o ṣàlàyé adisọkan àwọn ahlu sunna nínú ẹ pẹ̀lú ẹri rẹ lati inu Kuraani ati Hadiisi ati ẹri rẹ ti làákàyè, ati fífọ èsì fun àwọn alátakò pẹ̀lú nǹkan ti o maa fi òdodo hàn ti o si maa borí irọ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá woye sí ìyẹn nínú àwọn onímímọ̀, pẹ̀lú àníyàn rere ati inifẹẹ mímọ òdodo. Gbogbo ẹni tí o ba yapa àwọn ahlus sunna níbi adisọkan wọn ninu àkòrí àwọn orúkọ Ọlọhun ati awọn ìròyìn Rẹ, dandan ni ki onítọ̀hún ko sínú yiyapa àwọn ẹ̀rí inu Kuraani ati Hadiisi, ati ẹri ti làákàyè pẹ̀lú titako ara ti o fojú hàn nibi gbogbo nǹkan ti o ba n fi rinlẹ ati nǹkan ti o n takò Ṣugbọn àwọn ahlus sunna wal jamaa'ah fi rinlẹ fun Ọlọhun nǹkan ti O fi rinlẹ fun ara Rẹ ninu Kuraani, tabi eyi ti ojiṣẹ Rẹ Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- fi rinlẹ fun Un ninu Hadiisi rẹ ti o ni àlàáfíà ni ifirinlẹ ti ko si afiwe nibẹ, wọn si fọ Ọ mọ kúrò nibi jijọ ẹ̀dá Rẹ, láìsí sísọ pé nǹkan ko ri bẹ́ẹ̀ nibẹ, ìdí nìyí tí wọn fi là kúrò nibi titako ara, wọn si lo gbogbo ẹri pátá. Eyi ni ìlànà Ọlọhun fun ẹni tí o ba dirọ mọ òdodo ti O fi ran àwọn ojiṣẹ Rẹ, ti o si sapá rẹ nibẹ, ti o si ṣe òtítọ́ fun Ọlọhun nibi wíwá a, ki O fi ṣe kongẹ òdodo, ki O si fi ẹri Rẹ hàn, gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun ṣe sọ pé: Rárá o! À ń sọ òdodo lu irọ́ (mọ́lẹ̀ ni). Òdodo sì máa fọ́ agbárí irọ́. Irọ́ sì máa pòórá. [Al-Anbiyaa: 18] Allah tun sọ pe: Wọn kò níí mú àpẹẹrẹ kan wá fún ọ (bí ìbéèrè láti fi takò ọ́) àfi kí Á mú òdodo (ìyẹn, al-ƙur'ān) àti àlàyé t'ó dára jùlọ wá fún ọ (lórí rẹ̀). [Al-Fur'qaan: 33] Al-Haafidh, Ibn Katheer (Ki Ọlọhun kẹ ẹ) darukọ ninu tira Tafsiiri rẹ ti o gbajumọ nígbà tí ó ń sọrọ nípa ọrọ Ọlọhun - Ọba ti O tobi – ti O sọ pe: Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá} [A'raaf: 54]. Ọrọ kan ti o dara nibi àkòrí yii, mimu un wa sibi yii si maa dara latari anfaani rẹ ti o tobi. O sọ- ki Ọlọhun kẹ ẹ- pe: Àwọn eeyan sọ ọrọ ti o pọ gan ni ààyè yii, ibi kọ ni a ti maa ṣàlàyé rẹ, ṣùgbọ́n a maa tọ ojú ọna àwọn ẹni ìṣáájú rere ni aaye yii, bii: Maalik, ati Al'Aozaa'iy, ati Ath'Thaoriy, ati Al-Layth ọmọ Sah'd, ati Ash-Shaafihiy, ati Ahmad, ati Is'haaq ọmọ Raahawaih, ati awọn mìíràn nínú àwọn aṣáájú àwọn Mùsùlùmí àtijọ́ ati òde òní, oun naa ni jijẹ kí ó lọ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wá, lai sọ bí ó ṣe rí, tabi afiwe, tabi sisọ pe ko ri bẹ́ẹ̀. Ohun ti o si kọkọ maa wa si làákàyè àwọn aláfiwé jẹ nǹkan ti a ko le fi rinlẹ fun Ọlọhun; tori pé ko si nǹkan kan ti o jọ Ọlọhun nínú ẹ̀dá Rẹ, ko si si nǹkan ti o da bii Rẹ, Olugbọ ni, Olùríran ni. Bi ọ̀rọ̀ náà ṣe ri naa ni bi àwọn aṣáájú ẹsin ṣe sọ, ninu wọn ni Nuhaym ọmọ Hammaad Al-Khuzaa'iy tii ṣe alfa Al-Bukhaari, o sọ pe: Ẹni ti o ba fi Ọlọhun jọ ẹ̀dá Rẹ ti di Kèfèrí, ẹni tí ó bá tako ohun ti Ọlọhun fi ròyìn ara Rẹ̀ ti di Kèfèrí, ko si afijọ kankan nibi ohun ti Ọlọhun fi ròyìn ara Rẹ tabi eyi ti Ojiṣẹ Rẹ fi royin Rẹ, ẹni tí ó ba fi ohun ti àwọn aaya ti o la ọrọ mọ́lẹ̀ ati awọn hadiisi ti o ni àlàáfíà ni ọna ti o gbà yẹ Ọlọhun rinlẹ, ti ko si ṣe afirinlẹ àbùkù fun Un, onítọ̀hún ti tọ ojú ọ̀nà ìmọ̀nà.
Nini igbagbọ si awọn Malaika.
Amọ gbígba awọn Malaika gbọ: Yoo maa ko gbigba wọn gbọ lapapọ ati ni ifọsiwẹwẹ, Musulumi si maa gbagbọ pe Ọlọhun ni awọn Malaika kan ti O da wọn lati le maa tẹle E, O si royin wọn pe ẹru alapọn-ọnle ni wọn, wọn kì í ṣíwájú Allāhu sọ̀rọ̀. Wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. (Allāhu) mọ ohun t'ó ń bẹ níwájú wọn àti ohun t'ó ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì níí ṣìpẹ̀ (ẹnì kan) àfi ẹni tí (Allāhu) bá yọ́nú sí. Wọ́n tún ń páyà fún ìbẹ̀rù Rẹ̀. [Al-Anbiyaa: 28] Awọn iran wọn pọ, ninu wọn ni awọn ti wọn n mojuto gbigbe itẹ ọla Ọlọhun dani, ninu wọn ni awọn ẹ̀ṣọ́ alijanna ati ina, ninu wọn ni awọn alamojuto ṣiṣọ awọn iṣẹ awọn ẹrusin. A maa ni ìgbàgbọ́ ninu awọn ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ dárúkọ nínú wọn ni ifọsiwẹwẹ, ninu wọn ni Jibreel, Mikaaiil, Maalik ti o jẹ ẹ̀ṣọ́ ina, Israafeel ti o jẹ alamojuto fifọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Wọn dárúkọ rẹ ninu awọn Hadiisi ti o ni alaafia, o si rinlẹ lati ọdọ Aisha- (ki Ọlọhun yọnu si i) pe Anabi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ pe: Wọn da awọn Malaika latara imọle, wọn si da awọn alijannu latara awọn ina ti ko ni eefin, wọn si da Aadamọ latara ohun ti wọn royin rẹ fun yin Muslim lo gbe e jade ninu sohiihu rẹ. "
Nini igbagbọ si awọn tira Ọlọhun
Báyìí naa ni ìgbàgbọ́ nínú àwọn tira ṣe rí, o di dandan ki a gbagbọ pe Ọlọhun (Ọba ti O mọ) sọ awọn tira kalẹ fun awọn Anabi Rẹ ati awọn ojiṣẹ Rẹ lati le ṣalaye ododo Rẹ ati lati le fi pepe lọ sibẹ. Gẹgẹ bi Ọlọhun ṣe sọ pe: Dájúdájú A fi àwọn ẹ̀rí t'ó yanjú rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa. A sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn àti òṣùwọ̀n nítorí kí àwọn ènìyàn lè rí déédé ṣe (láààrin ara wọn). [Al-Hadeed:25] Allah tun sọ pe: Àwọn ènìyàn jẹ́ ìjọ kan ṣoṣọ (ẹlẹ́sìn 'Islām nípìlẹ̀). Allāhu sì gbé àwọn Ànábì dìde ní oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn pẹ̀lú òdodo nítorí kí Ó lè fi ṣe ìdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn nípa ohun tí wọ́n yapa ẹnu sí. Kò sì sí ẹni t'ó yapa ẹnu (sí 'Islām) [Al-Baqorah: 213] A o si tun maa gbagbọ ni ifọsiwẹwẹ ninu ohun ti Ọlọhun darukọ ninu wọn bii Taoorat, Injeel, Zabuur ati Alukurani ti o lọla ju ti o si jẹ opin wọn, ti o si ń wá ààbò fún àwọn òfin inú wọn, ti o si n jẹ́rìí sí èyí t'ó jẹ́ òdodo nínú wọn, oun ni yoo maa jẹ dandan fun gbogbo ijọ lati tẹle e, ti wọn o si maa fi ṣe idajọ pẹlu ohun ti o ni àlàáfíà nínú sunnah ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nitori pe Ọlọhun gbe ojiṣẹ Rẹ tii ṣe Muhammad dide ni ojiṣẹ si gbogbo awọn ẹda alijannu ati eeyan. O si sọ Alukurani kalẹ fun un lati fi maa dajọ, O si ṣe e ni iwosan fun (aisan) ti n bẹ ninu igbaaya ati ni alaye fun gbogbo nnkan ati ni imọna, ikẹ fun awọn olugbagbọ ododo, gẹgẹ bi Ọba ti O ga ṣe sọ pe: Èyí ni Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Kí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu) nítorí kí A lè kẹ yín. [Al-An`am: 155]" Ọlọhun ti O mọ tun sọ pe : A sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; (ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan, ìmọ̀nà, ìkẹ́ àti ìró ìdùnnú fún àwọn mùsùlùmí. An-Nah'l 89 Allah tun sọ pe: {Sọ pé: "Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu sí gbogbo yín pátápátá. (Allāhu) Ẹni t'Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni t'ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ẹ tẹ̀lé e nítorí kí ẹ lè mọ̀nà. 158} Suratul A'raf: 158 Awọn Aayah to wa lori itumọ yii pọ. "
Nini igbagbọ si awọn ojiṣẹ [Ọlọhun]
Gege bẹẹ naa ni awọn ojiṣẹ, nini igbagbọ ninu wọn jẹ dandan lapapọ ati ni ifọsiwẹwẹ, a maa ni igbagbọ pe dajudaju Ọlọhun, mimọ ni fun Un, ran awọn ojisẹ kan si awọn ẹrusin Rẹ nínú wọn, ní olufunni ni iro idunnu ati oluṣe ikilọ, ati awọn olupepe lọ si ibi ootọ, eniti o ba wa da wọn lohun maa jere pẹlu oriire, ẹni tí o ba wa yapa wọn si máa pòfo, o si maa ká àbámọ̀, òpin wọn ati ẹniti o dáa ju ninu wọn ni Anọbi wa Muhammad ọmọ Abdulahi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gẹ́gẹ́ bí Ọlọhun, mimọ ni fun Un, ṣe sọ pe: " Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà." Suratun Nahl: 36 Allah tun sọ pe: {(A ṣe wọ́n ní) Òjíṣẹ́, oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀ nítorí kí àwíjàre má lè wà fún àwọn ènìyàn lọ́dọ̀ Allāhu lẹ́yìn (tí) àwọn Òjíṣẹ́ (ti jíṣẹ́)} Suuratun Nisai: 165. Allah tun sọ pe: {(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì.} Suratul Ahzab: 40 Ẹni tí Ọlọhun ba dárúkọ, tabi ti sisọ orukọ ẹ fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun, a maa gba a gbọ́ ni ifọsiwẹwẹ ati ṣiṣe adayanri, gẹ́gẹ́ bíi Nuuh, atu Huud, ati Solih, ati Ibroheem, ati ẹniti o yatọ si wọn, eyi to dára julọ ninu ikẹ ati eyi ti o mọ julọ ninu ọla ki o maa ba wọn ati Anọbi wa. "
Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin.
Sugbọn nini igbagbọ ninu ọjọ ikẹyin: "
Nini igbagbọ pẹlu gbogbo nkan ti Ọlọhun fun wa ni iro nipa ẹ ati Ojisẹ Rẹ -Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọ inu ẹ, àti ohun ti o maa ṣẹlẹ̀ lẹyin ikú, gẹgẹ bii idaamu inu saare ati iya inu ẹ, ati idẹra inu ẹ, ati nkan ti yoo sẹlẹ ni ọjọ igbende ninu awọn ẹru ati awọn ilekoko, ati afárá asiraati, ati òṣùwọ̀n, ati iṣiro, ati ẹsan, ati fifọn awọn ìwé iṣẹ́ ka laarin awọn eeyan, o n bẹ nínú àwọn èèyàn ẹniti o maa gba iwe rẹ pẹlu ọwọ ọtun, ati ẹniti o maa gba iwe rẹ pẹlu ọwọ osi tabi lati ẹyin rẹ, " Ati pe nini igbagbọ ninu abata ti a maa wọ inu ẹ, ti o wa fun Anọbi wa Muhammad, ati nini igbagbọ ninu ọgba idẹra ati ina, ati ninu pe awọn onigbagbọ maa ri Ọlọhun Ọba wọn, mimọ ni fun Un, ati pe yoo ba wọn sọrọ, ati nkan ti o yatọ si iyẹn ninu nkan ti o wa ninu Kuraani Alapọn-ọnle ati Hadiisi ti o ni alaafia lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun (Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a). Nini igbagbọ ninu gbogbo iyẹn patapata jẹ dandan ati gbigba a ni ododo ni ọna ti Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ gba ṣe alaye rẹ (Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a). "
Nini igbagbọ ninu kadara "
Sugbọn nini igbagbọ ninu kadara ko igbagbo ninu awọn alamọri mẹrin kan sinu: "
Àkọ́kọ́ nibẹ: Dajudaju Ọlọhun, mimọ ni fun Un, ti mọ nkan ti o ti n bẹ, ati nkan ti o maa bẹ, O si mọ awọn isesi awọn ẹrusin Rẹ, O si mọ awọn ijẹ-imu wọn ati awọn igba ti wọn maa lo laye, ati nkan to yatọ si awọn nkan yẹn ninu eto igbesi aye wọn, nkankan o pamọ si I ninu gbogbo iyẹn, mimọ ni fun Un, ti ọla Rẹ ga, gẹ́gẹ́ bi O ṣe sọ pé: " {dájúdáju Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan} " [Al-Baqarah: 231] Ọlọhun- Alágbára ti O gbọnngbọn- sọ pé: {nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. Àti pé dájúdájú Allāhu fi ìmọ̀ rọ̀gbà yí gbogbo n̄ǹkan ká.} (At-Talâq: 12)" Alamọri elẹẹkeji: Kikọ ti Ọlọhun, mimọ ni fun Un, kọ gbogbo nkan ti O kadara ẹ, gẹgẹ bi O ṣe sọ, mimọ ni fun un, pé: " {Dájúdájú A ti mọ ohun tí ilẹ̀ ń mú jẹ nínú wọn. Tírà (iṣẹ́ ẹ̀dá ) tí wọ́n ń ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ Wa} [Surah Qâf: 4] Allah tun sọ pe: Gbogbo n̄ǹkan ni A ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú tírà kan t'ó yanjú.} " [Yâ-sîn: 12] Allah tun sọ pe: Ṣé o ò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l'Ó mọ ohun tí ń bẹ nínú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Dájúdájú (àkọsílẹ̀) ìyẹn wà nínú tírà kan. Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu. (Al-Hajj:70) Alamọri elẹẹkẹta: Nini igbagbọ ninu fifẹ Rẹ ti yóò ṣẹ, nnkan ti O ba fẹ ni o maa bẹ, nkan ti ko ba fẹ ko nii maa bẹ, gẹ́gẹ́ bi O ṣe sọ, mimọ ni fun un, pé: " {Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́. }" [Al-Hajj:18] Ọlọhun- Alágbára ti O gbọnngbọn- sọ pé: Àṣẹ Rẹ̀ nígbà tí Ó bá gbèrò kiní kan ni pé, Ó máa sọ fún un pé "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. [Yâ-sîn: 82]" Ọlọhun ti O mọ tun sọ pe : Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (kiní kan) àfi tí Allāhu bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. [Al-Insân: 30] Alamọri elẹẹkẹrin: Dídá Rẹ , mimọ ni fun Un, ti O da gbogbo nkan ti n bẹ ti ko si Aṣẹ̀dá mìíràn to yatọ si I, ti ko si si oluwa mìíràn lẹyin Rẹ, gẹ́gẹ́ bi O ṣe sọ, mimọ ni fun un, pé: " Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan. [Az-Zumar: 62] Allah tun sọ pe: Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín. Ǹjẹ́ ẹ̀lẹ́dàá kan yàtọ̀ sí Allāhu tún wà tí ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo? Suratu Fatir: 3 Ini igbagbọ si kadara, yoo maa ko nini igbagbọ si awọn nnkan mẹrin yii sínú lọ́dọ̀ awọn Ah'lus sunnah wal Jama'ah, yatọ si awọn ti wọn tako apakan nínú iyẹn ninu awọn oni adadaalẹ
Ini igbagbọ yii ko ọrọ ati iṣẹ sinu, yoo maa lekun pẹlu titẹle, yoo si maa dinku pẹlu dida ẹṣẹ
O maa wọ inú ìgbàgbọ́ nínú Ọlọhun ìní adisọkan pe ìgbàgbọ́ jẹ ọ̀rọ̀ àti iṣẹ́, ti yoo maa lekun pẹ̀lú itẹle ti Ọlọhun, ti yoo si maa dínkù pẹ̀lú yiyapa ti Ọlọhun, ati pe ko ni ẹtọ ki a pe Musulumi kankan ni Kèfèrí pẹ̀lú ẹṣẹ ti o ba da ti ko to ẹbọ, ati iṣekeferi gẹ́gẹ́ bíi àgbèrè, ati jijale, ati jíjẹ owó èlé, ati mímú nǹkan ti n pa èèyàn bí ọtí, ati ṣíṣe òbí méjèèjì, ati ohun ti o yatọ si ìyẹn nínú àwọn ẹṣẹ ńlá, lópin ìgbà tí ko ba sọ ọ di ẹ̀tọ́, fun ọrọ Ọlọhun ti O sọ pe: Dajudaju Ọlọhun o ni ṣe aforijin lori pe ki wọn o mu orogun pẹlu Rẹ, yio si maa ṣe aforijin ẹṣẹ ti ko ba to o fun ẹniti o ba wu U" (suratun-Nisaa :48) Ati fun ohun ti o fi ẹsẹ rinlẹ ninu awọn hadiisi ti awọn eeyan pupọ gba wa lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) wi pe: Ọlọhun yoo mu ẹniti ohun ti o to òdiwọ̀n èso kardal ninu igbagbọ ba wa ninu ọkan rẹ jade ninu ina.
Ini ifẹ nítorí Ọlọhun, kikorira nítorí Ọlọhun, mímú ni ọ̀rẹ́ nitori Ọlọhun, mimu ni ọ̀tá nítorí Ọlọhun.
Nínú ìgbàgbọ́ nínú Ọlọhun ni: Ini ifẹ nítorí Ọlọhun, kikorira nítorí Ọlọhun, mímú ni ọ̀rẹ́ nitori Ọlọhun, mimu ni ọ̀tá nítorí Ọlọhun. Mumini maa nífẹ̀ẹ́ mumini, o si maa mu wọn ni ọrẹ, o maa korira àwọn keferi, o si maa mu wọn ni ọ̀tá, àwọn olórí àwọn mumini nínú ìjọ yii naa ni àwọn saabe ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a) Awọn Ah'lu-sunnah wal jama'a, yoo maa nífẹ̀ẹ́ wọn, wọn o si maa ba wọn ṣe ọrẹ, wọn o si maa ni adisọkan pe awọn ni ẹniti o loore julọ ninu awọn eeyan lẹyin awọn Anabi fun ọrọ Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) ti o sọ pe: Ọ̀rúndún ti o loore ju ni ọrundun temi, lẹyin naa ni o kan awọn ti wọn tẹle wọn, lẹyin naa ni awọn ti wọn tun tẹle wọn. Ohun ti wọn fẹnu ko lori nini alaafia rẹ ni, Wọn yoo si maa ni adisọkan pe ẹniti o lọla ju ninu wọn ni Abubakar As-Sideeq, lẹyin rẹ ni Umar Al-Faaruq, lẹyin rẹ Uthmaan Dhuu nurain, lẹyin rẹ ni Ali Al-Mur'tadho, (ki Ọlọhun yọnu si gbogbo wọn), lẹyin wọn ni awọn ti o ṣẹku ninu mẹ́wàá, lẹyin naa ni o kan awọn saabe ti o ku ( ki Ọlọhun yọnu si gbogbo wọn), wọn si maa dakẹ nibi nǹkan ti o ṣẹlẹ̀ láàrin wọn, wọn si maa ni adisọkan pe wọn jẹ onigbiyanju nibẹ ni, ẹni tí o ba ṣe ohun ti ó tọ̀nà, ẹsan meji o maa bẹ fun un, ẹniti o ba si ṣe aṣiṣe, ẹsan kan yoo maa bẹ fun un. Wọn si maa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará ilé ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ni àwọn tí wọ́n gba a gbọ́, wọn si maa nífẹ̀ẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀ tii ṣe àwọn ìyá àwọn mumini, wọn si ma maa tọrọ ki Ọlọhun yọnu si wọn lapapọ, wọn si maa yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò ni ojú ọ̀nà àwọn Rawaafidh ti wọn korira àwọn saabe, ti wọn si maa n bu wọn, ti wọn si n tayọ ààlà nipa àwọn ará ilé anọbi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a), ti wọn si n gbe wọn kọjá ipò ti Ọlọhun fi wọn si, wọn si tun maa yọwọ yọsẹ̀ kúrò ni ojú ọ̀nà àwọn Nawaasib ti wọn maa n fi suta kan àwọn ará ilé anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àbí iṣẹ́
Gbogbo ohun ti a sọ yii ninu ọrọ ṣoki yii ko sinu adisọkan ti o ni alaafia, eleyii ti Ọlọhun titori rẹ gbe ojiṣẹ Rẹ tii ṣe Muhammad dide (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) oun si ni adisọkan awọn ikọ ti o la (Ahlus-sunnah wal jama'a) eyii ti Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ nipa wọn pe: Ikọ̀ kan nínú ìjọ mi ko nii yẹ̀ ko nii gbò lẹniti wọn o maa ranṣe lórí òdodo, ẹni ko ba ran wọn lọ́wọ́ ko nii ko ìnira ba wọn titi ti àṣẹ Ọlọhun yóò fi deO sọ – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a– pe: Awọn ijọ Yahuudi ti pin si ẹgbẹ́ mọkanlelaadọrin, awọn ijọ Nasọọrọ naa si ti pin si ẹgbẹ mejilelaadọrin, ijọ mi yii si maa wa pin si ẹgbẹ mẹtalelaadọrin, gbogbo wọn ni yoo si wọ ina ayafi ẹgbẹ kan ninu wọn. Awọn saabe wa sọ pe: Tani wọn irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: ẹniti o ba wa lori deedee ohun ti emi ati awọn saabe mi wa lori rẹ. Oun si ni adisọkan ti o jẹ dandan lati dìrọ̀ mọ́ ọn ati diduro ṣinṣin lori rẹ ati ṣiṣọra kuro nibi ohun ti o ba yapa si i.
Dida orukọ awọn ti wọn yẹ̀gẹ̀rẹ̀ kuro nibi adisọkan yii ati awọn ti wọn n takò ó"
"Awọn iran wọn "
Sugbọn awọn ti wọn yẹgẹrẹ kuro nibi adisọkan yii ati awọn ti wọn n takò ó, onírúurú to pọ ni wọ́n, o n bẹ nínú wọn awọn to n bọ ère, ati awọn to n bọ oriṣa, ati awọn Mọlaika ati awọn wolii ati alujannu, ati awọn igi, ati awọn okuta, ati nkan ti o yatọ si i Gbogbo awọn yii o dahun si ipepe awọn Ojisẹ, bi ko ṣe pe wọn yapa wọn ni, wọn si ṣe agidi pẹlu wọn, gẹgẹ bi iran Kùráìṣì ati awọn iran larubawa ṣe ṣe pẹlu Anọbi Muhammad -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti wọn n beere lọdọ awọn nkan ti wọn jọsin fun, bibiya bukata wọn, iwosan awọn alaisan, ati àrànṣe lori awọn ọta, wọn maa n du ẹran fun wọn, wọn si maa n ṣe ileri fun wọn, igbati ojisẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa takò wọn ti o si pa wọn laṣẹ pẹlu ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, wọn ṣeemọ pẹlu iyẹn, wọn si ta ko o, wọn si sọ pe: " Ṣé ó máa sọ àwọn òrìṣà di Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí A óò máa jọ́sìn fún ni? Dájúdájú èyí mà ni n̄ǹkan ìyanu. "[Sâd: 5]" Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- ko yẹ ko gbo ti o n pe wọn si ti Ọlọhun, ti o si n ṣe ikilọ fun wọn kuro nibi ẹbọ, ti o si n ṣe alaye fun wọn nipa paapaa nkan ti wọn n pe wọn lọ si bẹ, titi ti Ọlọhun fi fi ọna mọ awọn ti o mọna ninu wọn, lẹyin iyẹn ni wọn wọ inu ẹṣin Ọlọhun nijọnijọ, ti ẹṣin Ọlọhun fi borí awọn ẹṣin yoku lẹyin ipepe ti ko duro, ati ijagun si oju ọna Ọlọhun fun ìgbà pípẹ́, lati ọdọ Ojisẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati awọn saabe Rẹ -ki Ọlọhun yọnu si wọn- ati awọn ti o tẹle wọn pẹlu dáadáa. Leyin naa ni awọn iṣesi yi pada ti aimọkan si bori ọpọlọpọ ẹda titi tí ogunlọgọ awọn eeyan fi ṣeri pada lọ sibi ẹsin ìgbà aimọkan, pẹ̀lú aṣeju nipa awọn Anọbi ati awọn Wòlíì, ati pípè wọn, ati iwa ìgbàlà pẹlu wọn, ati eyi ti o yatọ si iyẹn ninu awọn onírúurú ẹbọ, ti wọn ko si mọ itumọ "Laa Ilaaha Illallohu" gẹ́gẹ́ bí awọn alaigbagbọ ninu awọn Larubawa ṣe mọ itumọ rẹ, ki Ọlọhun ṣàánú fún wa.
"Ẹbọ yii o yẹ ko gbo ti o n fọnka laarin awọn eeyan titi di asiko wa yii latara aimọkan ati jíjìnnà si àsìkò Anọbi.
Iruju awọn ẹni ikẹyin ninu wọn ni ìríjú awọn ẹni iṣaaju, wọn wa dárúkọ díẹ̀ ninu awọn adisọkan ti aigbagbọ"
Iruju awọn ẹni ikẹyin yii ni iruju awọn ẹni iṣaaju, oun naa ni ọrọ wọn pe: Awọn eyi ni oluṣipẹ wa lọdọ Ọlọhun, a ko jọsin fun wọn bi ko ṣe pe nitori ki wọn le mu wa sunmọ Ọlọhun, Ọlọhun si ti ba iruju yii jẹ, O si ti ṣalaye pe dajudaju ẹniti o ba jọsin fun ẹlomiran ti o yatọ si Oun, ẹnikẹni ti o baa jẹ, o ti da ẹbọ pọ mọ Oun, o si ti ṣe aigbagbọ, gẹ́gẹ́ bí Ọba ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pe: " {Wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò lè kó ìnira bá wọn, tí kò sì lè ṣe wọ́n ní àǹfààní lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń wí pé: "Àwọn wọ̀nyí ni olùṣìpẹ̀ wa lọ́dọ̀ Allāhu} " "[Yûnus: 18]" Ọlọhun- mimọ ni fun Un- wa fun wọn ní esi pẹlu ọrọ Rẹ pe:" {" Sọ pé: "Ṣé ẹ máa fún Allāhu ní ìró ohun tí kò mọ̀ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni?" Mímọ́ ni fún Un, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.} " "[Yûnus: 18]" Ọlọhun- mimọ ni fun Un- ṣe alaye ninu aaya yii pe dajudaju ìjọsìn fun ẹlomiran to yatọ si Oun, ninu awọn Anọbi ati awọn Wòlíì, tabi ẹniti o yatọ si wọn, ẹbọ ti o tobi julọ ni, koda ti awọn ti o n ṣe e ba sọ ọ ni nkan miran to yatọ si ìyẹn, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: " {Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): "A ò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni. }" Suuratuz Zumar: 3. Ọlọhun -mimọ ni fun Un- fèsì fún wọn pẹlu ọrọ Rẹ pe:" "{Dájúdájú Allāhu l'Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn 'Islām). Dájúdájú Allāhu kì í fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́.} Suuratuz Zumar: 3. "Ọlọhun, mimọ ni fun Un, wa fi han pẹlu ìyẹn pe dajudaju ijọsin wọn fun ẹlomiran pẹlu pípè wọn, ati ibẹru, ati irankan, ati nkan to jọ ìyẹn jẹ aigbagbọ si I mimọ ni fun Un, ti O si pe wọn ni irọ nibi ọrọ wọn pe dajudaju awọn oosa wọn o mu wọn sunmọ Ọlọhun ni pẹkipẹki. " Ninu awọn adisọkan ti aigbagbọ ti o n yapa adisọkan ti o ni alaafia ti o jẹ alatako fun nkan ti awọn Ojiṣẹ- ki ikẹ ati ọla maa ba wọn- mu wa naa ni nkan ti awọn ti ko ni igbagbọ ninu bibẹ Ọlọhun di sọkan ni asiko wa yii ninu awọn olutẹle Marx ati Lenin, ati awọn ti o yatọ si awọn mejeeji ninu awọn olupepe si aini igbagbọ si bibẹ Ọlọhun ati keferi, boya wọn sọ ọ ni ìṣesósíálístì tabi ìṣekọ́múnístì, tabi iṣebasisiimu, tabi eyi to yatọ si ìyẹn ninu awọn orukọ, ati pe ninu awọn ìpìlẹ̀ awọn ti ko ni igbagbọ ninu bibẹ Ọlọhun yii ni pe ko si Ọlọhun, ati pe iṣẹmi jẹ ohun ti a le fojú rí" Ninu ìpìlẹ̀ wọn tun ni titako iseri pada sọdọ Ọlọhun ati bibẹ ọgbà idẹra ati iná, ati ṣiṣe aigbagbọ si gbogbo ẹsin patapata, ẹni tí ó bá wo awọn iwe wọn ti o sì kọ́ nkan ti wọn wa lori ẹ, yoo mọ ìyẹn ni amọdaju. Ko si iyemeji pe dajudaju adisọkan yii tako gbogbo awọn ẹsin atọrunwa, ti o si maa ti awọn ti wọn n ṣe e lọ si eyi ti o buru julọ ninu awọn àtúbọ̀tán ni aye ati ọjọ ikẹyin Ninu awọn adisọkan to tako òdodo ni nkan ti apakan awọn Baatiniyyah di sọkan ati apakan awọn Suufi pe dajudaju apakan awọn ti wọn pe wọn ni wolii n ba Ọlọhun kẹ́gbẹ́ nibi ṣíṣe ètò ti wọn si n ṣe bi o ṣe wu wọn nipa eto igbesi aye ti wọn si n pe wọn ni qutubu, ati watadu, ati gaosu, ati nkan miran to yatọ si ìyẹn ninu awọn orukọ ti wọn hun wọn fun awọn ọlọhun wọn, " Eleyii wa ninu eyi ti o buru ju lọ ninu ẹbọ nibi nini igbagbọ ninu Ọlọhun nikan ṣoṣo nibi awọn iṣe Rẹ, oun tun buru ju ẹbọ ìgbà aimọkan àwọn Larubawa lọ; tori pe awọn alaigbagbọ Larubawa o da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun nibi nini igbagbọ ninu Ọlọhun nikan ṣoṣo nibi awọn iṣe Rẹ, bi ko ṣe pe wọn da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun nibi ijọsin, dida ẹbọ pọ wọn si jẹ nigba idẹra, ṣugbọn nigba ilekoko wọn maa n mọ ijọsin kanga fun Ọlọhun ni, gẹgẹ bi Ọlọhun, mimọ ni fun Un, ṣe sọ pé: " Nígbà tí wọ́n bá gun ọkọ̀ ojú-omi, wọ́n yóò pe Allāhu (gẹ́gẹ́ bí) olùṣàfọ̀mọ́-àdúà fún Un. Àmọ́ nígbà tí Ó bá kó wọn yọ sí orí ilẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa ṣẹbọ "[Al-`Ankabût: 65] Ṣugbọn nini igbagbọ ninu Ọlọhun nikan ṣoṣo nibi awọn iṣe Rẹ, wọn fi rinlẹ fun Un ni Oun nikan ṣoṣo, gẹgẹ bi Ọlọhun- mimọ ni fun Un- ṣe sọ pé: " {Àti pé tí o bá bi wọ́n léèrè pé: "Ta ni Ó dá wọn?", dájúdájú wọn á wí pé: "Allāhu ni.}" "[Az-Zukhruf: 87]" Allah tun sọ pe: Sọ pé: "Ta ni Ó ń pèsè fun yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ta ni Ó ní ìkápá lórí ìgbọ́rọ̀ àti ìríran? Ta ni Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú, tí Ó tún ń mú òkú jáde láti ara alààyè? Ta sì ni Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá)?" Wọn yóò wí pé: "Allāhu" Nígbà náà, sọ pé: "Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?" Suratu Yunus: 31 Awọn Aayah to wa lori itumọ yii pọ.
Nkan ti awọn ọṣẹbọ ti wọn de kẹyin ṣe afikun ẹ lori ti awọn ẹni iṣaaju"
Ṣugbọn awọn ọṣẹbọ ti o de kẹyin ṣe afikun lori awọn ẹni iṣaaju ni ọna meji: Àkọ́kọ́ ninu ẹ: Dida ẹbọ apakan ninu wọn pọ mọ Ọlọhun nibi nini igbagbọ ninu Ọlọhun nikan ṣoṣo nibi awọn iṣe Rẹ. Ẹlẹẹkeji: Dida ẹbọ wọn pọ mọ Ọlọhun nigba idẹkun ati ilekoko, ti ko si pamọ fun ẹni tí ó ba ròpọ̀ mọ wọn, ti o si mọ iṣesi wọn, ti o si ri nkan ti wọn ṣe nibi saare Hussein ati Al-Badawy ati awọn to yatọ si wọn ni ìlú Egypt, ati nibi saare Al-A'idaruus ni Hadan, ati saare Al-Haadiy ni Yemen ati saare Ibnul Arabiy ni Shaam, ati saare As-Sheikh Abdul Qoodir Al-Jailaaniy ni Iraq, ati awọn to yatọ si wọn ninu awọn saare to gbajumọ ti awọn eeyan ṣe àṣejù nibẹ ti wọn si yi ọpọ ninu ẹtọ Ọlọhun fun wọn-Ọba ti O tobi ti O gbọnngbọn- ti awọn to n takò wọn sì kéré, ti wọn yoo si ṣe alaye fun wọn paapa nini igbagbọ ninu Ọlọhun ni Òun nikan ṣoṣo, eleyii ti Ọlọhun gbe Anọbi Rẹ dide pẹlu ẹ- Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati awọn ti o ṣíwájú rẹ ninu awọn Ojiṣẹ- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba wọn- tori pe dajudaju ọdọ Ọlọhun lati wa ọdọ Rẹ naa ni a maa pada si: " A n bere lọwọ Rẹ, mimọ ni fun Un, lati ṣẹ wọn lori pada sibi imọna wọn, ki O si jẹ ki awọn olupepe sí imọna pọ laarin wọn, ki O si fi awọn aṣaaju awọn Musulumi ati awọn onímímọ̀ wọn ṣe kongẹ lati gbe ogun ti ẹbọ yii, ati lati pa a rẹ, ati awọn àtẹ̀gùn rẹ, dajudaju Oun ni Ọba ti O n gbọ ti O sunmọ. " "Ninu awọn adisọkan ti o tako adisọkan ti o ni alaafia nibi àkòrí nini igbagbọ ninu awọn orukọ Ọlọhun ati awọn iroyin Rẹ, ni awọn adisọkan awọn oni adadaalẹ ninu awọn Al-Jahmiyyah ati awọn Al-Muhtazilah ati ẹniti o ba tẹle ilana wọn nibi titako awọn iroyin Ọlọhun (Ọba ti O tobi ti O gbọnngbọn), ati sisọ pe Ọlọhun ko ni iroyin pípé, ati rí ròyìn Rẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan ti kò sí, ati awọn nǹkan ti kò ní ẹ̀mí, ati awọn nǹkan ti o ṣòro láti ṣẹlẹ̀, Ọlọhun ga ní gíga t'ó tóbi tayọ ohun tí wọ́n ń wí. Ninu awọn ti wọn wọnú ìyẹn naa ni àwọn ti wọn tako àwọn ìròyìn kan, ti wọn si fi àwọn kan rinlẹ, gẹ́gẹ́ bíi àwọn Ashaa'irah, torí pé o maa jẹ dandan fun wọn nibi awọn ìròyìn tí wọ́n fi rinlẹ irú nǹkan tí wọ́n sá fún nibi awọn ìròyìn tí wọ́n takò, ti wọn si tú àwọn ẹ̀rí rẹ ní ìtúkútùú, ti wọn wa ti ipasẹ rẹ yapa àwọn ẹri Kuraani ati Hadiisi, ati awọn ẹri ti làákàyè, ti wọn si tako ara wọn nibi ìyẹn ni itako ti o fi ojú hàn Ṣugbọn awọn ahlus sunna wal jamaa'ah ti fi awọn nkan ti Ọlọhun fi rinlẹ fun ara Rẹ rinlẹ, tabi nkan ti Ojisẹ Rẹ Muhammad fi rinlẹ fun Un- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu awọn orukọ Ọlọhun ati iroyin Rẹ ni ọna pípé, ti wọn si fọ Ọ mọ kuro nibi jijọ ẹda Rẹ ni afọmọ kan to mọ kuro ninu ẹ̀gbin sísọ pé kò rí bẹ́ẹ̀, ti wọn si ṣe àmúlò awọn ẹri naa patapata ti wọn o si yi i pada, ti wọn o si sọ pé kò rí bẹ́ẹ̀, ti wọn si la kuro nibi titako ara ẹni ti awọn ti o yatọ si wọn ko si, gẹ́gẹ́ bí alaye yẹn ṣe ṣaaju, " Eléyìí naa ni ọna ọlà àti oriire ni ile aye ati ọjọ ikẹyin, òun naa ni ọna ti o tọ ti awọn ẹni iṣaaju ijọ yii ati awọn imaamu wọn tọ, kò sí ohun ti o le mú kí àwọn ẹni ìkẹyìn wọn dára àyàfi ohun ti awọn ẹni àkọ́kọ́ wọn fi dára, oun naa ni itẹle Kuraani ati Sunna, ati gbigbe nkan ti o yapa mejeeji ju silẹ. "
Ijẹ dandan ijọsin Ọlọhun nikan ṣoṣo ati alaye awọn okunfa bibori awọn ọta Ọlọhun"
Dajudaju nkan ti o ṣe pataki ju ninu nkan ti o jẹ dandan fun ẹniti a la iwọ Ọlọhun bọ lọrun, ati eyi ti o tobi julọ ninu nkan ti o jẹ ọranyan le e lori ni ki o maa jọsin fun Ọlọhun Ọba Rẹ, mimọ ni fun Un, Oluwa awọn sanma ati ilẹ, ati Oluwa aga ọla ti o tobi, Ọba ti O n sọrọ ninu iwe Rẹ Alapọn-ọnle pé: " Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá. Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá. Ṣūratul A'rōf: 54. Ọlọhun tun sọrọ ni ààyè miran ninu iwe Rẹ pe dajudaju Oun da èèyàn ati alujannu fun ijọsin Rẹ, O wa sọ pe: " Àti pé Èmi kò ṣẹ̀dá àlùjànnú àti ènìyàn bí kò ṣe pé kí wọ́n lè jọ́sìn fún Mi. Suuratudh Dhāriyāt: 56. "Ijọsin yii ti Ọlọhun da eeyan ati alujaanu tori ẹ ni mímú Un ní ọ̀kan pẹlu awọn iran ijọsin, bíi kiki irun ati gbigba awẹ ati yiyọ Zakah ati lilọ si ile Oluwa, ati rukuu ati fifi ori balẹ, ati rirọkirika ile Oluwa ati didu ẹran ati ileri ati ibẹru ati irankan, ati iwa ìgbàlà, ati iwa iranlọwọ, ati iwa iṣora, ati gbogbo awọn iran adua to ku, ati pe titẹ le E, mimọ fun Un, nibi gbogbo awọn aṣẹ Rẹ ati gbigbe awọn nǹkan ti O kọ̀ ju silẹ naa wọnú iyẹn, lori nkan ti iwe Rẹ Alapọn-ọnle, Sunna Ojisẹ Rẹ olufọkantan da le lori, ki eyi to daa julọ ninu ikẹ ati ọla lati ọdọ Oluwa Rẹ maa ba a. Ọlọhun (Ọba ti O mọ) pa gbogbo awọn eeyan ati alijannu laṣẹ lati maa ṣe ijọsin yii ti wọn titori rẹ da wọn. O si ran gbogbo awọn ojiṣẹ pátá, O si sọ awọn tira kalẹ lati le ṣalaye ijọsin yii lẹkunrẹrẹ, ati pípe ìpè lọ sibẹ, ati ṣíṣe e fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, gẹgẹ bi Ọba ti O ga ṣe sọ pe: Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó da ẹ̀yin àti àwọn t'ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè ṣọ́ra (fún ìyà Iná). Suratul Baqara: 21 Ọlọhun- Alágbára ti O gbọnngbọn- sọ pé: Olúwa rẹ pàṣẹ pé: "Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Òun. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì. Al-Isroo: 23 Itumọ "Qọdọọ" ninu aayah yii ni; "O paṣẹ", ati "O sọ asọtẹlẹ". Allah tun sọ pe: Àwa kò sì pa wọ́n ní àṣẹ kan bí kò ṣe pé kí wọ́n jọ́sìn fún Allāhu (kí wọ́n jẹ́) olùṣe-àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn fún Un, olùdúró déédé. Kí wọ́n kírun, kí wọ́n sì yọ Zakāh. Ìyẹn sì ni ẹ̀sìn t'ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀. Sūratul Bayyinah: 5 Awọn aayah ti o da lori itumọ yii ninu ọrọ Ọlọhun pọ pupọ, Ọlọhun sọ pe: Ohunkóhun tí Òjíṣẹ́ bá fun yín, ẹ gbà á. Ohunkóhun tí ó bá sì kọ̀ fun yín, ẹ jáwọ́ nínú rẹ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le níbi ìyà. Al-Hash'r: 7 Ọlọhun ti O mọ tun sọ pe : Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu, ẹ tẹ̀lé (àṣẹ) Òjíṣẹ́ náà àti àwọn aláṣẹ nínú yín. Nítorí náà, tí ẹ bá yapa ẹnu sí kiní kan, ẹ ṣẹ́rí rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ (sollalāhu 'alayhi wa sallam), tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn lóore jùlọ, ó sì dára jùlọ fún ìkángun ọ̀rọ̀. [An-Nisaa': 59]. Ọlọhun- Alágbára ti O gbọnngbọn- sọ pé: Ẹnikẹ́ni t'ó bá tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, ó ti tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu. (Suuratun Nisaa: 80) Ọlọhun ti O mọ tun sọ pe : Dájúdájú A ti gbé Òjíṣẹ́ dìde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan (láti jíṣẹ́) pé: "Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì jìnnà sí àwọn òrìṣà." Suratun Nahl: 36 Ọlọhun ti O mọ tun sọ pe : A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: "Dájúdájú kò sí ọlọ́hun tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi." Suratul Anbiyaa: 25 Allah tun sọ pe: 'Alif lām rọ̄. (Èyí ni) Tírà tí wọ́n ti to àwọn āyah inú rẹ̀ ní àtògún régé, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán. (A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé ẹ má jọ́sìn fún kiní kan àfi Allāhu. Dájúdájú emi ni olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fun yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. [Huud:1 - 2]. Awọn aayah ti wọn to ni àtògún régé yii ati awọn nnkan ti o wa ti n tumọ rẹ lati inu tira Ọlọhun, gbogbo rẹ ni n tọka lori jijẹ dandan ijọsin fun Ọlọhun nìkan, iyẹn si ni ipilẹ ẹsin, gẹgẹ bi o ti ṣe jẹ pe o n tọka si pe ìyẹn naa ni ọgbọn ti o n bẹ nibi dida awọn alijannu ati eeyan ati riran awọn ojiṣẹ ati sisọ awọn tira kalẹ. Eyi ti o jẹ dandan lori gbogbo awọn ti wọn la nnkan bọ wọn lọrun naa ni ini akolekan alamọri yii, ati gbigbọ ọ ye, ati ṣiṣọra kuro nibi ohun ti ọpọlọpọ Musulumi ko sinu rẹ nibi kikọja aala latara awọn Anabi ati awọn ẹniire, ati kíkọ́ nǹkan sórí sàréè wọn ati kíkọ́ mọṣalaaṣi ati awọn òrùlé rìbìtì lórí wọn, ati mimaa beere nnkan lọwọ wọn, ati wiwa ìgbàlà lọ si ọdọ wọn, ati sísádi wọ́n, ati mimaa bi wọn leere lati biya awọn bukaata ati mimu idaamu kuro, ati ṣiṣe iwosan fun awọn alaisan, ati bibori ọ̀tá, ati awọn nnkan mìíràn ti o yatọ si i ti o wa ninu awọn oríṣiríṣi ẹbọ ti o tobi. O wa ni ohun ti o ni alaafia lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) ni ohun ti o ṣe deedee ohun ti ọrọ Ọlọhun (Ọba ti O tobi) n tọka le lori. O wa lati inu Saheeh mejeeji lati ọdọ Muaadh (ki Ọlọhun yọnu si i) pe: Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ fun un pe: "Njẹ o mọ iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ati iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun? Muaadh sọ pe: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn mọ julọ. Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) wa sọ pe: Iwọ̀ Ọlọhun lori awọn ẹrusin naa ni ki wọn maa jọsin fun Un, ki wọn si ma ṣe ẹbọ kankan pẹlu Rẹ. Iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun ni pe ki O ma fi iya jẹ ẹniti ko ba ṣe ẹbọ kankan pẹlu Rẹ." 7 O wa ninu Saheeh Bukhari lati ọdọ Ibn Mas'uud (ki Ọlọhun yọnu si i) pe: Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ pe: "Ẹniti o ba ku lẹniti ti n pe akẹgbẹ́ kan fun Ọlọhun, onitọun yoo wọ ina."Muslim gbe e jade ninu Sọhiihu rẹ lati ọdọ Jaabir (ki Ọlọhun yọnu si i) pe Anabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ pe: "Ẹniti o ba pade Ọlọhun lẹniti ko ṣe ẹbọ kankan pẹlu Rẹ, onitọun yoo wọ Alijanna, ẹniti o ba pade Rẹ lẹniti o ti ṣe ẹbọ pẹlu Rẹ onitọun yoo wọ ina"Àwọn ti wọn wa lori itumọ yii pọ̀, àlámọ̀rí yii si jẹ ọkan ninu awọn àlámọ̀rí ti o pàtàkì jù ti o si tóbi jù, Ọlọhun ti gbe anọbi Muhammad- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá a- dìde pẹ̀lú ipepe si imọ Ọlọhun lọkan, ati kikọ kúrò níbi ẹbọ, o si jẹ nnkan ti Ọlọhun ran an ni ti jijẹ, wọn fi suta kan an, o si ṣe suuru lori rẹ, àwọn saabe rẹ- ki Ọlọhun yọnu si wọn- naa si ṣe suuru pẹ̀lú rẹ lori jijẹ iṣẹ ipepe naa, titi ti Ọlọhun fi mu àwọn ère ati ooṣa kuro ni erékùṣù ilẹ̀ Lárúbáwá, ti àwọn eeyan si wọ inu ẹsin Ọlọhun nijọnijọ, wọn si run àwọn ère ti wọn wa ni àyíká kaaba ati inú rẹ, wọn si wó ooṣa laata ati huzzaa, ati manaata, wọn si rún gbogbo àwọn ère inu awọn ìdílé larubawa ati awọn ooṣa wọn, ti ọrọ Ọlọhun si bori, ti Isilaamu si hàn ni erékùṣù Lárúbáwá. Lẹ́yìn náà ni àwọn Mùsùlùmí gbe ipepe ati jihaad kuro ninu erékùṣù larubawa, Ọlọhun si ni ki ẹni ti a ti kọ àkọsílẹ̀ oriire mọ ninu awọn ẹrusin o mọ̀nà láti ipasẹ wọn, Ọlọhun si tun ti ipasẹ wọn fọn òdodo ati déédéé ká ni ọpọ agbègbè ilé ayé, wọn wa ti ipasẹ ìyẹn di aṣáájú imọna ati òdodo, ati olupepe si déédéé ati atunṣe, ti àwọn taabi'uun ati awọn ti wọn tẹle wọn naa si rìn ni ojú ọ̀nà wọn pẹ̀lú dáadáa, ti àwọn naa si jẹ aṣáájú imọna ati olupepe òdodo, ti wọn si n tan ẹsin Ọlọhun ká, ti wọn si n pe àwọn èèyàn lọ sibi imọ Ọlọhun lọkan, ti wọn si n jagun si oju ọna Rẹ pẹ̀lú ẹmi wọn ati dúkìá wọn, lai bẹ̀rù èébú eléèébú, Ọlọhun si kún wọn lọ́wọ́, O si fi wọn bori alátakò wọn, O si pe ohun ti O ṣe ni adehun fun wọn nínú ọrọ Rẹ ti O sọ pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí ẹ bá ran (ẹ̀sìn) Allāhu lọ́wọ́, (Allāhu) máa ràn yín lọ́wọ́. Ó sì máa mú ẹsẹ̀ yín dúró ṣinṣin. [Muhammad: 7]. Ati ọrọ Ọlọhun Ọba ti O ga julọ ti O si gbọn-n-gbọn ti O sọ pe : {Dájúdájú Allāhu yóò ṣe àrànṣe fún ẹnikẹ́ni t'ó ń ran (ẹ̀sìn 'Islām) Rẹ̀ lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí. 40}. (Àwọn náà ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí A bá fún wọn ní ipò lórí ilẹ̀, wọn yóò kírun, wọn yóò yọ Zakāh, wọn yóò pàṣẹ ohun rere, wọn yó sì kọ ohun burúkú. Ti Allāhu sì ni ìkángun àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá. [Al-Hajj: 40 - 41] Lẹyin naa ni àwọn èèyàn wa yí padà ti wọn sì pín yẹlẹyẹlẹ, ti wọn si fi ọwọ́ dẹngẹrẹ mú ọ̀rọ̀ jihaad, ti wọn si gbé ọlá fún ìsinmi ati itẹle yòdòyìndìn ẹ̀mí, ti ìwà ibajẹ sì hàn láàrin wọn àyàfi ẹni ti Ọlọhun bá ṣọ́ kúrò nibẹ, Ọlọhun naa wa yí padà si wọn, O si dẹ ọ̀tá wọn sí wọn, ki o maa jẹ ẹsan fun nnkan ti wọn ṣe, Oluwa rẹ kii ṣe àbòsí fún ẹrú, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ìyẹn nítorí pé dájúdájú Allāhu kò níí ṣe ìyípadà ìdẹ̀ra tí Ó ṣe fún ìjọ kan títí wọn yóò fi ṣe ìyípadà n̄ǹkan tí ń bẹ lọ́dọ̀ ara wọn [Al-Anfaal: 53]. Ohun ti o jẹ dandan fun gbogbo Mùsùlùmí, ati ijọba ati ará ìlú, naa ni ki wọn ṣẹri pada si ọdọ Ọlọhun, ki wọn si maa jọsin fun Oun nìkan, ki wọn si tuuba lọ sí ọdọ Rẹ kúrò nínú ìkùdíẹ̀-káàtó wọn ti o ti ṣáájú, ati awọn ẹṣẹ wọn, ki wọn si yara maa ṣe ohun ti Ọlọhun ṣe ni ọranyan le wọn lori, ki wọn si jina si ohun ti O ṣe ni eewọ, ki wọn si maa sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ láàrin ara wọn, ki wọn si maa ran ara wọn lọ́wọ́ lori ẹ.
Ninu ohun ti o pataki ju ninu iyẹn ni gbigbe awọn aala ofin dide ati lilo awọn ofin ẹsin nibi gbogbo nnkan laarin awọn eeyan, ati gbígbé ẹjọ́ lọ ba wọn, ati pipa àwọn òfin ayé ti o yapa ti Ọlọhun tì, ati ki wọn si ma gbe ẹjọ́ lọ ba wọn, ki wọn sì ṣe ìdájọ́ ṣẹria ni tulaasi lori awọn ará ìlú, gẹgẹ bi o ṣe jẹ́ dandan fun àwọn onímímọ̀ lati jẹ ki awọn èèyàn gbọ́ ẹsin ye, ki wọn si tan agbọye Isilaamu ka láàrín wọn, ki wọn si maa sọ àsọtẹ́lẹ̀ òdodo ati sùúrù lórí rẹ, ki wọn si maa pàṣẹ dáadáa, ki wọn si maa kọ aburu, ki wọn si maa gbó àwọn adarí láyà lórí ìyẹn. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ dandan lati gbógun ti àwọn ìlànà ti maa n ba nǹkan jẹ bii àjùmọ̀ní, ati ìtanijí, ati ìgbónára fun orílẹ̀-èdè, ati ohun ti o yatọ si i ninu awọn ilana ati ẹ̀yà ìsìn ti o yapa ṣẹria, pẹ̀lú ìyẹn, Ọlọhun maa ṣe àtúnṣe ohun ti o ti bàjẹ́ fun àwọn Mùsùlùmí, Yoo si da ohun ti o ti bọ mọ wọn lọ́wọ́ pada, yoo si tun da iyì wọn ti o ti lọ padà, yoo si mu wọn borí ọ̀tá wọn, yoo si fi ààyè gba wọn lórí ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọba ti ọla Rẹ ga ṣe sọ pé: Ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ fún wa láti ṣe àrànṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. [Ar-Ruum: 47] Allah tun sọ pe: Allāhu ṣàdéhùn fún àwọn t'ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú yín, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere pé dájúdájú Ó máa fi wọ́n ṣe àrólé lórí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi àwọn t'ó ṣíwájú wọn ṣe àrólé. Dájúdájú Ó máa fi àyè gba ẹ̀sìn wọn fún wọn, èyí tí Ó yọ́nú sí fún wọn. Lẹ́yìn ìbẹ̀rù wọn, dájúdájú Ó máa fi ìfàyàbalẹ̀ dípò rẹ̀ fún wọn. Wọ́n ń jọ́sìn fún Mi, wọn kò sì fi n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí Mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì moore lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́. [An-Nuur: 55] Ọlọhun ti O mọ tun sọ pe : Dájúdájú Àwa kúkú máa ṣàrànṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn t'ó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìgbésí ayé yìí àti ní ọjọ́ tí àwọn ẹlẹ́rìí yó dìde (ní Ọjọ́ Àjíǹde). [Gaafir: 51]. Ní ọjọ́ tí àwáwí àwọn alábòsí kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní; ègún ń bẹ fún wọn, ilé (ìyà) burúkú sì wà fún wọn. [Gaafir: 52]
Ọlọhun ni a n bẹ̀ ki O tun àwọn adarí àwọn Mùsùlùmí ṣe ati awọn Mùsùlùmí ni àpapọ̀, ki O si fun wọn ni agbọye ẹsin, ki O si jẹ ki ohùn wọn ṣe ọ̀kan lórí ìpayà Ọlọhun, ki O si fi wọ́n mọ ọna ti o tọ́, ki O si fi wọn ran òdodo lọ́wọ́, ki O si fi wọn já irọ́ kulẹ̀, ki O si fin wọn ṣe kongẹ lati maa ran ara wọn lọ́wọ́ lórí dáadáa ati ìpayà Ọlọhun ati sisọ àsọtẹ́lẹ̀ òdodo ati suuru lórí rẹ, Oun ni olukapa lórí rẹ̀, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa bá ẹrú Rẹ ati ojiṣẹ Rẹ, ati ẹni ẹ̀sà Rẹ nínú àwọn ẹ̀dá Rẹ, anọbi wa, aṣáájú wa, Muhammad ọmọ Abdullaah, ati awọn ara ilé rẹ, ati awọn saabe rẹ, ati awọn ti wọn mọ̀nà pẹ̀lú imọna rẹ. Àlàáfíà Ọlọhun, ikẹ Rẹ, ati ìbùkún Rẹ ki o maa ba yin.